Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Esia ati Aarin Gbungbun Ila Oorun Aye

Esia ati Aarin Gbungbun Ila Oorun Aye
  • ILẸ̀ 48

  • IYE ÈÈYÀN 4,315,759,010

  • IYE AKÉDE 703,271

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 732,106

Ó Bi Í Bóyá Òun Lè Pe Àwọn Míì Wá

Nígbà tó ku ọjọ́ méjì kí Ìrántí Ikú Kristi wáyé ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà, arákùnrin kan fi ìwé pe ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìgbọ́kọ̀sí. Mùsùlùmí ni ọkùnrin náà, ó sì béèrè bóyá òun lè pe àwọn míì wá torí pé ìwé ìkésíni kan ṣoṣo ni wọ́n fún òun. Arákùnrin náà sọ fún un pé ó lè pe àwọn míì wá. Ọkùnrin náà wá sọ pé àwọn tó wà nínú ìdílé òun pọ̀, ó sì gba ìwé ìkésíni púpọ̀ sí i. Arákùnrin náà fún un ní ogún [20] lára ìwé ìkésíni náà, ó sì ṣàlàyé fún un pé Ìrántí Ikú Jésù la fẹ́ ṣe, gbogbo èèyàn la sì pè, wọn ì báà jẹ́ ẹlẹ́sìn Kristẹni tàbí Mùsùlùmí. Ọkùnrin náà fèsì pé òun máa mú nǹkan bí ọgọ́ta [60] sí àádọ́rin [70] èèyàn wá.

Ọ̀tàlénígba ó dín méjìlá [248] èèyàn ló wà níkàlẹ̀ nígbà tí àsọyé Ìrántí Ikú Kristi náà bẹ̀rẹ̀. Kò sì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ ni ọkùnrin yìí kó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn dé: ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé, àgbà àti obìnrin kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bímọ. Ṣe ni wọ́n gba àwọn ọkọ̀ èrò tó gbé wọn wá sí òtẹ́ẹ̀lì tá a ti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ òtẹ́ẹ̀lì náà rí àwọn èrò tó ń ya bọ̀ yìí, wọn ò kọ́kọ́ gbà kí wọ́n wọlé. Wọ́n ń wò ó pé kí làwọn Mùsùlùmí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fẹ́ wá ṣe níbi ìpàdé Kristẹni. Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi han àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, wọ́n gbà kí wọ́n wọlé, wọ́n sì tẹ̀ lé wọn dé inú gbọ̀ngàn tí a lò. Nǹkan bí ọgọ́ta [60] lára wọn ló ráyè wọlé torí pé gbọ̀ngàn náà ti kún fọ́fọ́.

Ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, arákùnrin wa pa dà lọ sọ́dọ̀ ọ̀gbẹ́ni tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìgbọ́kọ̀sí náà, ó sì bi í bóyá àwọn èèyàn tó tẹ̀ lé e wá gbádùn àsọyé náà. Ó dáhùn pé ojú kọ́kọ́ ń ti ọ̀pọ̀ lára wọn nígbà tí wọ́n dé, àmọ́ bí wọ́n ṣe ṣe sí wọn níbẹ̀ wú wọn lórí gan-an torí pé gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ níwà ọmọlúwàbí, wọ́n kí wọn dáadáa, wọ́n sì tún bọ̀ wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ṣe tán. Arákùnrin náà wá pè é síbi àkànṣe àsọyé tó wáyé lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e. Ogójì [40] èèyàn ló tún bá ọkùnrin yìí wá lára àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Torí pé ìpàdé náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí kí wọ́n tó dé, àwọn alàgbà pinnu láti tún àsọyé náà sọ lọ́jọ́ yẹn. Alága pa dà ké sí alásọyé, ó ṣàlàyé ṣókí nípa ohun tí àsọyé náà dá lé, ó pe orin, wọ́n sì gbàdúrà. Alásọyé náà lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tètè yé àwọn Mùsùlùmí jálẹ̀ àsọyé náà, irú bí “Ìwé Mímọ́” dípò “Bíbélì” àti “Ànọ́bì Ísá” dípò “Jésù.”

