ORÍ KEJÌDÍNLÓGÚN
Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’
1, 2. Kí lo lè sọ nípa ìrìn àjò Màríà? Kí ló mú kí ìrìn àjò náà nira fún un?
MÀRÍÀ rúnra lórí ẹranko arẹrù kékeré tó jókòó lé. Ó ti tó ọ̀pọ̀ wákàtí tó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà bọ̀, ara sì ń ni ín. Jósẹ́fù rọra ń fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ lójú ọ̀nà jíjìn tó lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Màríà ń mọ̀ ọ́n lára bí ọmọ tó wà níkùn rẹ̀ ṣe ń sọ kúlú.
2 Ikùn Màríà ti ga gan-an. Gbólóhùn tí Bíbélì fi ṣàlàyé ipò tó wà nígbà yẹn ni pé “ó ti sún mọ́ àkókò àtibímọ.” (Lúùkù 2:5) Bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe ń kọjá àwọn oko tó wà létí ọ̀nà, àwọn àgbẹ̀ tó ń kọbè tàbí tó ń fún irúgbìn lè máa kọminú nípa ohun tó fà á tí obìnrin tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bímọ yìí fi ń rìnrìn àjò. Kí ló fà á tí Màríà fi rìn jìnnà tó bẹ́ẹ̀ sí ibi tó ń gbé ní Násárétì?
3. Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run fún Màríà? Kí la máa fẹ́ láti mọ̀ nípa Màríà?
3 Ní ọ̀pọ̀ oṣù sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run fún ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ Júù yìí ní iṣẹ́ kan tá ò gbọ́ irú ẹ̀ rí látọjọ́ tí aláyé ti dáyé. Ó máa bí ọmọ tó máa di Mèsáyà, ìyẹn Ọmọ Ọlọ́run! (Lúùkù 1:35) Bí àsìkò tó máa bímọ ṣe ń sún mọ́lé, ó di dandan kó rin ìrìn àjò yìí. Nígbà ìrìn àjò náà sì rèé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló dán ìgbàgbọ́ Màríà wò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.
Wọ́n Lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
4, 5. (a) Kí nìdí tí Jósẹ́fù àti Màríà fi ń lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni àṣẹ tí Késárì pa mú kó ṣẹ?
4 Jósẹ́fù àti Màríà nìkan kọ́ ló rìnrìn àjò. Ìdí ni pé Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ṣẹ̀ṣẹ̀ pàṣẹ ni pé kí gbogbo èèyàn tó wà ní ilẹ̀ náà lọ forúkọ sílẹ̀. Torí náà àwọn èèyàn ní láti rìnrìn àjò lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn kí wọ́n lè pa àṣẹ náà mọ́. Kí ni Jósẹ́fù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Bí a ti lè retí, Jósẹ́fù pẹ̀lú gòkè lọ láti Gálílì, kúrò ní ìlú ńlá Násárétì, lọ sí Jùdíà, sí ìlú ńlá Dáfídì, èyí tí a ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ mẹ́ńbà ilé àti ìdílé Dáfídì.”—Lúùkù 2:1-4.
5 Àṣẹ tí Késárì pa ò ṣèèṣì bọ́ sí àkókò yẹn. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje [700] ọdún ṣáájú ìgbà náà ni àsọtẹ́lẹ̀ ti wà pé Míkà 5:2.) Kí àwọn tó ń rin ìrìn àjò láti ìlú Násárétì tó lè dé abúlé kékeré yẹn, wọ́n máa rin ìrìn àádóje [130] kìlómítà ní ojú ọ̀nà tí òkè pọ̀ sí, wọ́n á sì gba Samáríà kọjá. Bẹ́tílẹ́hẹ́mù yẹn ni àṣẹ Késárì sọ pé kí Jósẹ́fù lọ, torí ibẹ̀ ni ìlú ìbílẹ̀ Dáfídì Ọba, ìlà ìdílé yẹn sì ni Jósẹ́fù àti ìyàwó rẹ̀ ti wá.
