APÁ 4
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
Nínú gbogbo ìwà àti ìṣe Jèhófà, ìfẹ́ ṣàrà ọ̀tọ̀, òun ló sì fani mọ́ra jù lọ. Nínú apá yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ànímọ́ tó ṣeyebíye yìí, àá wá rí ìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 24
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
Sátánì máa ń parọ́ pé a ò wúlò àti pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa, àmọ́ má ṣe gba irọ́ yìí gbọ́ rárá.
ORÍ 25
“Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
Tá a ba ronú nípa bí ọ̀rọ̀ ọmọ kan ṣe rí lára ìyá ẹ̀, báwo ló ṣe jọra pẹ̀lú bọ́rọ̀ wa ṣe rí lára Ọlọ́run?
ORÍ 26
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
Nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni pípé tí kì í gbàgbé nǹkan, báwo ló ṣe wá jẹ́ pé tó bá ti dárí jini, kì í rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́?
ORÍ 28
“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ adúróṣinṣin ṣe pàtàkì ju bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ tàbí ẹni tó ṣeé gbára lé?
ORÍ 29
Kí Ẹ Lè “Mọ Ìfẹ́ Kristi”
Tá a bá ronú nípa ọ̀nà mẹ́ta tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn, àá rí i pé ó fara wé ìfẹ́ Jèhófà lọ́nà tó pé.