Nígbà tó yá, alàgbà kan lọ sílé ọ̀gbẹ́ni tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìgbọ́kọ̀sí náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run láti fi jíròrò Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn méjìlá míì tún dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjíròrò náà, títí kan àwọn obìnrin tó jẹ́ Mùsùlùmí àtàwọn ọmọdé mélòó kan.

Ìwé Tí Àwọn Èrò Ọkọ̀ Lè Máa Kà

Orílẹ̀-Èdè Mòǹgólíà: Wọ́n yọ̀ǹda pé kí àwọn ará máa fi ìwé síbi ìjókòó fáwọn èrò ọkọ̀

Àwọn ọkọ̀ èrò tó ń gbéra nílùú Ulaanbaatar, ní orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà, máa ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Ìrìn àjò náà máa ń gbà wọ́n tó ọjọ́ méjì. Àwọn èrò ọkọ̀ máa ń wòran látojú fèrèsé tàbí kí oorun gbé wọn lọ. Wọn kì í fún wọn ní ìwé kankan kà bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aráàlú náà fẹ́ràn ìwé kíkà. Torí náà, àwọn arákùnrin kan láti Ìjọ Songinokhairkhan lọ bá àwọn awakọ̀ èrò náà, wọ́n sì sọ fún wọn pé: “A fẹ́ fún yín láwọn ìwé kan tó dáa gan-an. Téèyàn bá wọ ọkọ̀ òfuurufú, wọ́n sábà máa ń fi ìwé téèyàn lè kà síbi ìjókòó kọ̀ọ̀kan. Tẹ́ ẹ bá ronú pé àwọn èrò ọkọ̀ yín máa nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà, a lè bá wọn fi ìwé tí wọ́n lè kà síbi ìjókòó wọn.” Mẹ́jọ lára àwọn awakọ̀ náà ló gbà pé ká fi ìwé sínú ọkọ̀ wọn. Èyí mú kí àwọn ará fi ìwé ìròyìn mọ́kàn-dín-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [299] àti ìwé pẹlẹbẹ mẹ́rìn-lé-lógóje [144] sóde. Wọ́n tún ṣètò láti máa lọ fi àwọn ìwé ìròyìn tuntun tó bá ń jáde síbẹ̀.

Ọ̀tọ̀ Lẹni Tí Wọ́n Lọ Bá

orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà, wọ́n rán àwọn alàgbà méjì pé kí wọ́n lọ bẹ arábìnrin kan tó ti di akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ọdún mẹ́jọ wò. Torí pé wọn ò tíì rí arábìnrin náà rí, àwọn alàgbà yìí pè é lórí fóònú, wọ́n sì sọ fún un pé àwọn á wá bá a ní ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ láàárín ọjà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn káàkiri àwọn ọ̀nà tóóró tó jọra tó kúnnú ọjà náà, wọ́n rí ṣọ́ọ̀bù kan tó jọ èyí tí arábìnrin náà júwe fún wọn. Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n rí obìnrin kan tó fi Bíbélì sórí tábìlì, obìnrin náà sì kí wọn dáadáa. Lẹ́yìn tí wọ́n béèrè orúkọ obìnrin náà àti ìdílé tó ti wá títí kan ọjọ́ orí àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, àwọn arákùnrin yìí parí èrò pé òun ni arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ náà. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni o, arákùnrin yín ni wá.”