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí. Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ìlú kan wà tó ń jẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí kò ju kìlómítà mọ́kànlá sí Násárétì. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ ní pàtó pé “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni Mèsáyà ti máa wá. (Ka6, 7. (a) Kí nìdí tó fi máa ṣòro fún Màríà láti rìnrìn àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù? (b) Ìyàtọ̀ wo ló dé bá ọ̀nà tí Màríà ń gbà ṣe ìpinnu látìgbà tó ti di ìyàwó Jósẹ́fù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Ṣé Màríà máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jósẹ́fù láti ṣègbọràn sí àṣẹ Késárì? Ó ṣe tán, ó máa ṣòro fún Màríà láti rin ìrìn àjò náà. Ó jọ pé apá ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ni, torí náà ó ṣeé ṣe kí òjò ti máa fún wínníwínní, torí pé ìgbà ẹ̀rùn á ti máa kásẹ̀ nílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, gbólóhùn náà, “gòkè lọ láti Gálílì” bá a mu gan-an ni, torí pé orí òkè téńté tó ga tó òjì-dín-lẹ́gbẹ̀rin [760] mítà (ìyẹn, ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ẹsẹ bàtà) ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wà. Kò rọrùn rárá láti fi òkè pípọ́n tó ń tánni lókun yìí parí ìrìn àjò gígùn tó ti gbà ọ̀pọ̀ ọjọ́! Ó tún ṣeé ṣe kí ìrìn àjò náà pẹ́ wọn ju bó ṣe máa ń rí lọ, torí ipò tí Màríà wà máa gba pé kí wọ́n máa dúró sinmi léraléra. Nírú àsìkò yìí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin ló máa fẹ́ wà nílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ tó máa tètè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tọ́mọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í
mú wọn. Kò sí àní-àní pé kí Màríà tó lè rin ìrìn àjò yìí, ó gbọ́dọ̀ ní ìgboyà.7 Síbẹ̀, Lúùkù sọ pé Jósẹ́fù lọ “láti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Màríà.” Ó tún sọ pé a ti fi Màríà fún Jósẹ́fù “nínú ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí a ti ṣèlérí.” (Lúùkù 2:4, 5) Láti ìgbà tí Màríà ti di ìyàwó Jósẹ́fù ni ìyàtọ̀ ti dé bá ọ̀nà tí Màríà gbà ń ṣe ìpinnu. Ó mọ̀ pé ọkọ òun ni Ọlọ́run yàn ṣe orí òun, ó sì fi ọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe tí Ọlọ́run fún un gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ nípa kíkọ́wọ́ ti ìpinnu tí ọkọ rẹ̀ bá ṣe. * Bí Màríà ṣe múra tán láti máa ṣègbọràn sí ọkọ rẹ̀ yìí fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́.
8. (a) Ohun mìíràn wo ló ṣeé ṣe kó fà á tí Màríà fi gbà láti bá Jósẹ́fù lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Màríà ṣe jẹ́ ìṣírí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?
8 Ohun mìíràn wo ló tún ṣeé ṣe kó fà á tí Màríà fi ṣègbọràn? Ṣó mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí ni? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó mọ̀, torí pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ò ṣàjèjì sí àwọn àlùfáà àgbà àti àwọn akọ̀wé àti àwọn èèyàn lápapọ̀. (Mát. 2:1-7; Jòh. 7:40-42) Tó bá sì dọ̀rọ̀ kéèyàn mọ Ìwé Mímọ́, Màríà ò kẹ̀rẹ̀. (Lúùkù 1:46-55) Lọ́rọ̀ kan ṣá, yálà Màríà lọ nítorí kó lè ṣègbọràn sí ọkọ rẹ̀ ni o tàbí torí kó lè ṣègbọràn sí àṣẹ ìjọba tàbí torí pé ó mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà, tàbí nítorí ìdí tó ju ẹyọ kan lọ lára èyí, pàtàkì ibẹ̀ ni pé ó fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ fún wa. Jèhófà mọyì àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì máa ń ṣègbọràn. Lóde òní táwọn èèyàn ò ka ìtẹríba sí ohun tó gbayì láwùjọ, ìṣírí ni àpẹẹrẹ tí Màríà fi lélẹ̀ jẹ́ fún àwa ìránṣẹ́ Jèhófà níbi gbogbo.
