Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 10

Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ

Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ

Òwe 8:4, 7

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Tó o bá ń gbóhùn sókè tó o sì ń rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ bó ṣe yẹ, tí ò ń lo oríṣiríṣi ìró ohùn, tó o sì ń yí bó o ṣe ń yára sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ pa dà, ọ̀rọ̀ rẹ á ṣe kedere, á sì wọni lọ́kàn.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Máa gbóhùn sókè kó o sì máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ bó ṣe yẹ. Gbóhùn sókè tí o bá fẹ́ sọ àwọn kókó pàtàkì tó o fẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ṣiṣẹ́ lé lórí. Ohun kan náà ni kó o ṣe tó o bá fẹ́ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́. Rẹ ohùn rẹ sílẹ̀ tó o bá fẹ́ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ máa fojú sọ́nà sí ohun tó o fẹ́ sọ tẹ̀ lé e tàbí tó o bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ẹni tí ẹ̀rù ń bà tàbí tí ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀.

  • Lo oríṣiríṣi ìró ohùn. Tí èdè rẹ bá fàyè gbà á, jẹ́ kí ohùn rẹ túbọ̀ rinlẹ̀ tó o bá fẹ́ fi ìtara sọ ọ̀rọ̀ kan tàbí tó o fẹ́ ṣàlàyé bí nǹkan ṣe tóbi tó tàbí bí ibì kan ṣe jìnnà tó. Ohùn tó dẹ̀ ni kó o fi sọ ọ̀rọ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bà jẹ́ tàbí tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀.

  • Máa yí bó o ṣe ń yára sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ pa dà. Yára sọ̀rọ̀ tó o bá fẹ́ sọ̀rọ̀ ẹni tí ara rẹ̀ yá gágá tí inú rẹ̀ sì ń dùn. Rọra sọ̀rọ̀ tó o bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì.