Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 44

Jésù Mú Kí Ìjì Dáwọ́ Dúró Lórí Òkun

Jésù Mú Kí Ìjì Dáwọ́ Dúró Lórí Òkun

MÁTÍÙ 8:18, 23-27 MÁÀKÙ 4:35-41 LÚÙKÙ 8:22-25

  • JÉSÙ MÚ KÍ ÌJÌ DÁWỌ́ DÚRÓ LÓRÍ ÒKUN GÁLÍLÌ

Nígbà tó máa fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti rẹ Jésù torí àtàárọ̀ ló ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ ká sọdá sí èbúté kejì” tó wà ní òdìkejì Kápánáúmù.—Máàkù 4:35.

Apá ìlà oòrùn Òkun Gálílì ni ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gérásà wà. Wọ́n tún máa ń pe agbègbè yẹn ní Dekapólì. Àṣà àwọn Gíríìkì gbilẹ̀ gan-an láwọn ìlú tó wà ní Dekapólì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù náà ń gbé ibẹ̀.

Àwọn èèyàn rí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ kúrò ní Kápánáúmù. Torí náà, àwọn kan gbé ọkọ̀ tẹ̀ lé wọn nígbà tí wọ́n ń sọdá. (Máàkù 4:36) Adágún omi kan tí kò fẹ̀ púpọ̀ ni Òkun Gálílì. Ó gùn tó nǹkan bíi máìlì mẹ́tàlá (13), ó sì fẹ̀ tó máìlì méje. Àmọ́ ó jìn.

Bí Jésù tiẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, ó nílò ìsinmi torí pé àtàárọ̀ ló ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, lẹ́yìn tí ọkọ̀ wọn ṣí, ó lọ sẹ́yìn ọkọ̀ náà, ó fi nǹkan rọrí, ó sì sùn lọ.

Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpọ́sítélì ló mọ bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀, àmọ́ ìrìn àjò yìí ò ní rọrùn fún wọn. Ìdí sì ni pé àpáta ló yí omi náà ká, ojú omi Òkun Gálílì sì máa ń lọ́ wọ́ọ́rọ́. Nígbà míì, afẹ́fẹ́ tó tutù máa ń fẹ́ látorí àwọn àpáta náà, tó bá wá pàdé omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ nísàlẹ̀, á fa ìjì tó le gan-an lórí òkun. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, atẹ́gùn ti ń fẹ́ omi lu ọkọ̀ náà. Bíbélì sọ pé “omi wá ń rọ́ wọnú ọkọ̀ wọn, wọ́n sì wà nínú ewu.” (Lúùkù 8:23) Síbẹ̀, Jésù ò tíì jí!

Àwọn atukọ̀ yìí sapá gan-an kí ọkọ̀ wọn má bàa dà nù, ó ṣe tán kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa wa ọkọ̀ nínú ìjì. Àmọ́ ti ọ̀tẹ̀ yìí yàtọ̀. Ẹ̀rù bà wọ́n débi tí wọ́n fi sáré lọ jí Jésù, wọ́n sì kígbe pé: “Olúwa, gbà wá, a ti fẹ́ ṣègbé!” (Mátíù 8:25) Ní báyìí, àyà wọn ń já gan-an torí wọ́n gbà pé àwọn máa tó rì.

Nígbà tí Jésù jí, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?” (Mátíù 8:26) Lẹ́yìn náà, Jésù bá ìjì àti òkun náà wí, ó ní: “Ó tó! Dákẹ́ jẹ́ẹ́!” (Máàkù 4:39) Bí ìjì náà ṣe rọlẹ̀ nìyẹn tí òkun náà sì pa rọ́rọ́. (Nígbà tí Máàkù àti Lúùkù ń sọ nípa ìtàn alárinrin yìí, wọ́n sọ pé ìjì yẹn ni Jésù kọ́kọ́ bá wí kó tó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé ìgbàgbọ́ wọn kéré.)

Ẹ wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe máa rí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà! Ìṣojú wọn ni omi tó ń ru gùdù yẹn pa rọ́rọ́. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n wá ń sọ fún ara wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an? Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.” Bí wọ́n ṣe sọdá omi náà láìfara pa nìyẹn o. (Máàkù 4:41–5:1) Ó sì ṣeé ṣe káwọn ọkọ̀ ojú omi tó tẹ̀ lé wọn ti pa dà síbi tí wọ́n ti ń bọ̀.

Ẹ ò rí bó ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run lágbára lórí ojú ọjọ́! Nígbà tí Ìjọba ẹ̀ bá dórí ilẹ̀ ayé, gbogbo èèyàn ló máa wà ní àlàáfíà tí ọkàn wọn á sì balẹ̀ torí pé àjálù ò ní dé bá ẹnikẹ́ni mọ́!