Ìbí Kristi
9, 10. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí Màríà àti Jósẹ́fù máa ronú nípa rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù? (b) Ibo ni Màríà àti Jósẹ́fù sùn mọ́jú, kí sì nìdí?
9 Màríà ti ní láti mí kanlẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ rí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ́ọ̀ọ́kán. Bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe ń gòkè lọ ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè náà, tí wọ́n ń kọjá lára àwọn igi ólífì, tó jẹ́ ọ̀kan lára ohun ọ̀gbìn tí wọ́n máa ń kórè kẹ́yìn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú nípa ìtàn abúlé kékeré náà. Bí wòlíì Míkà ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ìlú yìí kéré ju èyí tí wọ́n lè kà mọ́ àwọn ìlú Júdà. Síbẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n bí Bóásì, Náómì àti Dáfídì sí, ní èyí tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn.
10 Nígbà tí Màríà àti Jósẹ́fù dé ìlú náà, èrò ti kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Àwọn míì ti débẹ̀ ṣáájú wọn láti wá forúkọ sílẹ̀, torí náà kò sí àyè fún wọn mọ́ ní ibi tí àwọn àlejò máa ń wọ̀ sí. * Kò sí ibòmíì tí wọ́n lè sùn mọ́jú ju ilé ẹran lọ. Ẹ wo wàhálà ọkàn tó máa bá Jósẹ́fù nígbà tí ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ irú ìrora kan tí kò jẹ rí, tí ìrora náà sì ń pọ̀ sí i. Lọ́rọ̀ kan ṣá, inú ilé ẹran yìí ni wọ́n wà tí Màríà fi bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí.
11. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn obìnrin níbi gbogbo á mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà lára? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “àkọ́bí”?
11 Àwọn obìnrin níbi gbogbo á mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà lára. Ìdí ni pé ní nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún, gbogbo obìnrin lá máa jẹ̀rora nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bímọ. (Jẹ́n. 3:16) Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ti Màríà yàtọ̀. Ìwé Lúùkù ò ṣàlàyé ìrora tí Màríà jẹ, ńṣe ló kàn sọ pé: “Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí.” (Lúùkù 2:7) Báyìí ni Màríà ṣe bí “àkọ́bí” rẹ̀, ìyẹn àkọ́kọ́ nínú ọmọ púpọ̀ tí Màríà bí. Ó kéré tán, wọ́n tó méje. (Máàkù 6:3) Àmọ́, ó dájú pé èyí tó kọ́kọ́ bí yìí kò ní ní àfiwé. Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àkọ́bí Màríà, ó tún jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” Jèhófà, ìyẹn Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run!—Kól. 1:15.
12. Ibo ni Màríà tẹ́ ọmọ jòjòló náà sí? Báwo ni èyí ṣe yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n máa ń fi hàn nínú àwọn àwòrán àti eré nípa ìbí Jésù?
12 Bíbélì wá sọ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ nípa ìtàn Jésù, ó ní: Lúùkù 2:7) Nínú àwọn àwòrán àti eré nípa ìbí Jésù, wọ́n máa ń mú kí ibùjẹ ẹran náà fani mọ́ra lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká wo bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an. Inú ibi tí ẹran ọ̀sìn ti máa ń jẹun ni ibùjẹ ẹran. Ká sì rántí pé ilé ẹran ni Jósẹ́fù àti Màríà sùn, irú ibẹ̀ yẹn kì í mọ́ tónítóní nígbà yẹn tàbí lóde òní pàápàá, kódà á máa rùn. Tó bá jẹ́ pé ibòmíì wà ni, òbí wo ló máa yàn láti lọ bímọ sírú ibẹ̀ yẹn? Kò sí òbí tí kò fẹ́ nǹkan tó dára fún àwọn ọmọ rẹ̀. Nítorí náà, ibi tó dára jù lọ ló máa wu Màríà àti Jósẹ́fù pé kí wọ́n bí Ọmọ Ọlọ́run sí.
