ORÍ 36
Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé?
NÍNÚ orí méjì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà kọjá yìí, ẹni mélòó ni a kà níbẹ̀ pé wọ́n jí dìde?— Ẹni márùn-ún. Mélòó nínú wọn ló jẹ́ ọmọdé?— Mẹ́ta. Wọ́n sì pe ẹni ìkẹrin ní ọ̀dọ́kùnrin. Kí ni o rò pé èyí fi hàn?—
Ó dára, èyí fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn èwe. Ṣùgbọ́n yóò tún jí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn dìde pẹ̀lú. Ṣé kìkì àwọn tó ṣe ohun rere nìkan ni Ọlọ́run yóò jí dìde?— A lè rò bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n ṣe ohun tó burú nítorí pé ohun tó lòdì ni wọ́n fi kọ́ wọn. Ǹjẹ́ o rò pé Jèhófà yóò jí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ dìde?—
Bíbélì sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Èé ṣe tí àwọn tí kì í ṣe olódodo, tàbí àwọn tí kò ṣe ohun tó tọ́ yóò fi ní àjíǹde?— Ó jẹ́ nítorí pé wọn kò ní àǹfààní rí láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti nípa ohun tí ó fẹ́ kí àwọn èèyàn máa ṣe.
Jòhánù 11:23, 24) Kí ni Màtá ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé Lásárù yóò dìde ní “ọjọ́ ìkẹyìn”?—
Ìgbà wo ni o rò pé àwọn èèyàn yóò ní àjíǹde?— Rántí ìgbà tí Lásárù kú tí Jésù ṣèlérí fún Màtá arábìnrin rẹ̀ pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Màtá fèsì pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Ṣé o rí i, Màtá ti gbọ́ nípa ìlérí tí Jésù ṣe pé: ‘Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò jáde wá.’ (Jòhánù 5:28, 29) Nítorí náà, “ọjọ́ ìkẹyìn” ni ìgbà tí a óò mú gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run padà wá sí ìyè. Ọjọ́ ìkẹyìn yìí kì í ṣe ọjọ́ tó jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún o. Yóò gùn tó ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. Ọjọ́ yìí ni Bíbélì sọ pé, ‘Ọlọ́run yóò ṣèdájọ́ gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé.’ Àwọn tí ó jíǹde yóò wà lára àwọn tí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ wọn.—Ìṣe 17:31; 2 Pétérù 3:8.
Ṣáà ronú nípa bí ọjọ́ yìí yóò ṣe jẹ́ ọjọ́ alárinrin tó! Ní ọjọ́ tí ó gùn tó ẹgbẹ̀rún ọdún yìí, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn tí ó ti kú ni a óò mú kí ó wà láàyè padà. Jésù pe ibi tí a mú wọn padà sí láti máa gbé ní Párádísè. Jẹ́ kí á wo ibi tí Párádísè yóò wà àti bí ibẹ̀ yóò ṣe rí.
Ní nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta ṣáájú kí Jésù tó kú lórí igi oró, ó sọ̀rọ̀ nípa Párádísè fún ọkùnrin kan tí ó wà lórí òpó igi ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Torí pé ọkùnrin yẹn jẹ́ ọ̀daràn ni wọ́n ṣe fẹ́ pa á. Ṣùgbọ́n bí ọ̀daràn yìí ṣe ń wo Jésù, tí ó sì ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nípa Rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí gba Lúùkù 23:42, 43.
Jésù gbọ́. Nítorí náà ọ̀daràn yìí sọ pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù dáhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ èyí? Ibo ni Párádísè wà?— Ronú nípa rẹ̀. Ibo ni Párádísè wà ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀?— Rántí, Ọlọ́run fi ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, àti aya rẹ̀ sínú Párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé wa níhìn-ín kí wọ́n máa gbé ibẹ̀. Ọgbà Édẹ́nì ni wọ́n ń pè é. Àwọn ẹranko wà nínú ọgbà náà, ṣùgbọ́n wọn kò pa ẹnikẹ́ni lára. Àwọn igi tó ń so èso aládùn tó pọ̀ gan-an wà níbẹ̀, àti odò ńlá kan pẹ̀lú. Ibi tó dára gan-an láti máa gbé ni!—Jẹ́nẹ́sísì 2:8-10.
Nítorí náà, tí a bá ti ń kà á pé ọ̀daràn yìí yóò wà nínú Párádísè, àwòrán ilẹ̀ ayé kan tí a sọ di ibi ẹlẹ́wà kan láti máa gbé ni kí ó máa wà lọ́kàn wa. Ṣé Jésù yóò wà lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín nínú Párádísè pẹ̀lú ẹni tó jẹ́ ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ rí yìí ni?— Rárá o. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù ò fi ní wà lórí ilẹ̀ ayé níbí?—
Ìdí ni pé Jésù yóò wà ní ọ̀run tí yóò máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lé ilẹ̀ ayé tó jẹ́ Párádísè lórí. Nítorí náà, Jésù yóò wà pẹ̀lú ọkùnrin yìí ní ti pé Jésù yóò jí i dìde kúrò nínú ipò òkú, yóò sì máa tọ́jú rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ló fà á tí Jésù yóò fi jẹ́ kí ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ rí yìí gbé nínú Párádísè?— Jẹ́ kí á wò ó bóyá a óò lè rí ìdáhùn rẹ̀.
Kí ọ̀daràn yìí tó bá Jésù sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ ó mọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run?—
Rárá, kò mọ̀. Ohun tó mú kí ó máa ṣe nǹkan burúkú ni pé kò mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Nínú Párádísè a óò kọ́ ọ ní ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà náà, yóò ní àǹfààní láti fi hàn pé òun fẹ́ràn Ọlọ́run ní tòótọ́ bí ó bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.Ṣé inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni gbogbo ẹni tí ó bá ní àjíǹde yóò wà?— Rárá, gbogbo wọn kọ́ ni yóò wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí kò fi ní jẹ́ gbogbo wọn?— Ìdí ni pé a óò jí àwọn kan dìde láti lọ gbé pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. Wọn yóò máa bá a ṣàkóso pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé tó jẹ́ Párádísè lórí. Jẹ́ kí á wo bí a ṣe mọ èyí.
Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé kí ó tó kú, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: ‘Nínú ilé Baba mi ní ọ̀run, ọ̀pọ̀ ibùgbé wà níbẹ̀, mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.’ Lẹ́yìn náà Jésù ṣèlérí fún wọn pé: “Èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.”—Jòhánù 14:2, 3.
Jòhánù 17:4, 5) Nítorí náà Jésù ṣèlérí fún àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mìíràn pé òun yóò jí wọn dìde kí wọ́n lè wà pẹ̀lú òun ní ọ̀run. Kí ni wọ́n yóò máa bá Jésù ṣe níbẹ̀?— Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí ó ní ipa nínú “àjíǹde èkíní” yóò gbé ní ọ̀run, wọn yóò sì máa ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí “gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún.”—Ìṣípayá 5:10; 20:6; 2 Tímótì 2:12.
Ibo ni Jésù lọ lẹ́yìn tí ó jíǹde?— Ó padà sí ọ̀run lọ bá Bàbá rẹ̀ ni o. (Àwọn mélòó ni yóò ní ipa nínú “àjíǹde èkíní” tí wọ́n yóò sì máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù gẹ́gẹ́ bí ọba?— Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) “Agbo kékeré” yìí, tí a jí dìde láti lọ wà pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run, jẹ́ iye àwọn èèyàn kan pàtó. Bíbélì fi hàn pé “ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì” ni àwọn tí a jí dìde láti ayé lọ sí ọ̀run.—Ìṣípayá 14:1, 3.
Àwọn mélòó ni yóò gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?— Bíbélì kò sọ iye wọn. Ṣùgbọ́n ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n ṣì wà nínú ọgbà Édẹ́nì ni pé kí wọ́n bí àwọn ọmọ, kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kùnà tí wọn kò sì lè ṣe é, síbẹ̀ Ọlọ́run yóò rí sí i pé ìfẹ́ òun pé kí àwọn èèyàn rere kún ilẹ̀ ayé ṣẹ lóòótọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Aísáyà 45:18; 55:11.
Áà, o ò rí i pé yóò jẹ́ ohun alárinrin láti máa gbé nínú Párádísè! Gbogbo ayé yóò dà bí ọgbà ẹlẹ́wà kan. Yóò jẹ́ ibi tí ó kún fún àwọn ẹyẹ àti ẹranko àti oríṣiríṣi igi àti òdòdó ẹlẹ́wà. Kò ní sí pé àìsàn ń kó ìrora bá ẹnikẹ́ni, kò sì ní sí ẹni tí yóò kú mọ́. Gbogbo èèyàn yóò jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Bí a bá fẹ́ gbé nínú Párádísè, ìsinsìnyí gan-an ni ó yẹ kí á múra sílẹ̀ fún un.
Kà sí i nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé, nínú Òwe 2:21, 22; Oníwàásù 1:4; Aísáyà 2:4; 11:6-9; 35:5, 6; àti Ais 65:21-24.