Ẹ̀kọ́ 16
Fi Ìfẹ́ Tó O Ní sí Ọlọ́run Hàn
Kí ọ̀rẹ́ ìwọ àti ẹnì kan tó lè wọ̀, o gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀. Wàá máa fetí sí i, òun náà á sì máa fetí sí ọ. Wàá tún máa sọ ọ̀rọ̀ tó dáa nípa ọ̀rẹ́ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí bí o bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Gbé ohun ti Bíbélì sọ nípa èyí yẹ̀ wò:
Máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé nínú àdúrà. “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.”—Róòmù 12:12.
Máa Ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.
Máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.
Máa lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.”—Hébérù 10:24, 25.
Kóo ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà. “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.