“Ó sì fi àwọn ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran kan.” (13. (a) Báwo ni Màríà àti Jósẹ́fù ṣe lo ohun tí wọ́n ní lọ́nà tó dára jù lọ? (b) Báwo làwọn òbí tó gbọ́n lóde òní ṣe lè fìwà jọ Jósẹ́fù àti Màríà?
13 Àmọ́ ṣá o, kàkà kí wọ́n banú jẹ́ nítorí ipò tí wọ́n wà yìí, ńṣe ni wọ́n lo ohun tí wọ́n ní lọ́nà tó dára jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí i pé Màríà fúnra rẹ̀ ló tọ́jú ọmọ jòjòló náà, ó fi ọ̀já wé e torí òtútù, ó rọra tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran kó lè sùn, ó sì rí i dájú pé kò sí ohun tó máa ṣe é. Màríà ò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa ipò tó wà yìí débi tí kò fi ní lè ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́jú ọmọ náà. Òun àti Jósẹ́fù sì tún mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn lè ṣe fún ọmọ náà ni kí àwọn kọ́ ọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Ka Diutarónómì 6:6-8.) Lóde òní, nínú ayé táwọn èèyàn ò ti mọyì ìjọsìn Ọlọ́run yìí, àwọn òbí tó gbọ́n mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì pé kí àwọn náà ṣe nìyẹn.
Ìbẹ̀wò Kan Gbé Ìgbàgbọ́ Wọn Ró
14, 15. (a) Kí nìdí tó fi ń ṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà bíi pé kí wọ́n ti rí ọmọ náà? (b) Kí ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe nípa ohun tí wọ́n rí ní ilé ẹran náà?
14 Ariwo ṣàdédé gba ilé ẹran náà kan nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn rọ́ wọlé kí wọ́n lè rí àwọn òbí ọmọ náà àti ọmọ wọn ní pàtàkì. Inú àwọn ọkùnrin yìí dùn gan-an, ayọ̀ sì hàn lójú wọn. Ńṣe ni wọ́n sáré wá láti ẹ̀bá àwọn òkè níbi tí àwọn àti àwọn agbo ẹran wọn ń gbé. * Kàyéfì lèyí jẹ́ fún Màríà àti Jósẹ́fù. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà wá ṣàlàyé ohun àgbàyanu tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí fún wọn. Wọ́n ní nígbà tí àwọn wà ní ẹ̀bá òkè láàárín òru, áńgẹ́lì kan ṣàdédé yọ sí àwọn. Ògo Jèhófà mọ́lẹ̀ yòò yí àwọn ká, áńgẹ́lì náà sì wá sọ fún àwọn pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí Kristi, tàbí Mèsáyà, ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni, àti pé àwọn máa rí ọmọ tí a fi ọ̀já wé náà níbi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí ní ibùjẹ ẹran. Wọ́n tún sọ pé lẹ́yìn èyí, àwọn wá rí ohun àràmàǹdà kan, ìyẹn ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì tó ń kọrin yin Ọlọ́run!—Lúùkù 2:8-14.
Lúùkù 2:17, 18) Ńṣe ni àwọn aṣáájú ìsìn ayé ìgbà yẹn máa ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn. Ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé Jèhófà mọyì àwọn ọkùnrin tó ní ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ yìí. Kí ni ìbẹ̀wò yìí mú kí Màríà ṣe?
