APÁ 4
Láti Ìgbà Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì sí Ìgbà Ìgbèkùn ní Bábílónì
Sọ́ọ̀lù di ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n Jèhófà kọ̀ ọ́, ó sì yan Dáfídì ní ọba dípò rẹ̀. A ó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Dáfídì. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó bá Gòláyátì òmìrán jà. Nígbà tó yá, ó sá lọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba òjòwú. Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì arẹwà kò jẹ́ kó hùwà búburú kan.
Lẹ́yìn èyí, a ó mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nípa Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì, ẹni tó gba ipò Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. Ogójì ọdún ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọba mẹ́ta àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì fi jọba. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pín sí ìjọba méjì, ìjọba àríwá àti ìjọba gúúsù.
Igba ọdún ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [257] ni Ìjọba àríwá, tó ní ẹ̀yà mẹ́wàá, fi wà kí àwọn ará Ásíríà tó pa á run. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [133] lẹ́yìn náà ni Ìjọba ìhà gúúsù tó ní ẹ̀yà méjì pẹ̀lú pa run. Àkókò yìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. Nítorí náà, ìtàn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó lé mẹ́wàá [510] ló wà ní Apá KẸRIN. Lákòókò yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀.
NÍ APÁ YÌÍ
ÌTÀN 56
Sọ́ọ̀lù—Ọba Àkọ́kọ́ Ní Ísírẹ́lì
Ọlọ́run ló yan Sọ́ọ̀lù ní ìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ó kọ̀ ọ́ nígbà tó yá. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú ọ̀rọ̀ Sọ́ọ̀lù.
ÌTÀN 58
Dáfídì àti Gòláyátì
Kì í ṣe kànnàkànnà nìkan ni Dáfídì fi bá Gòláyátì jà, agbára ńlá kan ló lò.
ÌTÀN 59
Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ
Inú Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ dùn sí Dáfídì, àmọ́ nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Sọ́ọ̀lù débi pé ó fẹ́ pa á. Kí ló dé?
ÌTÀN 60
Ábígẹ́lì àti Dáfídì
Ábígẹ́lì pe ọkọ rẹ̀ ní aláìmọ̀kan, àmọ́ ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n gbẹ̀míí ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ náà.
ÌTÀN 61
Wọ́n Fi Dáfídì Jọba
Àwọn ohun tí Dáfídì ṣe àti àwọn ohun tí kò ṣe fi hàn pé ó kúnjú ìwọ̀n láti di ọba Ísírẹ́lì.
ÌTÀN 62
Wàhálà Nínú Ilé Dáfídì
Àṣìṣe kan ṣoṣo péré ni Dáfídì ṣe tó fi kó wàhálà bá òun àti ìdílé rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.
ÌTÀN 64
Sólómọ́nì Kọ́ Tẹ́ńpìlì
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́gbọ́n ní Sólómọ́nì, wọ́n tì í ṣe ohun tí kò mọ́gbọ́n dání, tó sì burú.
ÌTÀN 65
Ìjọba Náà Pín sí Méjì
Gbàrà tí Jèróbóámù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ló ti mú kí àwọn èèyàn náà máa rú òfin Ọlọ́run.
ÌTÀN 67
Jèhóṣáfátì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Kí ló dé tó ṣe jẹ́ pé àwọn akọrin tí kò ní ohun ìjà kankan ló ṣáájú àwọn ọmọ ogun lọ sójú ogun?
ÌTÀN 69
Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkùnrin Alágbára Kan Lọ́wọ́
Ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kí iṣẹ́ ìyanu kan ṣẹlẹ̀.
ÌTÀN 73
Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì
Jòsáyà kò tíì pé ọmọ ogun ọdún nígbà tó ṣe nǹkan kan tó gba ìgboyà.
ÌTÀN 73
Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì
Jòsáyà kò tíì pé ọmọ ogun ọdún nígbà tó ṣe nǹkan kan tó gba ìgboyà.
ÌTÀN 75
Ọmọkùnrin Mẹ́rin Ní Bábílónì
Wọ́n ṣe ohun tó tọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó wọn kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn.
ÌTÀN 76
Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run
Kí ló dé tí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ísírẹ́lì pa Jerúsálẹ́mù run?