ÌTÀN 39
Ọ̀pá Áárónì Yọ Òdòdó
WO ÀWỌN òdòdó àti àwọn èso álímọ́ńdì pípọ́n tó yọ lára ọ̀pá yìí. Ọ̀pá Áárónì nìyí. Àwọn òdòdó wọ̀nyí àti èso pípọ́n náà yọ lára ọ̀pá Áárónì ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo! Jẹ́ ká wo ìdí rẹ̀.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń tàràkà nínú aginjù fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí. Díẹ̀ nínú wọn ò rò pé ó yẹ kí Mósè jẹ́ aṣáájú àwọn, tàbí pé kí Áárónì jẹ́ àlùfáà àgbà. Kórà jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn tó rò báyìí, Ábírámù àti ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́wàá [250] àwọn olórí nínú àwọn èèyàn náà sì rò bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn wọ̀nyí kó ara wọn wá sọ́dọ̀ Mósè wọ́n sì wí fún un pé: ‘Kí ló dé tó o fi gbé ara rẹ ga ju àwa tó kù lọ?’
Mósè wí fún Kórà àti àwọn tó tẹ̀ lé e pé: ‘Ní òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ mú ohun tá a fi ń sun tùràrí wá kẹ́ ẹ sì fi tùràrí sínú wọn. Lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ wá sí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà. A máa rí ẹni tí Jèhófà á yàn.’
Ní ọjọ́ kejì, Kórà àti ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́wàá [250] àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wá síbi àgọ́ ìjọsìn. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tún wá láti ti àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lẹ́yìn. Inú bí Jèhófà gidigidi. Mósè kìlọ̀ pé: ‘Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn èèyàn búburú wọ̀nyí. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí í ṣe tiwọn.’ Àwọn èèyàn náà ṣègbọràn, wọ́n sì kúrò níbi àgọ́ àwọn Kórà, Dátánì àti Ábírámù.
Ìgbà náà ni Mósè wí pé: ‘Nípa èyí ni ẹ̀yin ó fi mọ ẹni tí Jèhófà yàn. Ilẹ̀ máa la ẹnu á sì gbé àwọn èèyàn búburú wọ̀nyí mì.’
Gbàrà tí Mósè dákẹ́ báyìí ni ilẹ̀ lanu. Àgọ́ Kórà àti gbogbo ohun tó ní àti Dátánì àti Ábírámù àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú wọn rì lọ sí ìsàlẹ̀, ilẹ̀ sì pa ẹnu dé mọ́ wọn. Nígbà táwọn èèyàn náà gbọ́ igbe àwọn tó ń rì lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, wọ́n kígbe pé: ‘Ẹ jẹ́ ká sá lọ! Ilẹ̀ lè gbé àwa náà mì pẹ̀lú!’
Kórà àti ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́wàá [250] tó wọ́ tẹ̀ lé e lẹ́yìn ṣì wà lẹ́bàá àgọ́ ìjọsìn náà. Ni Jèhófà bá rọ òjò iná, ó sì jó gbogbo wọn run. Jèhófà wá sọ fún Élíásárì ọmọ Áárónì pé kó mú àwọn ohun táwọn ọkùnrin tó ti kú náà fi ń sun tùràrí kó sì fi wọ́n ṣe àwo irin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ. Èyí ni yóò jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ṣe àlùfáà fún Jèhófà àyàfi Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀.
Ṣùgbọ́n Jèhófà ń fẹ́ kó ṣe kedere pé Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lòun yàn láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà. Nítorí náà, ó wí fún Mósè pé: ‘Jẹ́ kí olórí kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì mú ọ̀pá rẹ̀ wá. Fún ẹ̀yà Léfì, jẹ́ kí Áárónì mú ọ̀pá tirẹ̀ wá. Wá fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀pá yìí sínú àgọ́ ìjọsìn níwájú àpótí ẹ̀rí. Ọ̀pá ẹni tí mo ti yàn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà yó yọ òdòdó.’
Nígbà tí Mósè lọ wò wọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wò ó, ọ̀pá Áárónì ló yọ àwọn òdòdó wọ̀nyí tí èso álímọ́ńdì pípọ́n sì hù lára rẹ̀! Ṣó o ti wá rí ìdí ẹ̀ nísinsìnyí tí Jèhófà fi mú kí ọ̀pá Áárónì yọ òdòdó?