APÁ 8
Ohun Tí Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Máa Nímùúṣẹ
Kì í ṣe ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ní ìgbà àtijọ́ nìkan ni Bíbélì sọ, ṣùgbọ́n ó tún sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Àwọn èèyàn ò le sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Ìdí rẹ̀ nìyí tá a fi mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá. Kí ni Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la?
Ó sọ́ nípa ogun ńlá Ọlọ́run. Nínú ogun yìí, Ọlọ́run á mú gbogbo ìwà búburú àtàwọn tó ń hùwa búburú kúrò, ṣùgbọ́n òun á dáàbò bo àwọn tó bá sìn ín. Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run yàn á rí sí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbádùn àlàáfíà àti ayọ̀ àti pé wọn ò tún ní máa ṣàìsàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì ní máa kú.
Ó yẹ kí inú wa dùn pé Ọlọ́run á mú kí Párádísè tuntun kan wà lórí ilẹ̀ ayé, àbí? Ṣùgbọ́n bá a bá máa wà nínú Párádísè yìí, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan. Nínú ìtàn tó kẹ̀yìn nínú ìwé yìí la ti máa kẹ́kọ̀ọ́ ohun tá a máa ṣe ká bàa lè gbádùn àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ní nípamọ́ fáwọn tó ń sìn ín. Nítorí náà, ka APÁ KẸJỌ kó o sì mọ ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la.
NÍ APÁ YÌÍ
ÌTÀN 114
Òpin Gbogbo Ìwà Búburú
Kí ló dé tí Ọlọ́run ṣe rán àwọn ọmọ ogun, tí Jésù ṣáájú wọn, lọ sí ogun Amágẹ́dọ́nì?
ÌTÀN 115
Párádísè Tuntun Lórí Ilẹ̀ Ayé
Àwọn èèyàn ti gbé nínú Párádísè rí ní ayé, ó sì tún máa ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.