Ọ̀rọ̀ yìí rú obìnrin náà lójú, ó sì sọ fún wọn pé: “Kristẹni lèmi náà.” Bó ṣe dáhùn yìí rí bákan lójú àwọn arákùnrin náà. Síbẹ̀, wọ́n fún un ní àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì, ó sì dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ wọn. Àmọ́, bí àwọn arákùnrin yìí ṣe ń kúrò níbẹ̀, wọ́n wá rí i pé ọ̀tọ̀ ni ṣọ́ọ̀bù táwọn lọ! Nọ́ńbà ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n fẹ́ lọ ni 2202, àmọ́ 2200 ni nọ́ńbà èyí tí wọ́n lọ. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà sọ pé: “Àyà mi là gààrà, ó sì ṣe mí bíi pé àwọn áńgẹ́lì ló ní ká yà sí ṣọ́ọ̀bù yẹn. Orúkọ kan náà ni obìnrin yẹn àti arábìnrin wa ń jẹ́, ọmọ ìlú kan náà ni wọ́n, ọjọ́ orí ọmọ àwọn méjèèjì kò sì fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra! Ká ní orúkọ obìnrin náà tàbí orúkọ ìlú rẹ̀ yàtọ̀ sí ti arábìnrin wa ni, à bá ti mọ̀ pé òun kọ́ lẹni tá à ń wá.” Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rí arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ tó ti ń retí wọn ní ṣọ́ọ̀bù kẹta sí ti obìnrin náà.

“Ó yà mí lẹ́nu pé wọ́n lè wá mi wá, mo wá rí i pé Jèhófà ò gbàgbé mi, láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí mo fi jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ sí”

Àṣìṣe tí wọ́n ṣe yìí mú kí obìnrin tí wọ́n yà sọ́dọ̀ rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ, ó sì ń wá sí òde ẹ̀rí déédéé. Ó ní, “Ó yà mí lẹ́nu pé wọ́n lè wá mi wá, mo wá rí i pé Jèhófà ò gbàgbé mi, láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí mo fi jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ sí.”

Wọ́n Lo Àtẹ̀jíṣẹ́ Nígbà Tí Ojú Ọjọ́ Kò Bára Dé

Orílẹ̀-Èdè Philippines: Arákùnrin Greg ń tẹ àtẹ̀jíṣẹ́

Greg àti Alma kó lọ sí erékùṣù Catanduanes tó wà ní orílẹ̀-èdè Philippines láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Òkè pọ̀ ní àgbègbè ibẹ̀, torí náà, Greg àti Alma máa ń rin ìrìn kìlómítà mọ́kàndínlógún [19] kí wọ́n tó dé àwọn ibì kan láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Nígbà míì sì rèé, wọ́n máa ń wa ọkọ̀ ọlọ́pọ́n fún wákàtí méjì kí wọ́n lè lọ wàásù láwọn erékùṣù míì. Àmọ́ ìrìn yìí kì í rọrùn nígbà òjò. Dípò kí Greg àti Alma jókòó sílé láìwàásù, wọ́n máa ń lo àǹfààní ẹ̀dínwó táwọn ilé iṣẹ́ tẹlifóònù alágbèéká fi ṣe ìpolówó ọjà, èyí tó mú kí wọ́n lè lo iye àtẹ̀jíṣẹ́ tí wọ́n bá fẹ́ láìnáwó rẹpẹtẹ.

Arákùnrin Greg sọ pé orúkọ òun lòun kọ́kọ́ máa ń sọ nínú àtẹ̀jíṣẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, òun á wá sọ pé, “Mo fẹ́ sọ ohun kan fún yín látinú Bíbélì.” Ìwé Jòhánù 17:3 wà lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti rí pé ó wúlò gan-an. Lẹ́yìn tó bá ti fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ, ó máa ń béèrè ìbéèré méjì pé: Ta ni Ọlọ́run tòótọ́? àti Ta ni Jésù Kristi? Á wá ní kí onítọ̀hún fèsì. Bí ẹni náà bá fèsì, Greg á tún fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì ránṣẹ́ sí i, irú bíi Sáàmù 83:18. Bí onítọ̀hún bá ṣì ń dá èsì pa dà, Greg á bi í bóyá òun lè pè é sórí fóònù káwọn lè máa bá ìjíròrò náà lọ. Greg àti Alma sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fèsì.

Obìnrin kan tí Greg àti Alma kàn sí nípasẹ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè látinú Bíbélì, torí náà, wọ́n fi àtẹ̀jíṣẹ́ tó pọ̀ ránṣẹ́ síra wọn. Ó sì yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó yá. Obìnrin yìí sọ ohun tó ń kọ́ fún ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àti ìbátan rẹ̀ kan. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá.