Ẹ̀kọ́ 15
Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run A Máa Ṣe Rere
Bóo ba ní ọ̀rẹ́ kan, tóo gba tiẹ̀, tóo sì bọ̀wọ̀ fún, wàá gbìyànjú láti dà bíi rẹ̀. Bíbélì wí pé: “Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà.” (Sáàmù 25:8) Láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni rere àti adúróṣánṣán. Bíbélì wí pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ.” (Éfésù 5:1, 2) Àwọn ọ̀nà díẹ̀ nìyí tí a lè gbà ṣe ìyẹn:
Máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”—Gálátíà 6:10.
Máa ṣiṣẹ́ kára. “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.”—Éfésù 4:28.
Jẹ́ mímọ́ nípa ti ara àti nínú ìwà híhù. “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.
Máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn. “Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.”—1 Jòhánù 4:7.
Máa ṣègbọ́ràn sí àwọn òfin orílẹ̀-èdè. “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ [ìjọba] . . . Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí.”—Róòmù 13:1, 7.