ORÍ 125
Wọ́n Mú Jésù Lọ Sọ́dọ̀ Ánásì àti Káyáfà
MÁTÍÙ 26:57-68 MÁÀKÙ 14:53-65 LÚÙKÙ 22:54, 63-65 JÒHÁNÙ 18:13, 14, 19-24
-
WỌ́N MÚ JÉSÙ LỌ SỌ́DỌ̀ ÁNÁSÌ TÓ TI FÌGBÀ KAN RÍ JẸ́ ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ
-
ÌGBÌMỌ̀ SÀHẸ́NDÌRÌN GBỌ́ ẸJỌ́ KAN LỌ́NÀ TÍ KÒ BÓFIN MU
Wọ́n de Jésù bí wọ́n ṣe ń de ọ̀daràn, wọ́n wá mú un lọ bá Ánásì. Ánásì yìí ni àlùfáà àgbà nígbà tí Jésù ṣì kéré, ìyẹn nígbà tí Jésù ṣe ohun kan tó ya àwọn olùkọ́ tó wà ní tẹ́ńpìlì lẹ́nu. (Lúùkù 2:42, 47) Nígbà tó yá, wọ́n fi àwọn kan lára àwọn ọmọ Ánásì joyè àlùfáà àgbà, àmọ́ ní báyìí, Káyáfà tó jẹ́ àna rẹ̀ ló wà nípò yẹn.
Ilé Ánásì ni Jésù wà nígbà tí Káyáfà pe ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn jọ. Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mọ́kànléláàádọ́rin (71) ni, àlùfáà àgbà tó wà lórí oyè lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn tó ti jẹ́ àlùfáà àgbà rí ló sì máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn.
Ánásì bi Jésù léèrè “nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.” Ohun tí Jésù sọ ò ju pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Gbogbo ìgbà ni mò ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọ sí; mi ò sì sọ ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀. Kí ló dé tí ò ń bi mí? Bi àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn.”—Jòhánù 18:19-21.
Ni ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ tó dúró síbẹ̀ bá fọ́ Jésù létí, ó sì bá a wí, ó ní: “Ṣé bí o ṣe máa dá olórí àlùfáà lóhùn nìyẹn?” Àmọ́ Jésù mọ̀ pé ohun tí òun sọ ò burú, torí náà, ó sọ pé: “Tó bá jẹ́ ohun tí kò tọ́ ni mo sọ, jẹ́rìí nípa ohun tí kò tọ́ náà; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó tọ́ ni mo sọ, kí ló dé tí o fi gbá mi?” (Jòhánù 18:22, 23) Ánásì wá ní kí wọ́n mú Jésù lọ bá Káyáfà tó jẹ́ àna òun.
Ní báyìí, ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti pé jọ. Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn ni àlùfáà àgbà tó wà lórí oyè lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn àgbààgbà àtàwọn akọ̀wé òfin. Ilé Káyáfà ni wọ́n pé jọ sí. Lóòótọ́ kò bófin mu láti ṣe irú ìgbẹ́jọ́ yìí lálẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá, síbẹ̀ àwọn èèyàn yẹn hu ìwà burúkú tó wà lọ́kàn wọn.
Ó dájú pé ọ̀nà èrú ni wọ́n máa gbà ṣèdájọ́ yìí, torí pé lẹ́yìn tí Jésù jí Lásárù dìde, ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti sọ pé Jésù gbọ́dọ̀ kú. (Jòhánù 11:47-53) Àti pé ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ń wá bí wọ́n ṣe máa mú Jésù, kí wọ́n sì pa á. (Mátíù 26:3, 4) Torí náà, kí wọ́n tiẹ̀ tó gbọ́ ẹjọ́ yẹn ló ti hàn pé ikú lọ̀rọ̀ náà máa já sí!
Yàtọ̀ sí pé ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí ò bófin mu, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn yòókù tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ń wá àwọn ẹlẹ́rìí tó máa fẹ̀sùn èké kan Jésù kí wọ́n lè rí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí wọ́n á fi dá a lẹ́bi. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn wá láti jẹ́rìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn ò bára mu. Nígbà tó yá, àwọn méjì bọ́ síwájú, wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ tó sọ pé, ‘Màá wó tẹ́ńpìlì yìí tí wọ́n fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ òmíràn tí wọn ò fi ọwọ́ kọ́.’ ” (Máàkù 14:58) Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí ò bára mu délẹ̀délẹ̀.
Káyáfà wá bi Jésù pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni? Ẹ̀rí tí àwọn èèyàn yìí ń jẹ́ lòdì sí ọ ńkọ́?” (Máàkù 14:60) Jésù ò sọ̀rọ̀ rárá, bí gbogbo àwọn ẹlẹ́rìí tó ń wá ṣe ń fẹ̀sùn èké kàn án, tí ọ̀rọ̀ wọn ò sì bára mu. Ni Káyáfà bá dọ́gbọ́n yí ọ̀rọ̀ yẹn.
Káyáfà mọ̀ pé àwọn Júù kì í fẹ́ gbọ́ ọ sétí kí ẹnì kan máa pe ara ẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run. Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé nígbà kan tí Jésù pe Ọlọ́run ní Baba òun, àwọn Júù fẹ́ pa á, torí wọ́n gbà pé ṣe ló “ń sọ pé òun àti Ọlọ́run dọ́gba.” (Jòhánù 5:17, 18; 10:31-39) Ohun tí Káyáfà mọ̀ yìí wá jẹ́ kó fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ fún Jésù pé: “Mo fi ọ́ sábẹ́ ìbúra níwájú Ọlọ́run alààyè pé kí o sọ fún wa bóyá ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run!” (Mátíù 26:63) Lóòótọ́, Jésù máa ń sọ ọ́ ní gbangba pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. (Jòhánù 3:18; 5:25; 11:4) Àmọ́ tó bá sọ ohun tó yàtọ̀ síyẹn níbí, wọ́n máa gbà pé ṣe ló ń sẹ́ pé òun kọ́ ni Ọmọ Ọlọ́run tàbí Kristi. Torí náà, Jésù sọ pé: “Èmi ni; ẹ sì máa rí Ọmọ èèyàn tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà ojú ọ̀run.”—Máàkù 14:62.
Ni Káyáfà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kígbe pé: “Ó ti sọ̀rọ̀ òdì! Kí la tún fẹ́ fi àwọn ẹlẹ́rìí ṣe? Ẹ wò ó! Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà. Kí lèrò yín?” Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn wá dá Jésù lẹ́bi láìtọ́, wọ́n ní: “Ikú ló tọ́ sí i.”—Mátíù 26:65, 66.
Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jésù ṣe ẹlẹ́yà nìyẹn, wọ́n sì ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn kan lára wọn gbá a létí, wọ́n sì tutọ́ sí i lójú. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n fi nǹkan bò ó lójú, wọ́n gbá a létí, wọ́n wá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ní: “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta lẹni tó gbá ọ?” (Lúùkù 22:64) Ẹ wo bí Ọmọ Ọlọ́run ṣe dẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ ẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́ láàárín òru!