Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 5

“Èyí Ni Ọmọ Mi”

“Èyí Ni Ọmọ Mi”

BÍ ÀWỌN ọmọdé bá ń ṣe dáadáa, inú àwọn tó ń tọ́jú wọn máa ń dùn. Bí ọmọbìnrin kan tàbí ọmọkùnrin kan bá sì ṣe ohun tó wu bàbá rẹ̀, inú bàbá rẹ̀ á dùn, á sì sọ fún àwọn èèyàn pé: “Ọmọ mi nìyí.”

Nígbà gbogbo ni Jésù máa ń ṣe ohun tó wu Bàbá rẹ̀. Nítorí náà, inú Bàbá rẹ̀ máa ń dùn sí i. Ǹjẹ́ o rántí ohun tí Bàbá Jésù ṣe lọ́jọ́ kan tí Jésù wà pẹ̀lú mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?— Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tààràtà láti ọ̀run sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”—Mátíù 17:5.

Ó máa ń dùn mọ́ Jésù nígbà gbogbo láti ṣe àwọn nǹkan tó ń mú inú Bàbá rẹ̀ dùn. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á? Ohun tó fà á ni pé Jésù fẹ́ràn Bàbá rẹ̀ gidigidi. Tí wọ́n bá ní kí èèyàn ṣe ohun kan tipátipá, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń dà bí ohun tó nira láti ṣe. Àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó wuni láti ṣe ni, kì í nira rárá. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kí nǹkan wuni láti ṣe? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fẹ́ láti ṣe nǹkan kan látọkàn rẹ̀ wá.

Kí Jésù tiẹ̀ tó wá sórí ilẹ̀ ayé rárá ló ti máa ń wù ú láti ṣe ohunkóhun tí Bàbá rẹ̀ bá ní kó ṣe. Ìdí ni pé ó fẹ́ràn Bàbá rẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run gan-an. Ipò pàtàkì ni Jésù wà lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run. Àmọ́ Ọlọ́run ní iṣẹ́ àkànṣe kan tó fẹ́ kí Jésù ṣe. Kí Jésù lè ṣe iṣẹ́ náà, ó gbọ́dọ̀ kúrò ní ọ̀run. A ní láti bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ jòjòló ní orí ilẹ̀ ayé. Iṣẹ́ yìí wu Jésù láti ṣe nítorí pé Jèhófà fẹ́ kó ṣe é.

Kí ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà?

Ká tó lè bí Jésù sórí ilẹ̀ ayé, obìnrin kan gbọ́dọ̀ wà tó máa jẹ́ ìyá rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ obìnrin tó di ìyá Jésù?— Màríà ni orúkọ rẹ̀. Jèhófà rán áńgẹ́lì rẹ̀ tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì láti ọ̀run pé kó lọ bá Màríà sọ̀rọ̀. Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé ó máa bí ọmọkùnrin kan. Ó ní Jésù ni wọn yóò pe orúkọ ọmọ náà. Ta ni yóò sì jẹ́ bàbá ọmọ náà?— Áńgẹ́lì náà sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni yóò jẹ́ Bàbá rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a ó fi pe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run.

Kí ni Màríà sọ nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà?— Ṣé ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ jẹ́ ìyá Jésù ní tèmi o”? Rárá, kò sọ bẹ́ẹ̀. Ohun tó wu Ọlọ́run ni Màríà fẹ́ láti ṣe. Ṣùgbọ́n báwo ni Màríà ṣe lè bí Ọmọ Ọlọ́run tó wà ní ọ̀run tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan sórí ilẹ̀ ayé? Báwo ni ọ̀nà tí wọ́n gbà bí Jésù ṣe yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń bí àwọn ọmọ yòókù? Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?—

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, lọ́nà tí wọ́n á fi lè sún mọ́ra wọn lọ́nà ìyanu kan. Lẹ́yìn ìyẹn, ọmọ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nínú ìyá rẹ̀. Àwọn èèyàn máa ń sọ pé iṣẹ́ ìyanu ni! Ó dá mi lójú pé ìwọ náà á gbà pé iṣẹ́ ìyanu ni.

Ọlọ́run tún wá ṣe iṣẹ́ ìyanu mìíràn tó yani lẹ́nu jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó mú ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ tó wà lọ́run ó sì fi sínú Màríà. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìyẹn, kò sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà. Iṣẹ́ ìyanu yìí ló mú kí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nínú Màríà bí àwọn ọmọ mìíràn ṣe máa ń dàgbà nínú ikùn ìyá wọn. Lẹ́yìn náà ni Màríà di ìyàwó Jósẹ́fù.

Nígbà kan tí Màríà àti Jósẹ́fù lọ sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àkókò tó láti bí Jésù. Àmọ́ àwọn èèyàn tó wá sí ìlú náà pọ̀ gan-an. Kódà, Màríà àti Jósẹ́fù kò tiẹ̀ rí yàrá kankan tí wọ́n lè wọ̀ sí níbẹ̀. Ibi tí wọ́n ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn sí ni wọ́n rí wọ̀ sí. Ibẹ̀ sì ni Màríà bí Jésù sí. Wọ́n wá tẹ́ Jésù sí ibùjẹ ẹran, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí. Ibi tí wọ́n máa ń bu oúnjẹ sí fún màlúù àtàwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn láti jẹ ni wọ́n ń pè ní ibùjẹ ẹran.

