ORÍ 56
Kí Ló Ń Sọni Di Aláìmọ́?
MÁTÍÙ 15:1-20 MÁÀKÙ 7:1-23 JÒHÁNÙ 7:1
-
JÉSÙ TÚ ÀṢÍRÍ ÀṢÀ ÀTỌWỌ́DỌ́WỌ́ ÀWỌN JÚÙ
Bí àjọyọ̀ Ìrékọjá ọdún 32 S.K. ṣe ń sún mọ́lé, ọwọ́ Jésù dí gan-an bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ní Gálílì. Ó ṣeé ṣe kó lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ Ìrékọjá bó ṣe wà nínú Òfin. Àmọ́ kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí àwọn Júù ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. (Jòhánù 7:1) Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Gálílì.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Kápánáúmù ni Jésù wà nígbà táwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin wá a wá láti Jerúsálẹ́mù. Kí nìdí tí wọ́n fi rìnrìn àjò yìí? Wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe fẹ̀sùn kan Jésù lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn. Wọ́n bi í pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́? Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í wẹ ọwọ́ wọn tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.” (Mátíù 15:2) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sígbà kankan tí Ọlọ́run sọ pé káwọn èèyàn òun máa wẹ “ọwọ́ wọn títí dé ìgúnpá” kí wọ́n tó jẹun. (Máàkù 7:3) Síbẹ̀, àwọn Farisí gbà pé tẹ́nì kan ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ló dá.
Dípò kí Jésù dá wọn lóhùn ní tààràtà, ṣe ló tọ́ka sí ọ̀kan lára àwọn Òfin Ọlọ́run tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń rú. Ó bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tẹ àṣẹ Ọlọ́run lójú torí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín? Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ’ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’ Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ̀bùn tí mo yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,” kò yẹ kó bọlá fún bàbá rẹ̀ rárá.’”—Mátíù 15:3-6; Ẹ́kísódù 20:12; 21:17.
Àwọn Farisí gbà pé owó, dúkìá tàbí ohunkóhun téèyàn bá yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run jẹ́ ti tẹ́ńpìlì. Kódà kó jẹ́ pé ọwọ́ onítọ̀hún ni ẹ̀bùn náà ṣì wà, wọ́n gbà pé ẹni yẹn ò lè lò ó fún nǹkan míì. Bí àpẹẹrẹ, “kọ́bánì” làwọn Júù máa ń pe ohunkóhun tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ láti mú wá fún Ọlọ́run tàbí tẹ́ńpìlì, ó lè jẹ́ owó tàbí dúkìá. Ọmọ kan lè sọ pé owó tàbí dúkìá òun jẹ́ “kọ́bánì,” ìyẹn lè mú kó gbà pé òun ò lè lò ó fún ohunkóhun míì mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀ ni owó tàbí dúkìá yẹn ṣì wà, àwọn Farisí gbà pé ó lè kọ̀ láti lò ó fáwọn òbí ẹ̀ tó ti dàgbà tí wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ òótọ́ kan ni pé, tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kó ní lè ṣe ojúṣe rẹ̀ fáwọn òbí rẹ̀.—Máàkù 7:11.
Inú bí Jésù torí pé wọ́n ń yí Òfin Ọlọ́run pa dà, ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ ti wá sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín. Ẹ̀yin alágàbàgebè, bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín ló rí gẹ́lẹ́, nígbà tó sọ pé: ‘Àwọn èèyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.’” Ṣe lẹnu àwọn Farisí yẹn wọhò torí wọn ò rí nǹkan kan sọ sí ohun tí Jésù sọ. Jésù wá pe àwọn èrò tó wà níbẹ̀ wá sí tòsí, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, kó sì yé yín: Ohun tó ń wọ ẹnu èèyàn kọ́ ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́, àmọ́ ohun tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde ló ń sọ ọ́ di aláìmọ́.”—Mátíù 15:6-11; Àìsáyà 29:13.
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n dé inú ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bi Jésù pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Farisí kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí o sọ?” Ó fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Baba mi ọ̀run kò gbìn la máa fà tu. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.”—Mátíù 15:12-14.
Ó jọ pé ẹnu ya Jésù nígbà tí Pétérù bi í pé kó túbọ̀ ṣàlàyé ohun tó ń sọni di aláìmọ́, kó lè túbọ̀ yé òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù. Jésù wà sọ pé: “Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ohunkóhun tó bá wọ ẹnu máa ń gba inú ikùn, tí a sì máa yà á jáde sínú kòtò ẹ̀gbin? Àmọ́ ohunkóhun tó bá ń ti ẹnu jáde, inú ọkàn ló ti ń wá, àwọn nǹkan yẹn ló sì ń sọ èèyàn Mátíù 15:17-20.
di aláìmọ́. Bí àpẹẹrẹ, inú ọkàn ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, títí kan ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe, olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ọ̀rọ̀ òdì. Àwọn nǹkan yìí ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́; àmọ́ èèyàn ò lè di aláìmọ́ tó bá jẹun láìwẹ ọwọ́.”—Jésù ò sọ pé kéèyàn jẹ́ onídọ̀tí, kò sì sọ pé kéèyàn má ṣe fọwọ́ kó tó se oúnjẹ tàbí kó tó jẹun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń dẹ́bi fún ìwà àgàbàgebè táwọn aṣáájú ìsìn ń hù bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ rọ́ Òfin Ọlọ́run sẹ́yìn tí wọ́n sì ń gbé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lárugẹ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ìwà burúkú tó ń wá látinú ọkàn èèyàn ló ń sọni di aláìmọ́.