ÌTÀN 50
Àwọn Obìnrin Méjì Tó Nígboyà
NÍGBÀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá kó sínú ìṣòro, wọ́n á ké pe Jèhófà. Jèhófà máa ń dá wọn lóhùn nípa fífún wọn ni àwọn aṣáájú tó nígboyà láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bíbélì pe àwọn aṣáájú wọ̀nyí ní onídàájọ́. Jóṣúà ni onídàájọ́ kìíní, orúkọ díẹ̀ nínú àwọn onídàájọ́ tó wà lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Ótíníẹ́lì, Éhúdù àti Ṣámúgárì. Ṣùgbọ́n méjì nínú àwọn tó ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́ jẹ́ obìnrin, àwọn ni Dèbórà àti Jáẹ́lì.
Dèbórà jẹ́ wòlíì obìnrin. Jèhófà máa ń bá a sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, òun náà á sì sọ ohun tí Jèhófà wí fáwọn èèyàn náà. Dèbórà tún jẹ́ onídàájọ́. Ó máa ń jókòó sábẹ́ igi ọ̀pẹ kan lápá òkè ilẹ̀ náà, àwọn èèyàn sì máa ń tọ̀ ọ́ wá láti wá ìrànlọ́wọ́ lórí ìṣòro wọn.
Ní àkókò yẹn, Jábínì ni ọba Kénáánì. Ó ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án kẹ̀kẹ́ ogun. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lágbára tó bẹ́ẹ̀ débi pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti fi ipá mú láti di ìránṣẹ́ Jábínì. Orúkọ olórí ogun Jábínì Ọba sì ni Sísérà.
Ní ọjọ́ kan, Dèbórà ránṣẹ́ pe Bárákì Onídàájọ́, ó sì wí fún un pé: ‘Jèhófà wí pé: “Mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ọkùnrin kó o sì ṣáájú wọn lọ sí Òkè Tábórì. Ibẹ̀ ni màá mú Sísérà tọ̀ ọ́ wá. Màá sì mú kó o ṣẹ́gun rẹ̀ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀.”’
Bárákì wí fún Dèbórà pé: ‘Àfi tó o bá tẹ̀ lé mi lọ ni màá fi lọ.’ Dèbórà bá a lọ, ṣùgbọ́n ó wí fún Bárákì pé: ‘Ìwọ kọ́ lo máa gba ìyìn fún ìṣẹ́gun náà, nítorí pé obìnrin ni Jèhófà máa fi Sísérà lé lọ́wọ́.’ Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyí gẹ́lẹ́.
Bárákì sọ̀ kalẹ̀ láti Òkè Tábórì láti pàdé ogun Sísérà. Lójijì, Jèhófà mú kí omi púpọ̀ ya wá, púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ọ̀tá ló sì kú sínú omi náà. Ṣùgbọ́n Sísérà bẹ́ sílẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ó sì sá lọ.
Nígbà tó ṣe Sísérà wá sí àgọ́ Jáẹ́lì. Obìnrin náà gbà á wọlé, ó sì fún un ní wàrà mu. Èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í tòògbé, láìpẹ́, ó sì sùn lọ fọnfọn. Jáẹ́lì sì mú igi ìpàgọ́ ẹlẹ́nu ṣóńṣó kan ó sì gbá a mọ́ orí ọkùnrin búburú yìí títí ó fi wọ agbárí rẹ̀ lọ. Nígbà tí Bárákì sì dé, obìnrin náà fi òkú Sísérà hàn án! Báyìí ni ọ̀rọ̀ Dèbórà ṣe ní ìmúṣẹ.
Níkẹyìn wọ́n pa Jábínì Ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i fún àkókò kan.