ORÍ 19
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jà?
ǸJẸ́ o mọ àwọn ọmọdé tí wọ́n máa ń ṣe agídí tí wọ́n sì máa ń ṣe bíi pé wọ́n lágbára gan-an?— Ǹjẹ́ o máa ń fẹ́ láti bá wọn rìn? Tàbí o máa ń fẹ́ láti bá ẹnì kan tó níwà tútù tó sì ń fẹ́ àlàáfíà rìn?— Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé: ‘Aláyọ̀ ni àwọn tó ní ẹ̀mí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní “ọmọ Ọlọ́run.”’—Mátíù 5:9.
Ṣùgbọ́n nígbà mìíràn àwọn ẹlòmíràn lè ṣe àwọn ohun tó ń bí wa nínú. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Nítorí náà, a lè fẹ́ gbẹ̀san padà. Láyé àtijọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tí wọ́n ń bá Jésù rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù. Jẹ́ kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọ.
Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀, Jésù rán àwọn kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣáájú lọ sí ìlú Samáríà kan níwájú pé kí wọ́n lọ wá ibì kan tí wọ́n máa lè sùn sí. Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú yẹn ò fẹ́ kí wọ́n dúró ní ìlú
àwọn nítorí pé ẹ̀sìn àwọn ará Samáríà yàtọ̀. Wọn kò fẹ́ràn ẹnikẹ́ni tó bá ń rìnrìn àjò lọ sí ìlú Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe ìsìn.Bó bá jẹ́ ìwọ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí lo máa ṣe? Ṣé ìwọ yóò bínú? Ṣé ìwọ yóò fẹ́ láti gbẹ̀san?— Ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù àti Jòhánù fẹ́ ṣe nìyẹn. Wọ́n sọ fún Jésù pé: ‘Ṣé o fẹ́ kí a sọ fún iná kí ó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, kí ó sì jó wọn run?’ Abájọ tí Jésù fi pè wọ́n ní Ọmọ Ààrá! Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé kò yẹ kí wọ́n hùwà bẹ́ẹ̀ sí ọmọnìkejì wọn.—Lúùkù 9:51-56; Máàkù 3:17.
Lóòótọ́ àwọn èèyàn lè hùwà tí kò dára sí wa nígbà mìíràn. Àwọn ọmọ mìíràn lè máà fẹ́ kí á bá àwọn ṣeré pa pọ̀. Wọ́n tiẹ̀ lè sọ pé: “Àwa ò bá ọ ṣeré o.” Bí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó lè dùn wá, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwa náà lè fẹ́ ṣe ohun kan padà fún wọn láti gbẹ̀san. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó yẹ kí á ṣe bẹ́ẹ̀?—
O ò ṣe gbé Bíbélì rẹ? Jẹ́ ká ṣí ìwé Òwe orí kẹrìnlélógún [24], ẹsẹ ìkọkàndínlọ́gbọ̀n [29]. Ó kà báyìí pé: ‘Má sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí mi gan-an, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí i. Èmi yóò san án padà fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe.”’
Kí ni o rò pé ẹsẹ yẹn ń sọ?— Ohun tó ń sọ ni pé kí á má ṣe gbìyànjú láti máa gbẹ̀san. Kí á má ṣe ṣìkà fún èèyàn nítorí pé ẹni náà ti ṣìkà fún wa. Bí ẹnì kan bá wá tọ́ ìjà rẹ ńkọ́? Ó lè máa pè ọ́ ní orúkọ tí kò dára torí kí o lè bínú. Ó lè máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pé ojo ni ọ́. Bóyá ó tiẹ̀ sọ pé ọ̀lẹ ni ọ́. Kí ló yẹ kí o ṣe? Ṣé ó yẹ kí o bá a jà?—
Lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì sọ. Ṣí Bíbélì rẹ sí Mátíù orí karùn-ún [5] ẹsẹ ìkọkàndínlógójì [39]. Jésù sọ níbẹ̀ pé: ‘Má ṣe kọjú ìjà sí ẹni burúkú; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú.’ Kí ni o rò pé Jésù ń fẹ́ kí á ṣe nínú ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí? Ṣé ohun tí Jésù fẹ́ kí á máa ṣe ni pé, bí ẹnì kan bá fi ẹ̀ṣẹ́ gbá apá kan ojú rẹ, kí o jẹ́ kó gbá ọ ní apá kejì pẹ̀lú?—
Rárá o, ìyẹn kọ́ ni Jésù fẹ́ kí á ṣe. Bí a bá fi ọwọ́ gbáni, kò lè dunni tó ká fi ẹ̀ṣẹ́ gbáni. Ó kàn dà bíi pé kí á ti ẹnì kan tàbí kí á taari rẹ̀ sẹ́yìn ni. Ẹnì kan lè fi ọwọ́ gbá wa láti fi tọ́ ìjà wa. Ṣe ló ń fẹ́ kí á bínú. Bí á bá sì bínú, tí a sì tì í tàbí tí a taari rẹ̀ sẹ́yìn, kí ló máa ṣẹlẹ̀?— Ó ṣeé ṣe kí o di ìjà.
