ORÍ 38
Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Á Fẹ́ràn Jésù
FOJÚ inú wò ó pé o wà nínú ọkọ̀ ojú omi kan tó ń rì. Ǹjẹ́ ìwọ yóò fẹ́ kí ẹnì kan wá gbà ọ́ sílẹ̀ kí o má bàa kú sómi?— Bí ẹnì kan bá yọ̀ǹda láti kú torí kí ó lè gbà ọ́ là, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ?— Ohun tí Jésù Kristi ṣe gan-an nìyẹn o. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí 37, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà kí a lè rí ìgbàlà.
Àmọ́ kì í ṣe pé Jésù wá gbà wá kí a má ṣe kú sínú omi o. Ǹjẹ́ o rántí ọwọ́ ohun tí Jésù ti gbà wá?— Ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ti ṣe ohun tó burú jáì, Jésù kú fún àwọn náà. Ǹjẹ́ ìwọ lè fi ẹ̀mí rẹ wewu láti lè gba irú èèyàn bẹ́ẹ̀ là?—
Bíbélì sọ pé: “Èkukáká ni ẹnikẹ́ni yóò fi kú fún olódodo; ní tòótọ́, bóyá ni ẹnì kan á gbójúgbóyà láti kú fún ènìyàn rere.” Àmọ́ Bíbélì ṣàlàyé pé Jésù “kú fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Àní títí kan àwọn tí kò sin Ọlọ́run pàápàá! Bíbélì sọ síwájú sí i pé: “Nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ [tí a ṣì ń hùwà tí kò dára], Kristi kú fún wa.”—Róòmù 5:6-8.
Ǹjẹ́ o mọ àpọ́sítélì kan tó ń hùwà tó burú gan-an nígbà kan rí?— Àpọ́sítélì náà kọ̀wé pé: “Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Nínú àwọn wọ̀nyí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló sọ bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé òun ‘jẹ́ òpònú nígbà kan rí’ àti pé òun “ń bá a lọ nínú ìwà búburú.”—1 Tímótì 1:15; Títù 3:3.
Ìwọ ronú nípa irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní kí ó tó lè rán Ọmọ rẹ̀ láti wá kú fún irú ẹni tó ti ṣe ohun tó burú bẹ́ẹ̀! O ò ṣe ṣí Bíbélì rẹ kí o sì kà nípa èyí nínú Jòhánù orí kẹta ẹsẹ ìkẹrìndínlógún. Ibẹ̀ kà báyìí pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [ìyẹn àwọn èèyàn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
Jésù fi hàn pé gẹ́gẹ́ bí Bàbá òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa ni òun náà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. O lè rántí pé ní Orí 30 nínú ìwé yìí, a kà nípa irú ìyà tó jẹ Jésù ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un. Wọ́n mú un lọ sílé Káyáfà Olórí Àlùfáà, níbi tí wọ́n ti ṣe ẹjọ́ Rẹ̀. Wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá kí wọ́n wá purọ́ mọ́ Jésù, àwọn èèyàn sì gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Ìgbà yẹn ni Pétérù sẹ́ Jésù tí ó sọ pé òun kò mọ Jésù. Wàyí o, jẹ́ kí á ṣe bíi pé a wà níbẹ̀ nígbà yẹn, tí a sì ń rí àwọn ohun mìíràn tó ń ṣẹlẹ̀.
Ilẹ̀ ti mọ́ báyìí. Jésù kò sùn tí ilẹ̀ fi mọ́. Ìgbẹ́jọ́ tí àwọn àlùfáà ṣe ní òru kò tọ̀nà, nítorí náà, àwọn àlùfáà sáré pe àjọ Sànhẹ́dírìn, tàbí ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù jọ ní òwúrọ̀, wọ́n sì ṣe ìgbẹ́jọ́ mìíràn. Wọ́n tún fi ẹ̀sùn kan Jésù níbẹ̀ pé ó dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run.
Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà de Jésù, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Pílátù, ìyẹn ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà wọn. Wọ́n sọ fún Pílátù pé: ‘Jésù ṣe ohun tó lòdì sí ìjọba. Pípa ni kí á pa á.’ Ṣùgbọ́n Pílátù rí i pé irọ́ ni àwọn àlùfáà náà ń pa. Nítorí náà Pílátù sọ fún wọn pé: ‘Èmi ò rí ìwà burúkú kankan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí o. Èmi yóò dá a sílẹ̀ kí ó máa lọ.’ Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn yòókù ń pariwo pé: ‘Rárá o! Pípa ni kí o pa á!’
