ORÍ 32
Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù
NÍGBÀ mìíràn, Jèhófà máa ń ṣe àwọn nǹkan lọ́nà ìyanu láti dáàbò bo àwọn tó jẹ́ ọmọ kékeré tí kò mọ nǹkan kan. Tí o bá jáde lọ sínú igbó o lè rí ọ̀nà kan tí Jèhófà máa ń gbà ṣe èyí. Ṣùgbọ́n ohun tó o rí lè máà kọ́kọ́ yé ọ.
O kàn lè rí i pé ẹyẹ kan bà sílẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Kí ó dà bíi pé ó ti ṣèṣe. Bí o ṣe ní kó o sún mọ́ ọn, bẹ́ẹ̀ ló rọra gbé apá kan bíi pé ó ń dùn ún, ó sì sáré síwájú díẹ̀. Bí o ṣe ń tẹ̀ lé e, ó ń sá síwájú títí ọwọ́ rẹ kò fi bà á. Lójijì ẹyẹ yìí wá fò lọ. Àṣé nǹkan kan kò ṣe é lápá! Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ẹyẹ náà ń ṣe?—
Ṣé o rí i, àwọn ọmọ ẹyẹ náà ti fara pa mọ́ sínú koríko kan ní ibi tí ẹyẹ yìí bà sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Ẹ̀rù ń ba ẹyẹ yìí pé o lè rí àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì pa wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi fi ọgbọ́n ṣe bíi pé òun ti ṣèṣe kí ó lè tàn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó lè dáàbò bò wá gẹ́gẹ́ bí ìyá ẹyẹ ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀?— Nínú Bíbélì, a fi Jèhófà wé ẹyẹ kan tó ń jẹ́ idì, tó máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ rẹ̀ kékeré.—Diutarónómì 32:11, 12.
Nínú àwọn ọmọ Jèhófà, Jésù ni Ọmọ tó ṣe iyebíye jù lọ. Nígbà tí Jésù wà ní ọ̀run, ó jẹ́ ẹni ẹ̀mí alágbára gẹ́gẹ́ bí Bàbá rẹ̀. Ó lè bójú tó ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré jòjòló sí ilẹ̀ ayé, kò lè dá ohunkóhun ṣe fúnra rẹ̀. Ó nílò ààbò.
Kí Jésù tó lè ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí ó ṣe ní ayé, ó ní láti kúrò ní ọmọdé kí ó di àgbà, ẹni pípé. Ṣùgbọ́n Sátánì gbìyànjú láti pa Jésù kí ó tó di àgbàlagbà. Ìtàn bí ó ṣe gbìyànjú láti pa Jésù nígbà tí ó ṣì wà ní ọmọdé àti bí Jèhófà ṣe dáàbò bò ó jẹ́ ìtàn kan tó dùn gan-an. Ṣé wàá fẹ́ láti gbọ́ ọ?—
Kò pẹ́ púpọ̀ sí ìgbà tí wọ́n bí Jésù, Sátánì mú kí ohun tó dà bí ìràwọ̀ tàn ní ojú ọ̀run ní apá Ìlà Oòrùn. Àwọn èèyàn kan tí à ń pè ní awòràwọ̀ tẹ̀ lé ìràwọ̀ yìí láti ibi tó jìnnà gan-an wá sí ìlú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n béèrè ibi tí wọ́n ti máa bí ẹnì kan tí yóò di ọba àwọn Júù. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tó mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀, wọ́n dáhùn pé: ‘Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.’—Mátíù 2:1-6.
Nígbà tí Hẹ́rọ́dù ọba burúkú tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa ọba tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìtòsí rẹ̀ yìí, ó sọ fún àwọn awòràwọ̀ náà pé: ‘Ẹ fara balẹ̀ wá ibi tí ọmọ náà wà dáadáa kí ẹ padà wá sọ fún mi.’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Hẹ́rọ́dù fi fẹ́ mọ ibi tí Jésù wà?— Nítorí pé òjòwú ni Hẹ́rọ́dù, ṣe ló fẹ́ pa ọmọ náà!
Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáàbò bo Ọmọ rẹ̀?— Ó dára, nígbà tí àwọn awòràwọ̀ rí Jésù, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn awòràwọ̀ náà ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù. Nítorí náà, wọ́n gba ọ̀nà ibòmíràn lọ sí ìlú wọn, wọn kò padà sí Jerúsálẹ́mù mọ́. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ pé àwọn awòràwọ̀ náà ti lọ, ó bínú gan-an. Nítorí kí Hẹ́rọ́dù lè pa Jésù, ó sọ pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọdé ọkùnrin tí kò tíì dàgbà tó ọmọ ọdún méjì tó bá wà nínú ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù! Ṣùgbọ́n ní àkókò yẹn Jésù kò sí níbẹ̀ mọ́.
Ǹjẹ́ o mọ bí Jésù ṣe kúrò níbẹ̀?— Lẹ́yìn tí àwọn awòràwọ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láti máa lọ sí ìlú wọn, Jèhófà kìlọ̀ fún Jósẹ́fù ọkọ́ Màríà pé kí ó dìde, kí ó sá lọ sí Íjíbítì tó jìnnà gan-an. Ní Íjíbítì tí Jésù wà yìí, Hẹ́rọ́dù ọba burúkú náà kò lè rí i pa. Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí Màríà àti Jósẹ́fù gbé Jésù padà wá láti Íjíbítì, Ọlọ́run tún ṣe ìkìlọ̀ mìíràn fún Jósẹ́fù. Ó sọ fún un ní ojú àlá pé kí ó lọ máa gbé ní Násárétì, níbi tí Jésù yóò wà láìsí ewu.—Mátíù 2:7-23.
Ǹjẹ́ o rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Ọmọ rẹ̀?— Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó dà bí àwọn ọmọ ẹyẹ tí ìyá wọn kó pa mọ́ sínú koríko tàbí ẹni tó dà bíi Jésù nígbà tó wà ní ọmọ kékeré?
Ǹjẹ́ ìwọ kò dà bíi wọn?— Àwọn kan wà tí wọ́n fẹ́ pa ìwọ pẹ̀lú lára. Ṣé o mọ àwọn ẹni náà?—Bíbélì sọ pé Sátánì dà bíi kìnnìún tó ń bú ramúramù tí ó fẹ́ láti pa wá jẹ. Bí kìnnìún ṣe sábà máa ń dójú sọ àwọn ẹran kéékèèké láti pa wọ́n jẹ, bẹ́ẹ̀ ni Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣe máa ń dójú sọ àwọn ọmọ kéékèèké. (1 Pétérù 5:8) Ṣùgbọ́n Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ. Jèhófà lè dáàbò bo àwọn ọmọ kéékèèké tó jẹ́ tirẹ̀ tàbí kí ó ṣe àtúnṣe gbogbo ibi tí Sátánì bá mú bá wọn.
Ǹjẹ́ o rántí ohun tí a kà ní Orí 10 nínú ìwé yìí pé Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbìyànjú láti mú kí á ṣe?— Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n máa ń gbìyànjú láti mú wa ṣe ìṣekúṣe tí Ọlọ́run sọ pé kò dára. Ṣùgbọ́n kìkì àwọn wo ni ó yẹ kí ó máa bá ara wọn lò pọ̀?— Bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí àwọn méjèèjì ti dàgbà, tí wọ́n sì jẹ́ ọkọ àti aya nìkan ni.
Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà kan máa ń fẹ́ bá àwọn ọmọdé lò pọ̀. Tí wọ́n bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọdé ọkùnrin àti obìnrin lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìṣekúṣe tí wọ́n ti kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí. Àwọn pẹ̀lú yóò bẹ̀rẹ̀ sí lo ẹ̀yà ìbímọ wọn lọ́nà tó lòdì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan láyé àtijọ́ nìyẹn, ní ìlú Sódómù. Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn ibẹ̀, “láti orí ọmọdékùnrin dórí àgbà ọkùnrin” gbìyànjú láti bá àwọn ọkùnrin kan tó jẹ́ àlejò Lọ́ọ̀tì lò pọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 19:4, 5.
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe nílò ààbò, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe yẹ kí á dáàbò bo ìwọ pẹ̀lú kúrò lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà—àti àwọn ọmọdé mìíràn pàápàá—tí ó lè gbìyànjú láti bá ọ ṣe ìṣekúṣe. Àwọn wọ̀nyí sábà máa ń kọ́kọ́ ṣe bí ẹni pé àwọn jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ. Wọ́n tiẹ̀ lè sọ pé àwọn yóò fún ọ ní ohun kan tí o bá ti lè sọ pé o kò ní sọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe pẹ̀lú rẹ fún ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, gẹ́gẹ́ bíi Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù. Ara wọn ni wọ́n kàn fẹ́ tẹ́ lọ́rùn. Ọ̀nà tí wọ́n sì fẹ́ gbà tẹ́ ara wọn lọ́rùn ni pé kí wọ́n máa bá àwọn ọmọdé ṣe ìṣekúṣe. Èyí sì lòdì gan-an!
Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn?— Wọ́n lè fẹ́ máa fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ. Tàbí wọ́n tiẹ̀ lè máa fi ẹ̀yà ìbímọ tiwọn pa tìrẹ. Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ẹ̀yà ìbímọ rẹ, ìyẹn okó rẹ tàbí òbò rẹ, ṣeré rárá. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, tàbí màmá tàbí bàbá rẹ pàápàá fi ṣeré o. Ibi tí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ máa fọwọ́ kan ṣeré rárá ni.
Báwo ni o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ kúrò lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń ṣe irú àwọn ohun burúkú bẹ́ẹ̀?— Ohun àkọ́kọ́ ni pé, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ẹ̀yà ìbímọ rẹ ṣeré rárá. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi ṣeré, kí o kọ̀, kí o sì kígbe sókè gan-an, pé: “Rárá o! Màá fẹjọ́ yín sùn!” Tí ẹni náà bá sọ pé ìwọ ló fà á tí òun fi ṣe bẹ́ẹ̀, má ṣe gbà á gbọ́. Irọ́ ni. Ìwọ ṣáà lọ sọ ohun tí ẹni náà ṣe, ẹni yòówù kí ó jẹ́! Tí onítọ̀hún bá tiẹ̀ sọ pé ohun àṣírí ni, pé o kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni, má dá a lóhùn, lọ sọ ohun tí ó ṣe. Kódà bí ẹni náà bá tiẹ̀ ṣèlérí pé òun yóò fún ọ ní àwọn ẹ̀bùn dáradára kan, tàbí pé ó ń dẹ́rù bà ọ́, kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ kí o lọ sọ ohun tí ó ṣe.
Kì í ṣe pé kí o máa sá fún àwọn èèyàn o, ṣùgbọ́n o ní láti máa ṣọ́ra. Tí àwọn òbí rẹ bá kìlọ̀ fún ọ nípa àwọn èèyàn kan tàbí àwọn ibì kan tó lè jẹ́ ewu fún ọ, gbọ́ ohun tí wọ́n sọ fún ọ. Bí o bá fetí sí wọn, ìyẹn kò ní jẹ́ kí ẹni burúkú kankan lè rí àyè pa ọ́ lára.
Kà síwájú sí i nípa bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ kúrò lọ́wọ́ ìwà ìṣekúṣe, nínú Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12; Òwe 4:14-16; 14:15, 16; 1 Kọ́ríńtì 6:18; àti 2 Pétérù 2:14.