15 Abájọ tí àwọn ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí fi sáré wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù! Inú wọn ti ní láti dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí ọmọ jòjòló kan níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ fún wọn. Wọ́n sọ ìhìn rere yìí fún àwọn ẹlòmíì, torí Bíbélì sọ pé: “Wọ́n sọ àsọjáde . . . yìí di mímọ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n sì gbọ́ ni ẹnu yà sí àwọn ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún wọn.” (Ó ṣe kedere pé Jèhófà mọyì àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ní ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ yìí
16. Kí ló fi hàn pé òótọ́ ni Màríà ní àròjinlẹ̀? Kí ni èyí kọ́ wa nípa ohun tó mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára?
16 Ó ti rẹ Màríà tẹnutẹnu torí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ni, síbẹ̀ ó fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ. Kò wá mọ síbẹ̀ o! Bíbélì sọ pé: “Màríà bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́, ní dídé ìparí èrò nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Lúùkù 2:19) Màríà ní àròjinlẹ̀ ní tòótọ́. Ó mọ̀ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán àwọn áńgẹ́lì yìí ṣe pàtàkì. Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀, fẹ́ kó mọ irú ọmọ tó bí kó sì mọ bí ọmọ náà ti ṣe pàtàkì tó. Kì í wá ṣe pé ó fetí sí wọn nìkan ni, ó tún fi gbogbo ohun tí wọ́n sọ sọ́kàn kó lè máa ronú lé wọn lórí bí oṣù ti ń gorí oṣù, tí ọdún sì ń gorí ọdún. Èyí sì ni ohun pàtàkì tó mú kí Màríà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.—Ka Hébérù 11:1.
17. Báwo la ṣe lè fi ọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi ti Màríà?
17 Ṣé wàá fìwà jọ Màríà? Jèhófà ti fi àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì kún inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́ tá ò bá kọ́kọ́ fiyè sí àwọn òtítọ́ pàtàkì tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò ní lè ṣe wá láǹfààní. Bí Bíbélì ṣe lè ṣe wá láǹfààní ni pé ká máa kà á déédéé bí Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, kì í ṣe bí ìwé àkàgbádùn lásán. (2 Tím. 3:16) Lẹ́yìn náà, bíi ti Màríà, a gbọ́dọ̀ máa pa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ nínú ọkàn wa, kó lè máa ràn wá lọ́wọ́ láti dé ìparí èrò tó tọ́. Tá a bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tá à ń kà nínú Bíbélì, tá à ń ronú nípa bá a ṣe lè túbọ̀ máa fi àwọn ìtọ́ni Jèhófà sílò, èyí á mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ máa lágbára.
Ọ̀rọ̀ Kù Tí Màríà Máa Pa Mọ́ Sínú Ọkàn Rẹ̀
18. (a) Báwo ni Màríà àti Jósẹ́fù ṣe pa Òfin Mósè mọ́ nígbà tí Jésù ṣì wà ní ìkókó? (b) Kí ni ohun tí Jósẹ́fù àti Màríà fi rúbọ ní tẹ́ńpìlì jẹ́ ká mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lówó tó?
18 Nígbà tó pé ọjọ́ mẹ́jọ tí wọ́n bí ọmọ náà, Màríà àti Jósẹ́fù dádọ̀dọ́ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mósè, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ. (Lúùkù 1:31) Nígbà tí ogójì [40] ọjọ́ sì pé, wọ́n gbé e láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn kìlómítà bíi mẹ́wàá. Wọ́n fi ohun tí Òfin sọ pé àwọn òbí tó jẹ́ tálákà lè lò rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́, ìyẹn oriri méjì tàbí ẹyẹlé méjì. Bí ojú bá tiẹ̀ tì wọ́n torí pé agbára wọn ò gbé e láti fi àgbò kan àti ẹyẹ àdàbà kan rúbọ bíi ti àwọn òbí míì, wọn ò jẹ́ kí ìyẹn dààmú wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé ìgbàgbọ́ wọn ró nígbà tí wọ́n wà ní tẹ́ńpìlì.—Lúùkù 2:21-24.
19. (a) Àwọn ohun wo ni Síméónì sọ tí Màríà tún ní láti pa mọ́ sínú ọkàn rẹ̀? (b) Kí ni Ánà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nígbà tó rí Jésù?
