Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 66

Jésíbẹ́lì—Ayaba Búburú

Jésíbẹ́lì—Ayaba Búburú

LẸ́YÌN tí Jèróbóámù Ọba kú, gbogbo ọba yòókù tó jẹ lórí ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà ní àríwá ló burú. Áhábù Ọba ló burú jù nínú gbogbo àwọn ọba yẹn. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀? Ìdí pàtàkì kan ni ti ìyàwó rẹ̀, Jésíbẹ́lì Ayaba búburú.

Jésíbẹ́lì kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Ọmọbìnrin ọba Sídónì ni. Báálì, ọlọ́run èké, ló ń sìn, ó sì mú kí Áhábù àti ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa sin Báálì pẹ̀lú. Jésíbẹ́lì kórìíra Jèhófà ó sì pa púpọ̀ nínú àwọn wòlíì rẹ̀. Ṣe làwọn mìíràn ní láti sá pa mọ́ sínú ihò òkúta kó má bàa pa wọ́n. Bí Jésíbẹ́lì bá ń fẹ́ ohun kan, ó tiẹ̀ lè pa èèyàn kó bàa lè rí ohun náà.

Lọjọ́ kan, inú Áhábù bà jẹ́ gan-an. Nítorí náà, Jésíbẹ́lì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tí inú rẹ fi bà jẹ́ lónìí?’

Áhábù dáhùn pé: ‘Nítorí ohun tí Nábótì sọ fún mi ni. Mo fẹ́ ra ọgbà àjàrà rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó sọ pé òun kò lè tà á fún mi.’

Jésíbẹ́lì fèsì pé: ‘Má dààmú ara rẹ. Màá gbà á fún ẹ.’

Nítorí náà, Jésíbẹ́lì kọ̀wé sí àwọn ìjòyè kan ní ìlú ibi tí ọkùnrin tó ń jẹ́ Nábótì yẹn ń gbé. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ mú kí àwọn èèyàn lásán kan wí pé Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ mú Nábótì kúrò ní ìlú kẹ́ ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.’

Kété tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé Nábótì ti kú, ó sọ fún Áhábù pé: ‘Nísinsìnyí lọ gba ọgbà àjàrà rẹ̀.’ Ṣé o kò gbà pé ó yẹ kí Jésíbẹ́lì jẹ ìyà fún ṣíṣe irú ohun tó burú bẹ́ẹ̀?

Nítorí náà, nígbà tó yá, Jèhófà rán ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jéhù láti jẹ ẹ́ ní ìyà. Nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé Jéhù ń bọ̀, ó kun ojú rẹ̀, ó sì gbìyànjú láti ṣe ara lọ́ṣọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jéhù dé tó sì rí Jésíbẹ́lì ní ojú fèrèsé, ó ké sí àwọn ọkùnrin tó wà ní ààfin pé: ‘Ẹ jù ú sí ìsàlẹ̀!’ Àwọn èèyàn náà ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bó o ti ń wò ó nínú àwòrán yìí. Wọ́n jù ú sí ìsàlẹ̀, ó sì kú. Ìgbẹ̀yìn ayé Jésíbẹ́lì Ayaba búburú nìyẹn o.