ORÍ 9
A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìdẹwò
ǸJẸ́ ẹnikẹ́ni sọ fún ọ rí pé kó o ṣe ohun kan tó burú?— Ǹjẹ́ ó sọ fún ọ pé kó o ṣe é tó o bá tó bẹ́ẹ̀? Àbí ó kàn sọ pé nǹkan náà yóò gbádùn mọ́ ẹ bí o bá ṣe é àti pé ohun náà kò burú rárá?— Bí ẹnì kan bá sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún wa, ṣe ló ń dán wa wò.
Kí ló yẹ kí a ṣe tí ẹnì kan bá dán wa wò? Ǹjẹ́ ó yẹ ká tẹ̀ lé ohun tí ẹni náà sọ ká wá ṣe ohun tó burú?— Inú Jèhófà Ọlọ́run kò ní dùn tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ǹjẹ́ o mọ inú ẹni tó máa dùn?— Inú Sátánì Èṣù ni.
Sátánì jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run, ọ̀tá àwa náà sì ni. A ò lè fojú rí i nítorí ẹni ẹ̀mí ni. Ṣùgbọ́n òun máa ń rí wa. Lọ́jọ́ kan, Èṣù bá Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà sọ̀rọ̀, ó gbìyànjú láti dán an wò. Jẹ́ ká wo ohun tí Jésù ṣe. Ìyẹn yóò jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ láti ṣe nígbà tí ẹnì kan bá dán wa wò.
Ìfẹ́ Ọlọ́run ni Jésù máa ń fẹ́ ṣe nígbà gbogbo. Ó fi èyí hàn gbangba gbàǹgbà bí ó ṣe wá láti ṣe ìrìbọmi nínú Odò Jọ́dánì. Gbàrà tí Jésù ṣèrìbọmi tán ni Sátánì dán an wò. Bíbélì sọ pé “ọ̀run ṣí sílẹ̀” fún Jésù. (Mátíù 3:16) Èyí lè túmọ̀ sí pé ìgbà yẹn ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí rántí bí òun ṣe ń gbé ní ọ̀run pẹ̀lú Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí.
Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi tán ó lọ sínú aginjù láti lọ ronú nípa àwọn ohun tó ń rántí yìí. Ibẹ̀ ló wà tí ogójì ọ̀sán àti ogójì òru kọjá lọ. Ní gbogbo àkókò
yìí, Jésù kò jẹ nǹkan kan, nítorí náà, ebi wá bẹ̀rẹ̀ sí pa á gan-an. Àkókò yìí ni Sátánì gbìyànjú láti dán Jésù wò.Èṣù sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́, sọ fún àwọn òkúta wọ̀nyí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.’ Wo bí búrẹ́dì ṣe máa dùn tó lẹ́nu rẹ̀ lásìkò yìí tí ebi ń pa á gan-an! Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ Jésù tiẹ̀ lè yí àwọn òkúta padà di búrẹ́dì?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè ṣe é. Kí ni yóò jẹ́ kó lè ṣe é? Ó jẹ́ torí pé Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, ó sì ní agbára àrà ọ̀tọ̀.
Ṣé bí Èṣù bá ní kó o sọ òkúta di búrẹ́dì wàá ṣe bẹ́ẹ̀?— Rántí pé ebi ń pa Jésù o. Nítorí náà, bó bá jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí lásán ni Jésù ṣe é, ǹjẹ́ ìyẹn burú?— Jésù mọ̀ pé kò tọ́ kí òun lo agbára òun lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kí Jésù lo agbára tí òun fún un láti fi mú kí àwọn èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run, kì í ṣe pé kí ó lò ó láti fi gbọ́ tara rẹ̀.
Nítorí náà, Jésù kò ṣe ohun tí Sátánì sọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó wà nínú Bíbélì ni Jésù sọ fún un, ó ní: ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló lè mú kí ènìyàn wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’ Jésù mọ̀ pé ṣíṣe ohun tó mú inú Jèhófà dùn ṣe pàtàkì púpọ̀ gan-an ju rírí oúnjẹ jẹ lọ.
Ṣùgbọ́n Èṣù tún dán an wò sí i. Ó mú Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù ó sì mú kó dúró sí ibì kan tó ga gan-an lórí tẹ́ńpìlì.
Sátánì wá sọ pé: ‘Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ láti ibí yìí. Nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí o fara pa.’Kí ló fà á tí Sátánì fi sọ èyí?— Ó sọ ọ́ láti fi dẹ Jésù wò kó lè hùwà òmùgọ̀. Ṣùgbọ́n Jésù tún kọ̀ láti ṣe ohun tí Sátánì wí. Ó sọ fún Sátánì pé: “A tún kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’” Jésù mọ̀ pé ó lòdì pé kí òun dán Jèhófà wò nípa fífi ẹ̀mí òun wewu.
