À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ
Yúróòpù
-
ILẸ̀ 47
-
IYE ÈÈYÀN 743,421,605
-
IYE AKÉDE 1,614,244
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 842,091
Wọ́n Ò Mọ̀ Pé Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí, Àmọ́ Ó Pa Dà Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ayọ̀ àwọn ará kọjá àfẹnusọ nígbà àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní ìlú London ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Tonílé-tàlejò ni inú wọn ń dùn ṣìnkìn. Andrew àti Elizabeth lọ sí ọ̀kan lára àwọn òtẹ́ẹ̀lì tó wà ní London kí wọ́n lè kí àwọn ará tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀. Bí wọn ṣe rí obìnrin kan tó múra lọ́nà tó yááyì ni Elizabeth dì mọ́ ọ tọ̀yàyà-tọ̀yàyà. Wọ́n rò
pé ọ̀kan lára àwọn tó wá sí àpéjọ ni, àmọ́ ṣe ni obìnrin náà ta kìjí. Ni Elizabeth bá bẹ̀ ẹ́ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má bínú. Mo rò pé ara àwọn tó wá sí àpéjọ ni yín ni.”Obìnrin náà fèsì pé: “Àpéjọ wo nìyẹn o?”
Elizabeth bá nawọ́ sí àmì tá a kọ sí ibi ìgbàlejò láti fi kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàbọ̀. Inú Elizabeth dùn nígbà tí obìnrin náà fèsì pé: “Ṣé pé èmi náà jọ ọ̀kan lára wọn? Inú mi mà dùn o.”
Ibi tí àwọn méjèèjì ti jọ ń sọ̀rọ̀ ni Elizabeth ti mọ̀ pé Vivien ni obìnrin yìí ń jẹ́ àti pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni Vivien ń gbé tẹ́lẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló tún jẹ́ fún arábìnrin wa pé àdúgbò tóun ń gbé nilé obìnrin náà wà. Vivien gbà pé kí wọ́n máa wá kọ́ òun àti àwọn ọmọ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí Elizabeth ṣe dì mọ́ Vivien tọ̀yàyà-tọ̀yàyà lọ́jọ́sí ni Vivien ṣe kí Andrew àti Elizabeth nígbà tí wọ́n lọ bá a nílé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n pàdé ní òtẹ́ẹ̀lì yẹn wọ Vivien lọ́kàn gan-an. Nígbà tí Andrew àti Elizabeth fi ìwe Bíbélì Fi Kọ́ni han Vivien, ẹnu yà wọ́n nígbà tó sọ pé òun ní ìwé náà, òun sì fi ń kọ́ àwọn ọmọ òun mẹ́rin. Ni wọ́n bá sọ pé a máa ń fi ìwé náà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Kíá ni Vivien fèsì pé: “Kí la tún ń dúró ṣe? Ó yá, ẹ jẹ́ á bẹ̀rẹ̀.”
Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Arákùnrin Kan Tó Jẹ́ Ẹ̀yà Roma
Oṣù November 2014 la dá ìjọ àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè Romany sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Slovakia, àwọn akéde mọ́kànlélógún [21] tó ń sọ èdè Romany ló sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká kan tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Abúlé kan náà sì ni gbogbo wọ́n ti wá. Ní ìjọ tó ń sọ èdè Romany yẹn, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti márùndínlọ́gọ́rùn-ún [495]
ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Arákùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi kọ̀wé pé:“Ọ̀kan lára ẹ̀yà Roma ni mí. Ìlú Žehra ní Slovakia ni mo ti wá. Àwọn òyìnbó tó ń gbé ládùúgbò mi sábà máa ń fi ojú alákòóká, ọ̀bùn, olè àti òpùrọ́ wo àwa ẹ̀yà Roma. Nígbà tí mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ẹni tó ń bójú tó ṣọ́ọ̀ṣì náà lé mi dànù ó sì sọ pé irú mi kọ́ ni wọ́n ń wá níbẹ̀. Àìmọye ìgbà ni irú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀. Bí àwọn òyìnbó sì ṣe máa ń fi ojú òkúùgbẹ́ wò wá yìí jẹ́ kí èmi náà ní èrò tí ò dáa nípa wọn. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí n wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo rò pé bíi ti àtẹ̀yìnwá ló máa rí. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé kí n tiẹ̀ tó wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba rara ni òyìnbó kan ti wá bọ̀ mí lọ́wọ́ tó sì kí mi káàbọ̀ tọ̀yàyà-tọyàyà. Ọkàn mi ò pa pọ̀ gbogbo bí ìpàdé yẹn ṣe ń lọ. Mo ṣáà ń rò ó pé, ‘Ìyẹn èmi náà. Kí ló dé táwọn ará ibí yìí ṣe nífẹ̀ẹ́ mi báyìí?’
“Mi ò sùn mọ́jú ọjọ́ yẹn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn ni mò ń rò. Mó bá pinnu pé àfi kí ń pa dà lọ bóyá èèṣì lásán ni ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ àkọ́kọ́ yẹn. Àwọn tí mo pàdé lẹ́ẹ̀kejì yìí tiẹ̀ tún yá mọ́ọ̀yàn ju tàkọ́kọ́, ṣe ni wọ́n ń bá mi sọ̀rọ̀ bíi pé a ti mọra tipẹ́. Àtigbà yẹn ni mi ò ti pa ìpàdé jẹ títí mo fi ṣèrìbọmi. Ìfẹ́ táwọn ará ní sí mi ò yingin lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, ṣe ló ń peléke sí i. Oúnjẹ táwọn alára ò rí jẹ ni wọ́n máa ń fún mi jẹ nígbà míì. Mo pinnu pé, bí iná ń jó, bí ìjì ń jà, Jèhófà ni Ọlọ́run tí màá máa sìn, inú ètò yìí sì ni màá kú sí.”
Ó Gbàdúrà Pé Kí Òun Lè Wàásù, Jèhófà Sì Gbọ́ Ọ
Nígbà tí Arábìnrin Aysel ń rin ìrìn àjò nínú bọ́ọ̀sì láti Ganja sí Baku ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé ó wu òun láti wàásù fún ẹnì kan báwọn ṣe ń lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Aysel ní àyè tiẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì, obìnrin kan ṣáà takú pé àfi kí Aysel wá jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ òun. Aysel bẹ̀rẹ̀
sí í bá obìnrin yìí tàkurọ̀sọ títí tó fi darí ìjíròrò náà sí Bíbélì. Obìnrin yìí sọ pé òun fẹ́ràn Jésù, àti pé ó wu òun láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Àwọn méjèèjì gba nọ́ńbà fóònú ara wọn, wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe tún ríra. Obìnrin yìí bẹ Aysel pé kó bá òun mú Bíbélì kan wá tó bá ṣeé ṣe.Nígbà tí Aysel pa dà sí Ganja, ó lọ wo obìnrin yìí níbi iṣẹ́ rẹ̀. Obìnrin yìí wá sọ pé òun ní “ìwé àdúrà” kan tí òun máa ń kà lójoojúmọ́. Ó ya Arábìnrin Aysel lẹ́nu gan-an nígbà tó wá mọ̀ pé ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 2013 ni ìwé tí obìnrin yìí ń pè ní ìwé àdúrà. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ṣe ni inú Aysel dùn pé Jèhófà fún òun nígboyà láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà.
Lẹ́tà Ìdúpẹ́ Látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́wọ̀n Kan
A rí lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí gbà láti orílẹ̀-èdè Sípéènì:
“Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún iṣẹ́ takuntakun tí ẹ̀ ń ṣe kí onírúurú èèyàn lè gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.
“Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sẹ́yìn ni mo kọ́kọ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé ní ìlú Tiranë ní orílẹ̀-èdè Alibéníà. Ó yà mí lẹ́nu pé Ẹlẹ́rìí kan gbójú-gbóyà láti wá bá àwa ọmọọ̀ta mẹ́wàá sọ̀rọ̀ níbi tá a kóra jọ sí. Kò sẹ́ni tó tó bẹ́ẹ̀ láti sún mọ́ wa, síbẹ̀ arákùnrin yẹn wá bá wa láìka gbogbo nǹkan ìjà tá a kó dání. Tìgboyà-tìgboyà ló bá wa sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ìgboyà tó ní yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.
“Ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn ní orílẹ̀-èdè Sípéènì níbí, Ẹlẹ́rìí kan wá bá mi ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó sì béèrè bóyá màá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo ní kò burú, àtìgbà yẹn sì ni ìgbà ọ̀tun ti dé bá mi. Mi ò kì í ṣe oníjàgídí-jàgan bíi ti ìgbà kan mọ́. Ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí tí mo ti ṣe ìjàngbọ̀n kẹ́yìn. Mo ti wá mọ Jèhófà, mo sì ti ní ohun gidi tí mò ń fi ayé mi ṣe. Mo ń sapá láti wà ní àlááfíà pẹ̀lú àwọn tó
yí mi ká, ó sì ti lé lọ́dún kan tí mo ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ọdún méjìlá [12] tí mo ti wà lẹ́wọ̀n, mi ò ní irú ayọ̀ àti ìbàlẹ̀-ọkàn tí mo ní lẹ́nu ọdún mẹ́rin tó kọjá yìí rí. Ojoojúmọ́ ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún èyí.
“Bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn ni mo wo àwọn fídíò kan lórí ìkànnì jw.org. Fídíò arákùnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wọ̀ mí lákínyẹmí ara. Mo máa ń mú nǹkan mọ́ra gan-an, àmọ́ mi ò lè mú ẹkún yìí mọ́ra nígbà tí mo rí àwọn ìyípadà tí arákùnrin yìí ṣe, ṣe ni omi bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú mi.
“Kí Jèhófà máa bù kún ìsapá yín láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ onírúurú èèyàn bẹ́ẹ ṣe ń tú u sí oríṣiríṣi èdè àti bẹ́ẹ ṣe ń bẹ àwa tá a wà lẹ́wọ̀n wò.
“Ẹ ṣeun gan-an.”
“Ọkàn Mi Ṣẹ̀ṣẹ̀ Balẹ̀ Ni!”
Orílẹ̀-èdè Sweden ni Felicity tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin [68] ń gbé. Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé ayé mi ò nítumọ̀, mo ṣáà kàn ń sùn, mo sì ń jí lójoojúmọ́. Mò ń sapá gan-an láti ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀-ọkàn, àmọ́ pàbó ló ń já sí.” Àwọn ohun tí ẹ̀sìn Kátólíìkì kọ́ ọ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò oríṣiríṣi ìsìn títí tó fi dí olóòṣà paraku.
Nígbà tí Felicity ò rí bá-ti-ṣé, ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò débi pé ó ronú àtigbẹ̀mí ara rẹ̀. Ó sọ pé: “Pẹ̀lú omijé lójú ni mo ké pe Ọlọ́run ní ohùn rara pé kó sọ ohun tó fẹ́ kí ń ṣe fún mi. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìyẹn ni ẹnì kan rọra kan ilẹ̀kùn mi. Bí mo ṣe ṣílẹ̀kùn ni ọkùnrin kan fi ẹ̀rín músẹ́ béèrè bóyá màá fẹ́ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mo sọ lọ́kàn mi pé: ‘Oò, ìwọ Ọlọ́run, àwọn Ajẹ́rìí kọ́ ni mo ní kó o rán sí mi.’”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe é bíi pé kó tilẹ̀kùn, ó ṣáà fetí sílẹ̀, ó sì gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ó sọ pé: “Àfi bíi pé mi ò ka Bíbélì rí.” Felicity ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè tá a ṣe ní Sweden lọ́dún 2014, ó wá sọ pé: “Ohun tí mò ń wá kiri látọdún yìí rèé, ọkàn mi ṣẹ̀ṣẹ̀ balẹ̀ ni.”