Kí ló fà á tí wọ́n fi tẹ́ Jésù sí ibùjẹ ẹran?

Àwọn ohun àrà ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tí Màríà bí Jésù. Áńgẹ́lì kan yọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé èèyàn pàtàkì ni Jésù. Áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Wò ó! Èmi ń kéde ìhìn rere tí yóò mú inú àwọn èèyàn dùn fún yín. A bí ẹnì kan lónìí tí yóò gba àwọn èèyàn là.’—Lúùkù 2:10, 11.

Ìhìn rere wo ni ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì yìí sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà?

Áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí pé wọn yóò rí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, níbi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí ní ibùjẹ ẹran. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn áńgẹ́lì mìíràn tún yọ lójijì láti ọ̀run, wọ́n sì wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ áńgẹ́lì tó ń sọ̀rọ̀ náà, gbogbo wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo. Àwọn áńgẹ́lì náà wá ń kọrin pé: ‘Ògo ni fún Ọlọ́run, àlàáfíà fún àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lórí ilẹ̀ ayé.’—Lúùkù 2:12-14.

Nígbà tí àwọn áńgẹ́lì náà lọ tán, àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà padà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì rí Jésù. Wọ́n wá sọ gbogbo nǹkan rere tí wọ́n gbọ́ fún Jósẹ́fù àti Màríà. Ǹjẹ́ o ò rí i pé inú Màríà yóò dùn gan-an pé òun gbà láti jẹ́ ìyá Jésù?

Nígbà tó yá, Jósẹ́fù àti Màríà wá gbé Jésù lọ sí ìlú Násárétì. Ibẹ̀ ni Jésù wà títí tó fi dàgbà. Nígbà tí Jésù dàgbà tán, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Èyí wà lára iṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ń fẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Jésù fẹ́ láti ṣe iṣẹ́ náà nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run gidigidi.

Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Olùkọ́ Ńlá tó ṣe yìí, Jòhánù Oníbatisí kọ́kọ́ rì í bọmi nínú Odò Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, ohun ńlá kan ṣẹlẹ̀! Bí Jésù ṣe ń jáde bọ̀ látinú omi báyìí, Jèhófà kàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run ni. Ó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Inú rẹ máa ń dùn tí àwọn òbí rẹ bá sọ fún ẹ pé àwọn fẹ́ràn rẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ó dájú pé inú Jésù náà dùn pẹ̀lú.

Ohun tó tọ́ ni Jésù máa ń ṣe nígbà gbogbo. Kì í purọ́ pé òun jẹ́ nǹkan tí òun kò jẹ́. Kò sọ fún àwọn èèyàn rárá pé òun ni Ọlọ́run. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ti sọ fún Màríà tẹ́lẹ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pe Jésù. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. Kò sì sọ fún àwọn èèyàn pé ìmọ̀ òun ju ti Bàbá òun lọ. Ó sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.”—Jòhánù 14:28.

Kódà ní ọ̀run, nígbà tí Bàbá Jésù fún un ní iṣẹ́ láti ṣe, Jésù ṣe iṣẹ́ náà. Kò sọ fún Bàbá rẹ̀ pé òun á ṣe iṣẹ́ náà kó wá lọ máa ṣe nǹkan mìíràn. Ó fẹ́ràn Bàbá rẹ̀. Nítorí náà ó máa ń fetí sí ohun tí Bàbá rẹ̀ bá sọ. Nígbà tí Jésù sì wá sí ayé, ohun tí Bàbá rẹ̀ ní kó wá ṣe ló ṣe. Kò fi àkókò rẹ̀ ṣe àwọn ohun tó yàtọ̀ sí èyí tí Bàbá rẹ̀ ní kó ṣe. Abájọ tí inú Jèhófà fi dùn sí Ọmọ rẹ̀!

Àwa náà fẹ́ mú inú Jèhófà dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Nígbà náà, a gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwa náà ń fetí sí Ọlọ́run dáadáa gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù. Bíbélì ni Ọlọ́run fi ń bá wa sọ̀rọ̀. Kó dára kéèyàn sọ pé òun ń fetí sí Ọlọ́run ṣùgbọ́n kó tún máa ṣe ohun tí Bíbélì sọ pé kò dára láti ṣe, àbí ó dáa bẹ́ẹ̀?— Sì rántí pé tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ràn Jèhófà, a óò fẹ́ láti máa ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn.

Wàyí o, ka àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí tó tún sọ ohun tó yẹ ká mọ̀ àti èyí tó yẹ ká gbà gbọ́ nípa Jésù: Mátíù 7:21-23; Jòhánù 4:25, 26; àti 1 Tímótì 2:5, 6.