Ṣùgbọ́n Jésù kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jà. Nítorí náà, ó sọ pé tí ẹnì kan bá gbá wa ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, kí á má ṣe gbá tirẹ̀ padà. Kí á má ṣe bínú kí á sì bẹ̀rẹ̀ sí jà. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a fi hàn pé a kò sàn ju ẹni tó bẹ̀rẹ̀ ìjà náà.
Tí ìjàngbọ̀n bá bẹ̀rẹ̀, kí ni o rò pé ó dára jù láti ṣe?— Òun ni pé kí o rìn kúrò níbẹ̀ kí o máa lọ. Ẹni tí ó fẹ́ bá ọ jà náà lè tì ọ́ tàbí kí ó taari rẹ díẹ̀ sí i. Àmọ́ ó lè má ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí o ṣe rìn kúrò níbẹ̀, kò fi hàn pé ọ̀lẹ ni ọ́. Ńṣe ló kàn fi hàn pé o lágbára láti ṣe ohun tí ó tọ́.
Ṣùgbọ́n kí á sọ pé o bá ẹni náà jà tí o sì nà án dáadáa ńkọ́? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?— Ẹni tí o nà dáadáa yẹn lè lọ pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá. Wọ́n sì lè wá la igi mọ́ ọ tàbí kí wọ́n fi ọ̀bẹ gun ọ. Ṣé o ti wá rí ohun tó fà á tí Jésù kò fi fẹ́ kí á máa jà?—
Kí ni ó yẹ kí á ṣe tí a bá rí i pé àwọn èèyàn mìíràn ń jà? Ṣé ó yẹ kí á gbèjà ẹnì kan ká sì máa bá ẹnì kejì jà?— Bíbélì sọ ohun tí ó tọ́ láti ṣe fún wa. Ṣí Bíbélì rẹ sí Òwe orí kẹrìndínlọ́gbọ̀n [26], ẹsẹ ìkẹtàdínlógún [17]. Ó kà pé: ‘Bí ẹni tí ó gbá etí ajá mú ni ẹnikẹ́ni tí ń kọjá lọ, tí ó ń bínú gan-an nítorí ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.’
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí o bá gbá etí ajá mú? Yóò dun ajá náà, yóò sì fẹ́ gé ọ jẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí ajá yẹn bá ṣe ń fẹ́ gba ara rẹ̀ ni ìwọ yóò máa túbọ̀ di etí rẹ̀ mú, ajá náà yóò sì túbọ̀ máa kanra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Tí o bá fi ajá náà sílẹ̀, ó lè bù ọ́ jẹ. Ṣùgbọ́n ṣé wàá lè mú etí rẹ̀ dání títí láé?—
Irú wàhálà tí a máa ní nìyẹn tí a bá dá sí ìjà àwọn ẹlòmíràn. A lè má mọ ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjà náà tàbí ìdí tí wọ́n fi ń jà. Wọ́n lè máa na ẹnì kan, àmọ́ ó lè jẹ́ pé onítọ̀hún jí
nǹkan ẹni tó ń nà án ni. Bí a bá gbèjà rẹ̀, a jẹ́ pé à ń gbèjà olè nìyẹn. Ìyẹn ò sì ní dára, àbí?Nítorí náà, kí ni ó yẹ kí o ṣe bí o bá rí i pé àwọn kan ń jà?— Tí ó bá jẹ́ ní ilé ìwé, o lè sáré lọ sọ fún olùkọ́ kan. Bí kì í bá ṣe ilé ìwé, o lè lọ pe òbí rẹ tàbí ọlọ́pàá kan. Nítorí náà, bí àwọn ẹlòmíràn bá tiẹ̀ fẹ́ láti jà, àwa ní láti jẹ́ ẹni tó ní ẹ̀mí àlàáfíà.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti má ṣe jà. Lọ́nà báyìí, a ó fi hàn pé a ní agbára láti ṣe ohun tí ó tọ́. Bíbélì sọ pé ‘kò yẹ kí ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.’—2 Tímótì 2:24.
Wàyí o, jẹ́ kí á wo àfikún ìmọ̀ràn rere tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìjà: Róòmù 12:17-21 àti 1 Pétérù 3:10, 11.