Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?

Oríṣi ìsìn méjì péré ló wà: ọ̀kan ń sinni lọ sí ìyè, èkejì sì ń sinni lọ sí ìparun. Ìwé yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọlọ́run Olódùmarè ló lè jẹ́ ká wà láàyè ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ìjọsìn wa tẹ́ ẹ lọ́rùn!

APÁ 1

Ǹjẹ́ Gbogbo Ìsìn Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ni?

Oríṣiríṣi nǹkan tó yàtọ̀ síra ni àwọn ẹlẹ́sìn gbà gbọ́. Ṣé gbogbo rẹ̀ lè jẹ́ òótọ́?

APÁ 2

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọlọ́run?

Ṣé ó ní ohun kan tí gbogbo èèyàn á jọ gbà, tí wọ́n máa gbé ẹ̀kọ́ òtítọ́ kà?

APÁ 3

Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ibùgbé Àwọn Ẹni Ẹ̀mí?

Ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn àbáláyé nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń ní ipa tó lágbára lórí àwọn èèyàn. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni àwọn ìgbàgbọ́ yìí? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí.

APÁ 4

Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé ṣe ni ẹni tó bá kú ṣípò pa dà sí ibòmíì, kì í ṣe pé ó ti kú pátápátá. Kí ni Bíbélì sọ?

APÁ 5

Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn

Àwọn ẹ̀mí èṣù lágbára, wọ́n sì burú, àmọ́ ìyẹn ò ní ká máa bẹ̀rù wọn ju bó ṣe yẹ lọ.

APÁ 6

Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Àwọn kan rò pé gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ṣé ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn lóòótọ́?

APÁ 7

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìsìn Tòótọ́?

Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dá àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run mọ̀.

APÁ 8

Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́

Jésù sọ pé: “Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi.” Báwo lo ṣe lè fi ẹ̀yìn ẹni tó o wà hàn?

APÁ  9

Ìsìn Tòótọ́ Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní Títí Láé!

Tó o bá ń sin Jèhófà, ó máa bù kún ẹ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú