Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 104

Lẹ́yìn Táwọn Júù Gbọ́ Ohùn Ọlọ́run, Ṣé Wọ́n Gba Jésù Gbọ́?

Lẹ́yìn Táwọn Júù Gbọ́ Ohùn Ọlọ́run, Ṣé Wọ́n Gba Jésù Gbọ́?

JÒHÁNÙ 12:28-50

  • Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBỌ́ OHÙN ỌLỌ́RUN

  • OHUN TÓ MÁA PINNU BÍ ỌLỌ́RUN ṢE MÁA DÁ ÈÈYÀN LẸ́JỌ́

Lọ́jọ́ Monday, Nísàn 10, Jésù wà ní tẹ́ńpìlì, ó sọ pé òun ò ní pẹ́ kú. Ó ń ká Jésù lára pé ikú òun lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run, ó wá sọ pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ni ohùn kan tó rinlẹ̀ bá dún láti ọ̀run pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”—Jòhánù 12:27, 28.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ò yé àwọn tó wà níbẹ̀. Àwọn kan rò pé ààrá ló sán. Àwọn míì sọ pé: “Áńgẹ́lì kan ti bá a sọ̀rọ̀.” (Jòhánù 12:29) Àmọ́ ohùn Jèhófà ni wọ́n gbọ́ yẹn! Kì í sì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí táwọn èèyàn máa gbọ́ tí Ọlọ́run bá Jésù sọ̀rọ̀.

Lọ́dún mẹ́ta ààbọ̀ sẹ́yìn, nígbà tí Jésù ń ṣèrìbọmi, Jòhánù Arinibọmi gbọ́ tí Ọlọ́run sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” Nígbà tó yá, lẹ́yìn Ìrékọjá ọdún 32 S.K., Ọlọ́run yí Jésù pa dà di ológo níṣojú Jémíìsì, Jòhánù àti Pétérù. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gbọ́ nígbà tí Ọlọ́run sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.” (Mátíù 3:17; 17:5) Èyí tó ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì yìí ni ìgbà kẹta tí Jèhófà sọ̀rọ̀, kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè gbọ́!

Jésù sọ pé: “Kì í ṣe torí tèmi ni ohùn yìí ṣe dún, torí tiyín ni.” (Jòhánù 12:30) Ohùn yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé Ọmọ Ọlọ́run ni lóòótọ́ àti pé òun ni Mèsáyà tí a ṣèlérí.

Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ nígbà tó wà láyé jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ káwa èèyàn tẹ̀ lé, ó sì tún jẹ́ kó dá wa lójú pé dandan ni kí Sátánì Èṣù, tó jẹ́ alákòóso ayé pa run. Jésù sọ pé: “Ní báyìí, à ń ṣèdájọ́ ayé yìí; ní báyìí, a máa lé alákòóso ayé yìí jáde.” Tí Jésù bá kú, ó lè fẹ́ dà bíi pé wọ́n ti rẹ́yìn rẹ̀, àmọ́ ìṣẹ́gun ló máa jẹ́. Lọ́nà wo? Ó sọ pé: “Síbẹ̀, tí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé, màá fa onírúurú èèyàn sọ́dọ̀ ara mi.” (Jòhánù 12:31, 32) Jésù máa kú lórí òpó igi, ìyẹn á jẹ́ kó lè fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ kí wọ́n lè rí ìyè.

Nígbà tí Jésù sọ pé a máa ‘gbé òun sókè,’ àwọn èèyàn sọ pé: “A gbọ́ látinú Òfin pé Kristi máa wà títí láé. Kí ló dé tí o wá sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè? Ta ni Ọmọ èèyàn yìí?” (Jòhánù 12:34) Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tí wọ́n rí, tí wọ́n sì tún gbọ́ ohùn Ọlọ́run, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni ò gbà pé Jésù gan-an ni Ọmọ èèyàn, Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.

Ṣáájú àkókò yìí, Jésù ti fi ara rẹ̀ wé “ìmọ́lẹ̀,” ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jòhánù 8:12; 9:5) Ó sọ pé: “Ìmọ́lẹ̀ máa wà láàárín yín fúngbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀ náà, kí òkùnkùn má bàa borí yín . . . Nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ náà, kí ẹ lè di ọmọ ìmọ́lẹ̀.” (Jòhánù 12:35, 36) Jésù wá kúrò níbẹ̀ torí pé kì í ṣe Nísàn 10 ló máa kú. Nísàn 14 tó jẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá ni wọ́n tó máa ‘gbé e sókè,’ tí wọ́n sì máa kàn án mọ́ òpó igi.—Gálátíà 3:13.

Ohun táwọn Júù ṣe nígbà tí Jésù ń wàásù jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ṣẹ sí wọn lára bí wọn ò ṣe gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ojú àwọn èèyàn yẹn máa lẹ̀ pọ̀, ọkàn wọn sì máa le kí wọ́n má bàa yí pa dà kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Àìsáyà 6:10; Jòhánù 12:40) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ò gbà pé Jésù ni olùgbàlà tí Ọlọ́run ṣèlérí, wọn ò gbà pé òun ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n lè gbà rí ìyè.

Òótọ́ ni pé Nikodémù, Jósẹ́fù ará Arimatíà àtàwọn alákòóso míì “ní ìgbàgbọ́ nínú” Jésù. Àmọ́ ṣé wọ́n máa fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́? Ṣé ìbẹ̀rù máa mú kí wọ́n yẹra fún Jésù, kí wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú sínágọ́gù? Àbí wọ́n á fi Jésù sílẹ̀ torí pé “wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo èèyàn”?—Jòhánù 12:42, 43.

Jésù ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti nígbàgbọ́ nínú òun, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kò ní ìgbàgbọ́ nínú èmi nìkan, àmọ́ ó tún ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán mi; ẹnikẹ́ni tó bá sì rí mi, ó rí Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.” Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Ọlọ́run rán Jésù pé kó fi kọ́ àwọn èèyàn ṣe pàtàkì gan-an, torí náà Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, tí kò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi ní ẹni tó máa dá a lẹ́jọ́. Ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ló máa dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn.”—Jòhánù 12:44, 45, 48.

Jésù wá sọ pé: “Èrò ara mi kọ́ ni mò ń sọ, àmọ́ Baba tó rán mi fúnra rẹ̀ ti fún mi ní àṣẹ kan nípa ohun tí màá wí àti ohun tí màá sọ. Mo sì mọ̀ pé àṣẹ rẹ̀ túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 12:49, 50) Jésù mọ̀ pé láìpẹ́ wọ́n máa ta ẹ̀jẹ̀ òun sílẹ̀, ìyẹn ni pé ó máa fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ káwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè rí ìgbàlà.—Róòmù 5:8, 9.