Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 95

Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Ń Kọ́ni

Ọ̀nà Tí Jésù Gbà Ń Kọ́ni

NÍ ỌJỌ́ kan Jésù sọ fún ọkùnrin kan pé ó gbọ́dọ̀ fẹ́ràn aládùúgbò rẹ̀. Ọkùnrin yẹn béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: ‘Ta ni aládùúgbò mi?’ Jésù mọ ohun tí ọkùnrin yìí ń rò. Ọkùnrin yẹn rò pé àwọn èèyàn tí àwọn jọ jẹ́ ìran àti ìsìn kan náà ni aládùúgbò òun. Nítorí náà jẹ́ ká wo ohun tí Jésù fi fún un lésì.

Nígbà mìíràn Jésù máa ń pa ìtàn láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ohun tó ṣe gan-an nìyẹn. Ó sọ ìtàn kan nípa Júù kan àti ará Samáríà kan. A ti kẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ò fẹ́ràn àwọn ará Samáríà. Bí ìtàn tí Jésù sọ ṣe lọ rèé:

Ní ọjọ́ kan ọkùnrin Júù kan ń lọ ní ọ̀nà òkè kan sí Jẹ́ríkò. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́ṣà dá a lọ́nà. Wọ́n gba gbogbo owó rẹ̀, wọ́n sì lù ú títí tó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.

Lẹ́yìn náà àlùfáà Júù kan gba ọ̀nà ibẹ̀ kọjá. Ó rí ọkùnrin tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán yìí. Kí ni ìwọ rò pé ó ṣe? Kò tiẹ̀ wò ó lẹ́ẹ̀méjì, ó kan bọ́ sí ọ̀nà òdìkejì ni, ó sì ń bá tiẹ̀ lọ. Ìgbà náà ni ọkùnrin kan tó jẹ́ onísìn paraku dé ibẹ̀. Ọmọ Léfì lọkùnrin yìí. Ṣé òun náà dúró? Rárá o, kò dúró láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọkùnrin tí wọ́n lù tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán yìí. Wò wọ́n, àwọn ló ń lọ lọ́ọ̀ọ́kán yẹn.

Ṣùgbọ́n wo ẹni tó wà pẹ̀lú ọkùnrin tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán yìí. Ará Samáríà ni ọkùnrin yìí. Ó ń ran ọkùnrin Júù yẹn lọ́wọ́. Ó ń bá a fi oògùn sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbé Júù yẹn lọ sí ibi tó ti máa lè sinmi tí wọ́n á ti lè tọ́jú rẹ̀.

Lẹ́yìn tí Jésù parí ìtàn rẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tó ń sọ ìtàn yìí fún pé: ‘Èwo nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ìwọ rò pé ó hùwà bí aládùúgbò sí ọkùnrin tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán yẹn? Ṣé àlùfáà yẹn ni, àbí ọmọ Léfì àbí ará Samáríà yẹn?’

Ọkùnrin yìí dáhùn pé: ‘Ọkùnrin ará Samáríà ni. Ó ṣàánú ọkùnrin tó ń kú lọ yẹn.’

Jésù sọ fún un pé: ‘Òótọ́ lo sọ. Nítorí náà lọ, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ sáwọn ẹlòmíì.’

Ṣé ìwọ náà fẹ́ràn ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni? Àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀pọ̀ ohun pàtàkì bá a bá ń fetí sí ohun tí Jésù sọ nínú Bíbélì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?