APÁ 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tó Ta Yọ Tí Jésù Ṣe ní Gálílì
‘Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pé: “Ìjọba Ọ̀run ti sún mọ́lé.”’—Mátíù 4:17
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 22
Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Mẹ́rin Di Apẹja Èèyàn
Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n pa òwò ẹja pípa tì, kí wọ́n sì di apẹja èèyàn.
ORÍ 23
Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu ní Kápánáúmù
Nígbà tí Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ó ní káwọn ẹ̀mí èṣù náà má ṣe sọ fún àwọn èèyàn pé ọmọ Ọlọ́run lòun. Kí nìdí?
ORÍ 24
Jésù Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Gbòòrò Sí I ní Gálílì
Àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ Jésù kó lè wò wọ́n sàn, àmọ́ ó ṣàlàyé fún wọn pé kì í ṣe ìdí pàtàkì tí òun fi wá sáyé nìyẹn.
ORÍ 25
Jésù Fàánú Hàn sí Adẹ́tẹ̀ Kan, Ó sì Wò Ó Sàn
Ọ̀rọ̀ ṣókí tí Jésù sọ fi hàn pé aláàánú ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wò sàn.
ORÍ 28
Kí Nìdí Tí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Kò Fi Gbààwẹ̀?
Jésù lo àpèjúwe kan nípa àpò awọ láti fi dáhùn ìbéèrè náà.
ORÍ 29
Ṣé Èèyàn Lè Ṣe Ohun Tó Dáa Lọ́jọ́ Sábáàtì?
Kí nìdí tí àwọn Júù fi ṣenúnibíni sí Jésù torí pé ó wo ọkùnrin kan tó ti ń ṣàìsàn fún 38 ọdún sàn?
ORÍ 30
Bí Jésù Ṣe Jẹ́ sí Baba Rẹ̀
Àwọn Júù ronú pé ńṣe ni Jésù ń sọ pé òun bá Ọlọ́run dọ́gba, àmọ́ Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Baba tóbi ju òun lọ.
ORÍ 32
Kí Ló Bófin Mu ní Sábáàtì?
Àwọn Sadusí àtàwọn Farisí tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá ara wọn látilẹ̀ gbìmọ̀ pọ̀ láti ta ko Jésù.
ORÍ 33
Jésù Mú Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà Ṣẹ
Kí nìdí tí Jésù fi máa ń sọ fáwọn tó wò sàn pé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ fáwọn míì nípa òun àti ohun tóun ṣe?
ORÍ 38
Jòhánù Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Látẹnu Jésù
Kí nìdí tí Jòhánù Arinibọmi fi béèrè bóyá Jésù ni Mèsáyà? Ṣé Jòhánù ń ṣiyèméjì ni?
ORÍ 39
Jésù Dẹ́bi fún Ìran Aláìgbọràn
Jésù sọ pé ilẹ̀ Sódómù máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ju Kápánáúmù lọ, ìyẹn ìlú tó gbé fúngbà díẹ̀.
ORÍ 40
Ẹ̀kọ́ Nípa Ìdáríjì
Nígbà tí Jésù sọ fún obìnrin kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ aṣẹ́wó pé a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í, ṣé ohun tó ń sọ ni pé èèyàn lè rú òfin Ọlọ́run bó ṣe fẹ́?
ORÍ 43
Àwọn Àpèjúwe Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Jésù sọ àpèjúwe mẹ́jọ kó lè ṣàlàyé onírúurú nǹkan tí Ìjọba ọ̀run túmọ̀ sí.
ORÍ 44
Jésù Mú Kí Ìjì Dáwọ́ Dúró Lórí Òkun
Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni Jésù ń kọ́ wa nípa bí ayé ṣe máa rí nínú Ìjọba rẹ̀ nígbà tó mú kí òkun pa rọ́rọ́, tí ìjì sì dáwọ́ dúró.
ORÍ 46
Obìnrin Kan Rí Ìwòsàn Nígbà Tó Fọwọ́ Kan Aṣọ Jésù
Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó lágbára, aláàánú sì ni.
ORÍ 47
Jésù Jí Ọmọbìnrin Kan Dìde!