Lẹ́yìn náà, Pílátù tún sọ fún àwọn èèyàn náà pé òun fẹ́ dá Jésù sílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà mú kí àwọn èrò tó wà níbẹ̀ máa pariwo pé: ‘Bí o bá tú u sílẹ̀, ìwọ náà lòdì sí ìjọba o! Pípa ni kí o pa á!’ Gbogbo èrò náà wá ń pariwo gèè. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Pílátù ṣe?—
Ó juwọ́ sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó mú kí wọ́n na Jésù lọ́rẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fi
lé àwọn ọmọ ogun lọ́wọ́ kí wọ́n lọ pa á. Wọ́n fi adé ẹ̀gún dé e lórí, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún un láti fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n wá gbé òpó ńlá kan lé Jésù kí ó rù ú, wọ́n sì mú un jáde kúrò ní ìlú lọ sí ibì kan tí wọ́n pè ní Ibi Agbárí. Wọ́n kan ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Jésù mọ́ òpó náà níbẹ̀. Wọ́n wá gbé òpó yẹn nàró kí Jésù lè so rọ̀ lórí rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ wá ń dà jáde lára rẹ̀. Ìrora yẹn sì pọ̀ gan-an.Jésù ò kú lójú ẹsẹ̀. Ó so rọ̀ sórí òpó níbẹ̀. Àwọn olórí àlùfáà wá ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn èrò tó ń kọjá lọ sì ń sọ pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró!” Ṣùgbọ́n Jésù mọ ohun tí Bàbá rẹ̀ rán an wá sí ayé wá ṣe. Ó mọ̀ pé òun ní láti fi ẹ̀mí òun pípé lélẹ̀ kí ó lè ṣeé Mátíù 26:36–27:50; Máàkù 15:1; Lúùkù 22:39–23:46; Jòhánù 18:1–19:30.
ṣe fún wa láti rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Níkẹyìn, ní nǹkan bí aago mẹ́ta ní ọ̀sán ọjọ́ yẹn, Jésù ké lóhùn rara sí Bàbá rẹ̀, ó sì kú.—Áà, Jésù mà yàtọ̀ sí Ádámù o! Ádámù ò fẹ́ràn Ọlọ́run. Ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ádámù ò sì tún fẹ́ràn àwa náà. Nítorí pé Ádámù dẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa ṣe dẹni tí à ń bí sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwa pẹ̀lú. Ó máa ń ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. Ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti lè mú ìpalára tí Ádámù ṣe fún wa kúrò.
Ǹjẹ́ o mọrírì ohun ńláǹlà tí Jésù ṣe yìí?— Nígbà tí o bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ǹjẹ́ o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún fífi tí ó fi Ọmọ rẹ̀ fún wa?— Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọrírì ohun tí Kristi ṣe fún un. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Ọmọ Ọlọ́run ‘nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’ (Gálátíà 2:20) Jésù kú fún ìwọ àti èmi pẹ̀lú. Àní ó fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun! Dájúdájú ìdí tó lágbára nìyẹn tó fi yẹ kí á fẹ́ràn Jésù.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní ń sún wa ṣiṣẹ́.” Irú iṣẹ́ wo ni ó yẹ kí ìfẹ́ tí Kristi ní sún wa láti ṣe? Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?— Kíyè sí ìdáhùn Pọ́ọ̀lù: “Kristi kú fún gbogbo èèyàn kí wọ́n lè máa wà láàyè fún Un. Kí wọ́n má ṣe wà láàyè fún ṣíṣe ìfẹ́ inú ara wọn.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15, New Life Version.
Ǹjẹ́ o lè ronú oríṣiríṣi ọ̀nà tí o lè gbà fi hàn pé ò ń lo ìwàláàyè rẹ fún ṣíṣe ohun tí Kristi ń fẹ́?— Ó dára, ọ̀nà kan ni pé kí o máa sọ àwọn ohun tí ò ń kọ́ nípa Kristi fún àwọn èèyàn. Sì tún ronú nípa èyí: Ìwọ nìkan lè wà níbì kan, kí màmá tàbí bàbá rẹ má lè rí ohun tí ò ń ṣe, tí ẹnikẹ́ni mìíràn ò sì lè rí ọ. Ǹjẹ́ ìwọ yóò wo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tàbí kí o ṣe ohun mìíràn tí o mọ̀ pé inú Jésù kò ní dùn sí?— Rántí pé, Jésù wà láàyè ó sì ń rí gbogbo ohun tí a bá ṣe!
Ìdí mìíràn tí ó fi yẹ kí á fẹ́ràn Jésù ni pé a fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà. Jésù sọ pé: ‘Baba nífẹ̀ẹ́ mi.’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí ó fi nífẹ̀ẹ́ Jésù àti ìdí tí o fi yẹ kí àwa náà nífẹ̀ẹ́ Jésù?— Ìdí náà ni pé Jésù yọ̀ǹda láti kú kí ìfẹ́ Ọlọ́run lè di ṣíṣe. (Jòhánù 10:17) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa ṣe ohun tí Bíbélì sọ fún wa, pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín.”—Éfésù 5:1, 2.
Láti lè dẹni tó mọyì Jésù àti ohun tí ó ṣe fún wa, jọ̀wọ́ ka Jòhánù 3:35; 15:9, 10; àti 1 Jòhánù 5:11, 12.