Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 6

Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere

Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere

Jòhánù 10:33-36

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Má kàn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan kó o sì bọ́ sórí kókó ọ̀rọ̀ míì. Jẹ́ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i kedere bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà ṣe bá kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tán, tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ tó bá kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ mu. Lára ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o tún àwọn ọ̀rọ̀ yẹn pè tàbí kó o béèrè ìbéèrè kan tó máa jẹ́ káwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ dá àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ mọ̀.

  • Tẹnu mọ́ kókó pàtàkì. Tó o bá pe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, tó o sì ti sọ ìdí tó o fi fẹ́ kà á, ṣàlàyé bí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe bá ohun tó o sọ yẹn mu.

  • Má ṣe àlàyé tí kò pọn dandan. Má ṣe àlàyé tí kò tan mọ́ kókó pàtàkì tí ò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kọ́kọ́ ronú nípa ohun tí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ ti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yẹn àti bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó, lẹ́yìn náà kó o wá pinnu bó ṣe yẹ kí àlàyé rẹ pọ̀ tó kí ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí tó lè yé wọn.