Àwọn èèyàn ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó sọ pé ọmọ náà kàn ń sùn ni. Kí ni Jésù mọ̀ táwọn èèyàn náà ò mọ̀?
ORÍ 48
Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu, àmọ́ Àwọn Ará Násárẹ́tì Kò Gbà Á Gbọ́
Kì í ṣe nítorí ẹ̀kọ́ Jésù tàbí nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe làwọn ará Násárẹ́tì fi kọ̀ ọ́, nǹkan míì ló fà á.
ORÍ 49
Ó Wàásù, Ó Sì Dá Àwọn Àpọ́sítélì Lẹ́kọ̀ọ́ ní Gálílì
Kí ló túmọ̀ sí pé ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé’?
ORÍ 50
Wọ́n Ṣe Tán Láti Wàásù Láìka Àtakò Sí
Kí nìdí tí Jésù fi sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n sá lọ síbòmíì tí wọn ò bá bẹ̀rù ikú?
ORÍ 51
Wọ́n Pa Èèyàn Níbi Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Kan
Bí Sàlómẹ̀ ṣe jó wú Hẹ́rọ́dù lórí gan-an débi tó fi ṣèlérí pé òun á fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. Nǹkan burúkú wo ló béèrè?
ORÍ 52
Ó Fi Ìwọ̀nba Búrẹ́dì àti Ẹja Bọ́ Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Èèyàn
Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ débi pé àwọn ìwé ìhìn rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló ròyìn ẹ̀.
ORÍ 53
Alákòóso Kan Tó Láṣẹ Lórí Àwọn Nǹkan Àdáyébá
Kí làwọn àpọ́sítélì rí kọ́ bí Jésù ṣe rìn lórí omi tó sì dá ìjì dúró?
ORÍ 54
Jésù “Ni Oúnjẹ Ìyè”
Kí nìdí tí Jésù fi bá àwọn èèyàn wí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sapá láti wá sọ́dọ̀ ẹ̀?
ORÍ 55
Ọ̀rọ̀ Jésù Ya Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lẹ́nu
Jésù sọ ọ̀rọ̀ kan tó ya àwọn èèyàn lẹ́nu débi pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ fi í sílẹ̀, wọn ò sì tẹ̀ lé e mọ́.
ORÍ 57
Jésù Wo Ọmọbìnrin Kan àti Adití Kan Sàn
Kí nìdí tí obìnrin kan ò fi bínú nígbà tí Jésù fi àwọn tí kì í ṣe Júù wé àwọn ajá kéékèèké?
ORÍ 58
Ó Mú Kí Búrẹ́dì Pọ̀, Ó sì Kìlọ̀ Nípa Ìwúkàrà
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn ọmọ ẹ̀yìn lóye irú ìwúkàrà tí Jésù ń sọ.
ORÍ 59
Ta Ni Ọmọ Èèyàn?
Kí làwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run? Ta ló máa lò wọ́n, báwo ló sì ṣe máa lò wọ́n?
ORÍ 61
Jésù Wo Ọmọkùnrin Tí Ẹ̀mí Èṣù Ń Yọ Lẹ́nu Sàn
Jésù sọ pé àìnígbàgbọ́ ni kò jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lágbára láti lé ẹ̀mí èṣù tó ń yọ ọmọ kan lẹ́nu jáde. Ta ni kò nígbàgbọ́? Ṣé ọmọ náà ni, àbí bàbá ẹ̀, àbí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
ORÍ 62
Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Nípa Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Àwọn ọkùnrin tó jẹ́ àgbàlagbà kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì látara ọmọ kékeré kan.
ORÍ 63
Méjì Lára Ìmọ̀ràn Jésù
Ó sọ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta tó yẹ káwọn arákùnrin gbé láti yanjú ọ̀rọ̀ tó lágbára tó wáyé láàárín wọn.
ORÍ 64
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini
Jésù lo àpèjúwe ẹrú tí kò láàánú náà ká lè rí i pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa dárí ji àwọn míì ní fàlàlà.
ORÍ 65
Jésù Ń Kóni Nígbà Tó Ń Lọ sí Jerúsálẹ́mù
Nígbà tí Jésù ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ló mẹ́nu ba àwọn ohun tó lè dí ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn òun.