ÌTÀN 109
Pétérù Lọ Sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù àti díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló wà lórí ìdúró yẹn. Ṣùgbọ́n kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi wólẹ̀ fún Pétérù? Ṣó yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣó o mọ ọkùnrin ọ̀hún?
Kọ̀nílíù lorúkọ rẹ̀. Òun ni olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù. Kọ̀nílíù ò mọ Pétérù rí, ṣùgbọ́n áńgẹ́lì kan sọ fún un pé kó ránṣẹ́ pe Pétérù wá sílé rẹ̀. Jẹ́ ká wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́.
Júù ni gbogbo àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n Kọ̀nílíù kì í ṣe Júù. Síbẹ̀, ó fẹ́ràn Ọlọ́run, ó máa ń gbàdúrà sí i, ó sì tún máa ń ṣe àwọn èèyàn lóore lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́sàn-án ọjọ́ kan áńgẹ́lì kan yọ sí i ó sì sọ fún un pé: ‘Inú Ọlọ́run dùn sí ọ, ó sì máa dáhùn àdúrà rẹ. Rán àwọn èèyàn láti lọ pe ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù wá fún ọ. Ó wà ní Jópà ní ilé Símónì, tó ń gbé lẹ́bàá òkun.’
Kíá ni Kọ̀nílíù rán àwọn èèyàn lọ láti wá Pétérù rí. Ní ọjọ́ kejì, nígbà táwọn ọkùnrin náà ń sún mọ́ Jópà, Pétérù wà lórí òrùlé ilé Símónì. Níbẹ̀, Ọlọ́run mú kí Pétérù ronú pé òun rí aṣọ ńlá fífẹ̀ kan tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run. Oríṣiríṣi ẹranko wà nínú aṣọ náà. Ohun tí òfin Ọlọ́run sì sọ ni pé àwọn ẹranko yẹn kò mọ́ fún jíjẹ, síbẹ̀ ohùn kan wí pé: ‘Dìde, Pétérù. Pa ẹran, kí o sì jẹ.’
Pétérù dáhùn pé: ‘Rárá! Ohun àìmọ́ kankan kò tíì wọ ẹnu mi rí.’ Ṣùgbọ́n ohùn náà sọ fún Pétérù pé: ‘Má ṣe pe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó ti di mímọ́ báyìí ní aláìmọ́.’ Ìgbà mẹ́ta lèyí ṣẹlẹ̀. Bí Pétérù ṣe ń ronú ohun tí gbogbo èyí túmọ̀ sí, àwọn ọkùnrin tí Kọ̀nílíù rán dé sí ilé yẹn, wọ́n sì béèrè Pétérù.
Pétérù sọ̀ kalẹ̀ láti òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ó sì wí pé: ‘Èmi ni ẹni tẹ́ ẹ̀ ń béèrè. Kí lẹ bá wá?’ Nígbà táwọn ọkùnrin náà ṣàlàyé pé áńgẹ́lì kan ló sọ fún Kọ̀nílíù láti ké sí Pétérù wá sí ilé rẹ̀, Pétérù gbà láti bá wọn lọ. Ní ọjọ́ kejì Pétérù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde láti bẹ Kọ̀nílíù wò ní Kesaréà.
Kọ̀nílíù ti pe àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jọ. Nígbà tí Pétérù sì dé, Kọ̀nílíù lọ pàdé rẹ̀. Ó wólẹ̀ ó sì tẹrí ba ní ẹsẹ̀ Pétérù, bó ṣe wà nínú àwòrán yìí. Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé: ‘Dìde; èèyàn ni èmi náà.’ Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì fi hàn pé kò tọ̀nà láti wólẹ̀ ká sì jọ́sìn èèyàn. Jèhófà nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.
Pétérù wá wàásù fún àwọn tó pé jọ. Ó sọ pé: ‘Mo wòye pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ sìn ín.’ Bó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Ọlọ́run rán ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ onírúurú èdè. Èyí ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ Júù tí wọ́n tẹ̀ lé Pétérù lẹ́nu, nítorí pé wọ́n rò pé àwọn Júù nìkan ni Ọlọ́run ṣe ojú rere sí. Nítorí náà èyí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í wo àwọn èèyàn ìran kan bíi pé wọ́n ṣe pàtàkì jù tàbí pé wọ́n dára ju ìran èyíkéyìí mìíràn lọ. Ǹjẹ́ ohun tó dáa kí gbogbo wa máa rántí kọ́ nìyẹn?