Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 17

“Ọgbọ́n . . . Ọlọ́run Mà Jinlẹ̀ O!”

“Ọgbọ́n . . . Ọlọ́run Mà Jinlẹ̀ O!”

1, 2. Kí ni Jèhófà fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ keje, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ keje yìí?

 NÍGBÀ tí ọjọ́ kẹfà ń parí lọ, lẹ́yìn tí Jèhófà Ọlọ́run ti dá èèyàn, “Ọlọ́run rí gbogbo ohun tó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Àmọ́, níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ keje, Ádámù àti Éfà yàn láti tẹ́tí sí Sátánì, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Torí náà, èèyàn tó jẹ́ ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ lára ohun tí Jèhófà dá sáyé dẹ́ṣẹ̀, wọ́n di aláìpé, wọ́n sì ń kú. Ó mà ṣe o!

2 Ó lè wá dà bíi pé gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje ò ní ṣẹlẹ̀ láé! Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni ọjọ́ keje yìí máa jẹ́ bíi ti ọjọ́ mẹ́fà tó ṣáájú. Jèhófà ti yà á sí mímọ́, tó bá sì fi máa parí, gbogbo ayé á ti di Párádísè, àwọn èèyàn pípé láá sì máa gbébẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:3) Ṣùgbọ́n ní báyìí tí Sátánì pẹ̀lú Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ṣáwọn nǹkan yìí ṣì máa ṣeé ṣe? Kí ni Jèhófà máa ṣe sọ́rọ̀ yìí? Báwo ló ṣe máa fi ọgbọ́n ẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ yìí? Ẹ ò rí i pé àdánwò ńlá lèyí!

3, 4. (a) Kí ni ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tí wàhálà ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì jẹ́ ká mọ̀ nípa ọgbọ́n rẹ̀? (b) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n Jèhófà?

3 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà ti mọ ohun tóun máa ṣe. Ó dá àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn lẹ́jọ́ ní Édẹ́nì, ó sì tún sọ ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé òun máa yanjú gbogbo wàhálà tí wọ́n dá sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ńṣe ni Jèhófà máa yanjú ìṣòro yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ó sì máa tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún kí ìṣòro tí ìwà ọ̀tẹ̀ yẹn dá sílẹ̀ tó yanjú pátápátá. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà yanjú ìṣòro yìí kò lọ́jú pọ̀ rárá, síbẹ̀ ó jọni lójú ó sì mọ́gbọ́n dání débi pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ń fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń ṣàṣàrò nípa ẹ̀, á ṣì máa jọ ọ́ lójú. Bákan náà, ó dájú pé ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ gbà yanjú ìṣòro yìí máa yọrí sí rere. Ó máa fòpin sí gbogbo ìwà ibi, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ó tún máa sọ àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ di pípé. Gbogbo nǹkan yìí ló máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí ọjọ́ keje tó parí, èyí jẹ́ ká rí i pé láìka gbogbo ohun tí Sátánì ṣe sí, gbogbo nǹkan tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe sí ayé àti fún àwa èèyàn ló máa ṣe lásìkò tó yẹ gẹ́lẹ́!

4 Ọgbọ́n Ọlọ́run yìí mà yani lẹ́nu gan-an o! Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: ‘Ọgbọ́n Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o!’ (Róòmù 11:33) Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ọgbọ́n Jèhófà, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé bíńtín báyìí la lè mọ̀ nínú ọgbọ́n Jèhófà tí kò lópin. (Jóòbù 26:14) Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ànímọ́ àgbàyanu yìí túmọ̀ sí.

Kí Ni Ọgbọ́n Ọlọ́run?

5, 6. Kí nìdí tẹ́nì kan fi gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ kó tó lè jẹ́ ọlọ́gbọ́n? Báwo ni ohun tí Jèhófà mọ̀ ṣe pọ̀ tó?

5 Ọgbọ́n àti ìmọ̀ kì í ṣe ohun kan náà. Ọ̀pọ̀ ìsọfúnni la lè fi pa mọ́ sórí kọ̀ǹpútà, àmọ́ a ò lè sọ pé kọ̀ǹpútà jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ṣùgbọ́n, kò sí béèyàn ṣe lè jẹ́ ọlọ́gbọ́n láìní ìmọ̀. (Òwe 10:14) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ò ń ṣàìsàn tó le gan-an tó o sì ń wá ẹni tó máa gbà ẹ́ nímọ̀ràn ọlọgbọ́n nípa ohun tó o lè ṣe kára ẹ lè yá, ṣé ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìṣègùn lo máa lọ bá? Rárá o! Torí náà, ká tó lè sọ pé ẹnì kan gbọ́n lóòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé kó ní ìmọ̀ tó péye.

