Ẹ̀kọ́ 11
Wọ́n Kọ Ìwé Nípa Jésù
Ǹjẹ́ o rí àwọn ọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí?— Orúkọ wọn ni Mátíù, Máàkù, Lúùkù, Jòhánù, Pétérù, Jákọ́bù, Júúdà àti Pọ́ọ̀lù. Ìgbà kan náà ni gbogbo wọ́n gbé láyè pẹ̀lú Jésù, wọ́n kọ ìwé nípa ìgbésí ayé Jésù. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa wọn.
Kí lo mọ̀ nípa àwọn ọkùnrin yìí?
Mẹ́ta nínú wọn jẹ́ àpọ́sítélì Jésù, wọ́n sì tẹ̀ lé e lọ wàásù. Ǹjẹ́ o mọ àwọn mẹ́ta yẹn?— Àwọn ni Mátíù, Jòhánù àti Pétérù. Àpọ́sítélì Mátíù àti àpọ́sítélì Jòhánù mọ Jésù dáadáa, àwọn méjèèjì sì kọ ìwé nípa ìgbésí ayé
Jésù. Àpọ́sítélì Jòhánù ló tún kọ ìwé Ìṣípayá àti lẹ́tà mẹ́ta nínú Bíbélì tí à ń pè ní Jòhánù Kìíní, Jòhánù Kejì àti Jòhánù Kẹta. Àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà méjì nínú Bíbélì. Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì ni à ń pe àwọn lẹ́tà náà. Nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì, Pétérù kọ̀wé nípa ìgbà tí Jèhófà sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, tó sì sọ nípa Jésù pé: ‘Èyí ni ọmọ mi. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, inú mi sì dùn sí i.’Àwọn ọkùnrin yòókù tó wà nínú àwòrán yìí tún kọ́ wa ní àwọn nǹkan kan nípa Jésù nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ nínú Bíbélì. Ọ̀kan nínú wọn ni Máàkù. Ó ṣeé ṣe kí ó wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn aláṣẹ wá mú Jésù, ó sì rí gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀. Ẹlòmíì tún ni Lúùkù. Dókítà ni, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù kú ló di Kristẹni.
Àwọn méjì míì lára àwọn tó kọ Bíbélì, tí wọ́n wà nínú àwòrán yìí jẹ́ àbúrò Jésù. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ wọn?— Jákọ́bù àti Júúdà ni orúkọ wọn. Wọn kò kọ́kọ́ gba Jésù gbọ́. Wọ́n tiẹ̀ rò pé orí rẹ̀ ti yí. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n gba Jésù gbọ́, wọ́n sì di Kristẹni.
Ẹni tó tún wà lára àwọn tó kọ Bíbélì, tó wà nínú àwòrán yìí ni Pọ́ọ̀lù. Kó tó di Kristẹni, Sọ́ọ̀lù ni orúkọ rẹ̀. Ó kórìíra àwọn Kristẹni, ó sì ń hùwà ìkà sí wọn. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni?— Lọ́jọ́ kan, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rin ìrìn àjò, lójijì ló gbọ́ tí ẹnì kan bá a sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Àṣé Jésù ló ń bá a sọ̀rọ̀! Jésù bi Pọ́ọ̀lù pé: ‘Kí ló dé tí ò ń hùwà ìkà sí àwọn tó gbà mí gbọ́?’ Lẹ́yìn ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù yí pa dà, ó sì di Kristẹni. Ìwé mẹ́rìnlá ni Pọ́ọ̀lù kọ nínú Bíbélì, látorí ìwé Róòmù títí dé ìwé Hébérù.
A máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ àbí?— Tí o bá ń ka Bíbélì wàá kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Jésù. Ṣé nǹkan tó wù ẹ́ kó o ṣe nìyẹn?—