19 Bàbá arúgbó kan tó ń jẹ́ Síméónì lọ bá wọn, ó sì sọ àwọn ohun mìíràn tí Màríà ní láti pa mọ́ sínú ọkàn rẹ̀. Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Síméónì pé ó máa rí Mèsáyà náà kó tó kú, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà sì jẹ́ kó mọ̀ pé Jésù, tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́ nígbà yẹn, ni Olùgbàlà tí wọ́n ń retí. Síméónì tún sọ fún Màríà nípa ìrora tó máa fara dà lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ pé ńṣe ló máa dà bíi pé wọ́n fi idà gígùn gún Màríà ní àgúnyọ. (Lúùkù 2:25-35) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ yìí ló ran Màríà lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí ìṣòro ọ̀hún dé ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] lẹ́yìn ìgbà náà. Yàtọ̀ sí Síméónì, wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Ánà rí Jésù tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún gbogbo àwọn tó ń retí ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.—Ka Lúùkù 2:36-38.
20. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé Màríà àti Jósẹ́fù gbé Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù?
20 Bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe pinnu láti gbé ọmọ wọn lọ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù yẹn mà dára gan-an ni o! Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹsẹ̀ ọmọ náà lé ọ̀nà tí yóò máa tọ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn wíwá sí tẹ́ńpìlì Jèhófà déédéé. Nígbà tí wọ́n wà ní tẹ́ńpìlì, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, wọ́n sì gbọ́ ìtọ́ni àti àwọn ọ̀rọ̀ tó fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ Màríà ti lágbára sí i kó tó kúrò nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó lè ṣàṣàrò lé lórí, tó sì lè fi kọ́ àwọn èèyàn sì kún inú ọkàn rẹ̀.
21. Kí la lè ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ máa lágbára bíi ti Màríà?
21 Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá rí àwọn òbí tó ń ṣe bíi ti Màríà lónìí. Àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń mú àwọn ọmọ wọn wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ máa ń fún àwọn míì ní ohun tí wọ́n bá ní, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ tó lè gbé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró. Nígbà tí wọ́n bá sì fi máa kúrò ní ìpàdé, ìgbàgbọ́ wọn á ti lágbára sí i, ayọ̀ wọn á ti pọ̀ sí i, wọ́n á sì ti ní ọ̀pọ̀ ohun rere láti sọ fún àwọn míì. Ó máa ń dùn mọ́ni láti wà pẹ̀lú irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń wà pẹ̀lú wọn, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ máa lágbára bíi ti Màríà.
^ ìpínrọ̀ 7 Kíyè sí i pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìn àjò yìí yàtọ̀ sí ohun tó sọ nípa èyí tí Màríà lọ tẹ́lẹ̀. Ní ti ìyẹn, Bíbélì sọ pé: “Màríà dìde . . . ó sì lọ” ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì. (Lúùkù 1:39) Màríà àti Jósẹ́fù ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà nígbà yẹn, àmọ́ wọn ò tíì ṣègbéyàwó, torí náà Màríà lè má sọ fún Jósẹ́fù kó tó lọ. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, Jósẹ́fù ló sọ pé ìrìn àjò yá, kì í ṣe Màríà.
^ ìpínrọ̀ 10 Àṣà ìgbà yẹn ni pé kí ìlú kọ̀ọ̀kan ní ilé táwọn arìnrìn-àjò àtàwọn oníṣòwò tó ń kọjá lọ á máa dé sí.
^ ìpínrọ̀ 14 Bó ṣe jẹ́ pé ìta làwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń tọ́jú àgbo ẹran wọn ní àkókò yìí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Bíbélì sọ nípa ìgbà tí wọ́n bí Jésù. Oṣù December kọ́ ni wọ́n bí Kristi torí tòsí ilé ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti máa ń tọ́jú agbo ẹran wọn lásìkò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ni wọ́n bí i.