APÁ 2
“Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”
Ìwà ìrẹ́jẹ wọ́pọ̀ gan-an láyé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé Ọlọ́run ló fà á. Síbẹ̀, Bíbélì kọ́ wa ní òótọ́ kan tó fini lọ́kàn balẹ̀. Òótọ́ náà ni pé “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 37:28) Nínú apá yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo lóòótọ́ àti pé òun máa mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò títí láé.
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 11
“Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
Kí nìdí tí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run fi mú kó wù wá láti sún mọ́ ọn?
ORÍ 12
“Ṣé Ọlọ́run Jẹ́ Aláìṣòdodo Ni?”
Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jèhófà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, kí nìdí tí ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ láyé lónìí?
ORÍ 14
Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”
Ẹ̀kọ́ tó rọrùn tó sì bọ́gbọ́n mu táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
ORÍ 15
Jésù “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”
Àwọn nǹkan wo ni Jésù ti ṣe láti fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀? Àwọn nǹkan wo ló ń ṣe ní báyìí? Báwo ló sì ṣe máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
ORÍ 16
Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rìn
Ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo kan ojú tá a fi ń wo ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ó tún kan bá a ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn.