Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2016

“Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.”Hébérù 13:1

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2016

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn . . . yóò kórìíra ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. . . . Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mát. 24:10, 12) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí fi hàn pé láwọn ọdún tó máa ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, ẹ̀mí ìkórìíra ló máa gbòde kan láàárín àwọn èèyàn náà. Àmọ́, ìfẹ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní láàárín ara wọn làwọn èèyàn fi máa dá wọn mọ̀. (Jòh. 13:35) Ẹ wo bí inú àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n ka ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó fi gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ jọba láàárín wọn, tó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe jẹ̀ kí ìfẹ́ ọ̀hún tutù.

Ní báyìí, a ti sún mọ́ ìgbà tí Jèhófà máa pa gbogbo ayé Sátánì run. Bíi tàwọn ará wa ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà ń gbé láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó, tó nífẹ̀ẹ́ adùn àti ara wọn nìkan, àmọ́ tí ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn ò ju bíńtín. (2 Tím. 3:1-4) Síbẹ̀, ibi yòówù kéèyàn wò láyé, ṣe ni okùn ìfẹ́ tó so àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pọ̀ túbọ̀ ń lágbára. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ara wa, nípa bẹ́ẹ̀ àá máa fìyìn fún Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́.