ORÍ 93
Ọlọ́run Máa Ṣí Ọmọ Èèyàn Payá
-
ÌJỌBA ỌLỌ́RUN WÀ LÁÀÁRÍN WỌN
-
BÁWO NI NǸKAN ṢE MÁA RÍ TÍ ỌLỌ́RUN BÁ ṢÍ JÉSÙ PAYÁ?
Samáríà tàbí Gálílì ni Jésù ṣì wà. Làwọn Farisí bá bi í nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé. Èrò wọn ni pé Ìjọba yẹn máa dé lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tí gbogbo èèyàn sì máa mọ̀ nípa ẹ̀. Àmọ́, Jésù sọ pé: “Dídé Ìjọba Ọlọ́run kò ní pàfiyèsí tó ṣàrà ọ̀tọ̀; àwọn èèyàn ò sì ní máa sọ pé, ‘Wò ó níbí!’ tàbí, ‘Lọ́hùn-ún!’ Torí pé, wò ó! Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.”—Lúùkù 17:20, 21.
Ohun tí Jésù sọ yẹn lè mú káwọn kan gbà pé inú ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Ìjọba yẹn wà. Àmọ́ ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí kọ́ nìyẹn, torí Ìjọba Ọlọ́run ò sí nínú ọkàn àwọn Farisí tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, Ìjọba náà wà ní àárín wọn torí pé Jésù tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Ọba Ìjọba yẹn wà láàárín wọn.—Mátíù 21:5.
Ó ṣeé ṣe káwọn Farisí yẹn ti kúrò kí Jésù tó ṣàlàyé bí Ìjọba yẹn ṣe máa dé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn, ó ní: “Ọjọ́ ń bọ̀ tó máa wù yín pé kí ẹ rí ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ Ọmọ èèyàn, àmọ́ ẹ ò ní rí i.” (Lúùkù 17:22) Ohun tí Jésù sọ yìí fi hàn pé ó di ọjọ́ iwájú kí Ọmọ èèyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ó lè ti máa ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan bíi pé kó tètè dé. Síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ ní sùúrù dìgbà tí Ọlọ́run ti pinnu pé kí Ọmọ èèyàn dé.
Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àwọn èèyàn á máa sọ fún yín pé, ‘Wò ó lọ́hùn-ún!’ tàbí, ‘Wò ó níbí!’ Ẹ má ṣe jáde lọ, ẹ má sì sáré tẹ̀ lé wọn. Torí bí mànàmáná ṣe ń kọ láti apá kan ọ̀run dé apá ibòmíì ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ èèyàn máa rí ní ọjọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 17:23, 24) Kí ni ò ní jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa tẹ̀ lé àwọn mèsáyà irọ́ kan? Jésù sọ pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti máa mọ̀ nígbà tí Mèsáyà tòótọ́ bá dé. Gbogbo àwọn tó bá sì fọkàn sí i ló máa rí ẹ̀rí tó dájú pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.
Jésù wá lo àfiwé kan nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́ kí wọ́n lè mọ irú ìwà táwọn èèyàn á máa hù lọ́jọ́ iwájú, ó sọ pé: “Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí ní àwọn ọjọ́ Ọmọ èèyàn . . . Bákan náà, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì: wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé. Àmọ́ lọ́jọ́ tí Lọ́ọ̀tì kúrò ní Sódómù, òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run. Bẹ́ẹ̀ náà ló máa rí ní ọjọ́ tí a bá ṣí Ọmọ èèyàn payá.”—Lúùkù 17:26-30.
Jésù ò sọ pé báwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà àti Lọ́ọ̀tì ṣe ń jẹ, tí wọ́n ń mu ló mú kí wọ́n pa run, bẹ́ẹ̀ ni kò sóhun tó burú nínú bí wọ́n ṣe ń rà, tí wọ́n ń tà, tí wọ́n ń gbìn, tí wọ́n sì ń kọ́lé. Ó ṣe tán, Nóà, Lọ́ọ̀tì àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn náà bá wọn lọ́wọ́ sí díẹ̀ lára àwọn nǹkan yìí. Àmọ́, ìṣòro ibẹ̀ ni pé báwọn èèyàn yẹn ṣe ń jẹ tí wọ́n ń mu, wọn ò ronú nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọn ò sì fọkàn sí ìkìlọ̀ tó fún wọn. Torí náà, ṣe ni Jésù ń gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n fọkàn sí ohun tí
Ọlọ́run fẹ́, kí wọ́n sì rí i pé wọ́n ń ṣe é. Jésù wá sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà, ìyẹn ohun táá jẹ́ kí wọ́n máa wà láàyè títí láé nígbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn èèyàn búburú run lọ́jọ́ iwájú.Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nítorí àwọn nǹkan tó wà nínú ayé, ìyẹn “àwọn ohun tó wà lẹ́yìn,” káwọn nǹkan yẹn má bàa pín ọkàn wọn níyà. Torí náà, Jésù sọ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, kí ẹni tó wà lórí ilé, àmọ́ tí àwọn ohun ìní rẹ̀ wà nínú ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó o, bákan náà, ẹni tó bá wà nínú pápá ò gbọ́dọ̀ pa dà sí àwọn ohun tó wà lẹ́yìn. Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:31, 32) Ẹ má gbàgbé pé ó di ọwọ̀n iyọ̀.
Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Ọmọ èèyàn bá di Ọba, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ní òru yẹn, ẹni méjì máa wà lórí ibùsùn kan náà; a máa mú ọ̀kan lọ, àmọ́ a máa pa ìkejì tì.” (Lúùkù 17:34) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run máa gba àwọn kan là, àmọ́ ó máa pa àwọn kan tì, ní ti pé wọ́n máa pa run.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bi Jésù pé: “Ibo ni, Olúwa?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Ibi tí òkú bá wà, ibẹ̀ náà ni àwọn ẹyẹ idì máa kóra jọ sí.” (Lúùkù 17:37) Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan máa dà bí ẹyẹ idì tó máa ń rí ibi tó jìnnà gan-an. Wọ́n máa kóra jọ sọ́dọ̀ Ọmọ èèyàn tó jẹ́ ojúlówó Kristi. Nígbà yẹn, Jésù máa jẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́ torí pé ìgbàgbọ́ wọn lágbára, ìyẹn sì máa gba ẹ̀mí wọn là.