Síbẹ̀ Sátánì kò jáwọ́ o. Ohun tó tún ṣe ni pé ó mú Jésù lọ sí orí òkè gíga fíofío kan. Láti orí òkè yìí ló ti fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn han Jésù. Lẹ́yìn náà, Sátánì wá sọ fún Jésù pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.”
Ronú nípa ohun tí Èṣù fi lọ̀ ọ́ yìí. Ṣé òótọ́ ni pé Sátánì ló ni gbogbo ìjọba èèyàn wọ̀nyí?— Ó dára, Jésù kò sọ pé Sátánì kọ́ ló ni wọ́n o. Jésù ì bá ti sọ pé irọ́ ló pa, tó bá jẹ́ pé Sátánì kọ́ ló ni wọ́n. Ní tòótọ́, Sátánì gan-an ló ń ṣàkóso gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bíbélì tiẹ̀ pè é ní “olùṣàkóso ayé.”—Jòhánù 12:31.
Kí lo máa ṣe bí Èṣù bá ṣèlérí pé òun yóò fún ọ ní ohun kan tó o bá sin òun?— Jésù mọ̀ pé ó lòdì láti sin Èṣù láìka ohun yòówù tó bá fẹ́ fún òun sí. Nítorí náà Jésù sọ pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí Bíbélì sọ pé, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’—Mátíù 4:1-10; Lúùkù 4:1-13.
Àwa pẹ̀lú máa ń rí ìdẹwò. Ǹjẹ́ o mọ díẹ̀ lára wọn?— Àpẹẹrẹ kan nìyí. Ìyá rẹ lè dín ẹran tàbí àkàrà tó dùn sílẹ̀. Ó lè sọ pé o kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án kó tó di ìgbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun. Ṣùgbọ́n tí ebi bá ń pa ọ́ gan-an, ó lè dà bíi pé kó o jí i jẹ. Ṣé ìwọ yóò ṣègbọràn sí ìyá rẹ?— Sátánì yóò fẹ́ kó o ṣàìgbọràn.
Rántí Jésù. Ebi pa òun náà dáadáa. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju oúnjẹ jíjẹ lọ. Tí o bá ṣe bí ìyá rẹ ṣe sọ, á jẹ́ pé ò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.
Àwọn ọmọdé ẹlẹgbẹ́ rẹ lè fún ọ ní hóró oògùn kan pé kó o gbé e mì. Wọ́n lè sọ pé èyí á mú kí orí rẹ yá gágá. Ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ oògùn olóró ni wọ́n ń fún ẹ. Oògùn náà lè pa ọ́ lára tàbí kó tiẹ̀ ṣekú pa ọ́ pàápàá. Ẹnì kan tún lè fún ẹ ní
sìgá, tó jẹ́ pé òun náà ní oògùn olóró nínú, kí ẹni náà wá sọ pé kó o fà á wò tó o bá tó bẹ́ẹ̀. Kí lo máa ṣe?—Rántí Jésù. Sátánì fẹ́ mú kí Jésù fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nígbà tó sọ fún Jésù pé kí ó bẹ́ sílẹ̀ láti orí tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀ o. Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan bá fẹ́ tì ọ́ ṣe ohun tó léwu?— Jésù kọ̀ láti ṣe ohun tí Sátánì wí o. Bákan náà, bí ẹnì kan bá sọ pé kí o ṣe ohun tó lòdì ìwọ náà gbọ́dọ̀ kọ̀.
Ó lè di ọjọ́ kan, kí wọ́n ní kí o wá ṣe ohun kan láti fi jọ́sìn ère, Bíbélì sì ti sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Ó lè jẹ́ pé ìgbà ayẹyẹ kan ní ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n á sọ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè sọ fún ẹ pé o kò gbọ́dọ̀ wá sí ilé ẹ̀kọ́ mọ́ tó o bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí lo máa ṣe?—
Ó máa ń rọrùn láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń ṣe é. Ṣùgbọ́n ó lè ṣòro gan-an láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí àwọn èèyàn bá ń gbìyànjú láti mú wa ṣe ohun tí kò tọ́. Wọ́n lè sọ fún wa pé kò sí ohun tó burú nínú ohun tí àwọn ń ṣe. Ṣùgbọ́n nǹkan pàtàkì tó yẹ ká máa bi ara wa léèrè ni pé, Kí ni Ọlọ́run sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run ló mọ ohun tó dára jù lọ tó yẹ ká ṣe.
Nítorí náà, ohun yòówù kí àwọn ẹlòmíràn sọ, a kò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run ti sọ pé ó lòdì o. Èyí ni yóò jẹ́ kí a máa mú inú Ọlọ́run dùn nígbà gbogbo, a kò sì ní ṣe ohun tí Èṣù fẹ́ rárá.
A lè rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí a ṣe lè kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tó burú nínú Sáàmù 1:1, 2; Òwe 1:10, 11; Mátíù 26:41; àti 2 Tímótì 2:22.