Ẹ̀KỌ́ 7
Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà
Lúùkù 1:3
KÓKÓ PÀTÀKÌ: Lo ẹ̀rí tó ṣeé gbára lé láti mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
-
Mú ọ̀rọ̀ rẹ láti ibi tó ṣeé gbára lé. Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni kó o gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà, kà á jáde ní tààràtà láwọn ìgbà tó bá ṣeé ṣe. Tó o bá fẹ́ fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwádìí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe tàbí ìròyìn kan, ó sì lè jẹ́ ìrírí kan tàbí ńṣe lo fẹ́ lo àwọn ẹ̀rí míì láti ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn, rí i dájú pé o ṣe ìwádìí tó yẹ, kó o lè mọ̀ bóyá àwọn nǹkan yẹn ṣì rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ tí wọ́n sì bá ìgbà mu.
-
Lo ìsọfúnni lọ́nà tó tọ́. Jẹ́ kí àlàyé tó o bá ṣe nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bá ohun tí ẹsẹ yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mu, kó bá ohun tí Bíbélì dá lé mu, kó sì bá ohun tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jádé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” mu. (Mát. 24:45) Lo àwọn ìsọfúnni míì tó o mú láti àwọn ibòmíì tó yàtọ̀ sí Bíbélì lọ́nà tó bá ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn mu.
-
Mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ronú lórí ẹ̀rí tó o mú wá. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí tó o tọ́ka sí ìsọfúnni kan, béèrè àwọn ìbéerè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tàbí kó o ṣàkàwé kókó tó wà níbẹ̀ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ lè rí ohun tó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ fúnra wọn.