6 Kò sóhun tí Jèhófà ò mọ̀. Torí pé “Ọba ayérayé” ni, òun nìkan ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀. (Ìfihàn 15:3) Gbogbo ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti àìmọye ọdún sẹ́yìn ló mọ̀ pátá. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ìṣẹ̀dá kankan tó fara pa mọ́ ní ojú rẹ̀, àmọ́ ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.” (Hébérù 4:13; Òwe 15:3) Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, gbogbo ohun tó dá ló mọ̀ dáadáa, gbogbo ohun táwọn èèyàn sì ń ṣe látìgbà tó ti dá wọn kò pa mọ́ lójú ẹ̀. Ó mọ gbogbo ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa èèyàn ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. (1 Kíróníkà 28:9) Torí pé Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè ṣe ìpinnu tó wù wá, inú ẹ̀ máa ń dùn gan-an tá a bá ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ohun míì tún ni pé òun ni “Olùgbọ́ àdúrà,” àìmọye ọ̀rọ̀ ló ń gbọ́ lẹ́ẹ̀kan náà! (Sáàmù 65:2) Agbára ìrántí Jèhófà yìí mà kàmàmà o!

7, 8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi òye, ìfòyemọ̀ àti ọgbọ́n hàn?

7 Ìmọ̀ nìkan kọ́ ni Jèhófà ní o, ó tún máa ń rí bí àwọn ọ̀rọ̀ ṣe so mọ́ra, á sì fòye mọ ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀, bó ti wù kí ọ̀rọ̀ náà lọ́jú pọ̀ tó. Ó máa ń fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa, ohun tó ṣe pàtàkì àti ohun tí kò ṣe pàtàkì. Bákan náà, ohun tó wà lọ́kàn wa ló máa ń wò, kì í ṣe bá a ṣe rí. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Torí náà, Jèhófà ní òye àti ìfòyemọ̀, èyí sì ju ìmọ̀ lọ. Àmọ́, ọgbọ́n ju gbogbo wọn lọ.

8 Ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ ọlọ́gbọ́n, á kọ́kọ́ ṣèwádìí nípa nǹkan, á rí i pé ó yé òun dáadáa, á sì lo ìmọ̀ àti òye tó ní yẹn láti ṣe ohun tó dáa. Kódà àwọn ọ̀rọ̀ kan tá a túmọ̀ sí “ọgbọ́n” látinú èdè tá a fi kọ Bíbélì ní tààràtà túmọ̀ sí “ohun tó ń ṣàṣeyọrí” tàbí “ọgbọ́n tó wúlò.” Nítorí náà, ọgbọ́n Jèhófà kì í ṣe bíi tẹni tó ń fẹnu ròfọ́ lásán. Ọgbọ́n tó ń ṣe àṣeyọrí tó sì wúlò ni. Jèhófà mọ ohun gbogbo, òye rẹ̀ ò sì lẹ́gbẹ́, torí náà ìpinnu tó dáa jù lọ ló máa ń ṣe, ọ̀nà tó sì dáa jù lọ ló máa ń gbà ṣe nǹkan. Ìyẹn gangan ni ọgbọ́n tòótọ́! Ohun tí Jèhófà ṣe bá ohun tí Jésù sọ mu gẹ́lẹ́, ó sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Àwọn ohun tí Jèhófà dá jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé ọlọ́gbọ́n ni.

Àwọn Ẹ̀rí Tó Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Hàn

9, 10. (a) Báwo ni ọgbọ́n Jèhófà ṣe pọ̀ tó, báwo ló sì ṣe fi ọgbọ́n náà hàn? (b) Báwo ni ohun bíńtín tó para pọ̀ di ara èèyàn ṣe jẹ́rìí sí ọgbọ́n Jèhófà?

9 Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá rí oníṣẹ́ ọnà kan tó fi ọgbọ́n ṣe ohun kan tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa tó sì wúlò? Ó dájú pé ó máa jọ ẹ́ lójú gan-an! (Ẹ́kísódù 31:1-3) Jèhófà ló gbọ́n jù láyé àtọ̀run, òun ló sì ń fún àwọn èèyàn ní ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣe àwọn ohun tó jọni lójú. Ọba Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Mo yìn ọ́ nítorí pé lọ́nà tó ń bani lẹ́rù ni o ṣẹ̀dá mi tìyanutìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, mo mọ èyí dáadáa.” (Sáàmù 139:14) Ká sòótọ́, bá a bá ṣe ń mọ̀ sí i nípa ara àwa èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n Jèhófà á ṣe máa jẹ́ àgbàyanu tó lójú wa.

10 Jẹ́ ká wo àpèjúwe kan: Ohun bíńtín kan báyìí tí wọ́n ń pè ní sẹ́ẹ̀lì, ìyẹn ẹyin kan láti ara obìnrin ló ń pàdé pẹ̀lú àtọ̀ ọkùnrin, tí obìnrin fi ń lóyún. Láìpẹ́, sẹ́ẹ̀lì yẹn á bẹ̀rẹ̀ sí í pín sí ọ̀nà púpọ̀. Nígbà tó bá fi máa di ọmọ, á ti pín sọ́nà tírílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún! Tín-tìn-tín báyìí ni àwọn sẹ́ẹ̀lì náà. Tá a bá kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá wọn jọ, kò lè ju orí abẹ́rẹ́ lásán lọ. Síbẹ̀, ohun àrà ló wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ohun tó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ju ti ẹ̀rọ tàbí ilé iṣẹ́ èyíkéyìí táwọn èèyàn ṣe lọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ńṣe ni sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan yìí dà bí ìlú kan tí wọ́n mọ ògiri yí ká, tó ní ọ̀nà àbáwọlé àti ọ̀nà àbájáde tí wọ́n ń ṣí, tí wọ́n sì ń tì, tó ní àwọn ọkọ̀ akẹ́rù, ètò ìbánisọ̀rọ̀, iná mànàmáná, ilé iṣẹ́ tó ń pèsè ohun èlò, ohun tó ń palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ àtèyí tó ń ṣe àlòtúnlò nǹkan, ó láwọn ẹ̀ṣọ́, ó tiẹ̀ tún ní ohun tó dà bí ètò ìjọba láàárín ẹ̀. Bákan náà, ohun bíńtín kọ̀ọ̀kan lè ṣe ẹ̀dà ara ẹ̀ gẹ́lẹ́ láàárín wákàtí mélòó kan!

11, 12. (a) Ibo ni ìlànà nípa báwọn sẹ́ẹ̀lì ṣe ń pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ wà, báwo lèyí sì ṣe bá ohun tó wà ní Sáàmù 139:16 mu? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni ọpọlọ èèyàn gbà fi hàn pé Jèhófà ‘ṣẹ̀dá wa tìyanutìyanu’?

11 Àwọn sẹ́ẹ̀lì tá à ń sọ yìí yàtọ̀ síra ṣá o. Bí ọmọ ṣe ń dàgbà nínú ìyá ẹ̀, ọ̀pọ̀ sẹ́ẹ̀lì ló máa ń jáde látara sẹ́ẹ̀lì àkọ́kọ́ yẹn. Àwọn kan á di sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ; àwọn míì á di egungun, iṣan, ẹ̀jẹ̀, tàbí ojú. Gbogbo ìlànà bí wọ́n ṣe máa pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti wà ní sẹpẹ́ nínú ibì kan tó dà bí ibi ìkówèésí tí wọ́n ń pè ní DNA. Ó gbàfiyèsí pé ẹ̀mí mímọ́ darí Dáfídì láti sọ fún Jèhófà pé: “Ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn; gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ.”​—Sáàmù 139:16.

12 Iṣẹ́ tó ń lọ nínú àwọn ẹ̀yà ara kan kì í ṣe kékeré. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọpọlọ àwa èèyàn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé nínú gbogbo nǹkan tó wà láyé yìí, ọpọlọ ló jọni lójú jù. Nǹkan bíi bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún sẹ́ẹ̀lì ló wà nínú ọpọlọ wa, ìyẹn á sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tí ayé yìí wà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ló sì so mọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sẹ́ẹ̀lì míì. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tiẹ̀ sọ pé ọpọlọ èèyàn lè gba gbogbo ìsọfúnni tó wà nínú gbogbo ìwé tó wà níbi ìkówèésí tó wà láyé yìí pátá àti pé bóyá ni àyè tí ọpọlọ ní ṣeé díwọ̀n. Pẹ̀lú gbogbo ọdún táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣèwádìí lórí ẹ̀yà ara tí Jèhófà ‘ṣẹ̀dá tìyanutìyanu’ yìí, wọ́n ṣì gbà pé àwọn ò lè mọ gbogbo nǹkan nípa bó ṣe ń ṣiṣẹ́.

13, 14. (a) Báwo làwọn èèrà àtàwọn ẹ̀dá míì ṣe fi hàn pé wọ́n ní “ọgbọ́n àdámọ́ni,” kí nìyẹn sì kọ́ wa nípa Ẹlẹ́dàá wọn? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ńṣe ni Jèhófà “fi ọgbọ́n ṣe” aláǹtakùn?

13 Àmọ́, àpẹẹrẹ kan ṣoṣo làwa èèyàn jẹ́ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà fi ọgbọ́n rẹ̀ ṣe. Sáàmù 104:24 sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe. Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.” Ọgbọ́n Jèhófà hàn kedere nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tó yí wa ká. Bí àpẹẹrẹ, èèrà ní “ọgbọ́n àdámọ́ni.” (Òwe 30:24) Bí àwọn èèrà ṣe ń ṣètò ara wọn jọni lójú gan-an. Àwọn èèrà kan máa ń sin kòkòrò kan bí ẹní sin ẹran ọ̀sìn. Wọ́n á ṣe ilé fún un, wọ́n á máa bọ́ ọ, wọ́n á sì máa fa oúnjẹ aṣaralóore lára ẹ̀. Àwọn èèrà míì máa ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, wọ́n máa ń gbin olú, kí wọ́n lè rí oúnjẹ jẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dá míì tún wà tí wọ́n ní ọgbọ́n àdámọ́ni tí wọ́n fi ń dárà. Kò sí ọkọ̀ òfúrufú tó lè dá irú àrà tí eṣinṣin máa ń dá tó bá ń fò. Àwọn ẹyẹ tó ń ṣí kiri máa ń fi ibi táwọn ìràwọ̀ kan wà mọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà, wọ́n máa ń lo ìlànà agbára òòfà ayé, tàbí kí wọ́n lo ohun kan tó dà bí afinimọ̀nà tó wà nínú ara wọn. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè fi máa ń ṣèwádìí nípa àwọn ohun tó jọni lójú táwọn ẹ̀dá yìí máa ń ṣe. Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan yẹn mọ́ wọn. Ẹ ò rí i pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé!

14 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti kẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ gan-an látara àwọn ohun tí Jèhófà fi ọgbọ́n rẹ̀ dá. Kódà, ẹ̀ka kan wà nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n ń pè ní biomimetics tí wọ́n ti máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, tí wọ́n á sì fi ohun tí wọ́n rí kọ́ ṣe oríṣiríṣi nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá rí bí okùn aláǹtakùn ṣe rẹwà tó. Àmọ́ ní táwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, bí okùn náà ṣe lágbára tó ló máa ń jọ wọ́n lójú. Ó lè jọ ohun tó fẹ́lẹ́ lójú, àmọ́ ó lágbára ju irin lọ. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká sọ pé wọ́n sọ okùn aláǹtakùn di títóbi débi tó fi nípọn tó sì fẹ̀ tó àwọ̀n tí wọ́n fi ń pẹja. Tí wọ́n bá ta á dínà ọkọ̀ òfúrufú ńlá tó ń fò lọ, ó máa dá ọkọ̀ òfúrufú náà dúró bí okùn aláǹtakùn ṣe máa ń mú eṣinṣin tàbí ẹ̀fọn! Dájúdájú, ńṣe ni Jèhófà “fi ọgbọ́n ṣe” àwọn nǹkan yìí lóòótọ́.

Ta ló dá “ọgbọ́n àdámọ́ni” mọ́ àwọn ẹranko?

Àwọn Nǹkan Tó Wà Lọ́run Ń Fi Ọgbọ́n Rẹ̀ Hàn

15, 16. (a) Báwo làwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run ṣe jẹ́rìí sí i pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà? (b) Tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń darí ọ̀kẹ́ àìmọye awọn áńgẹ́lì, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n rẹ̀ pọ̀ gan-an?

15 Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá sí ọ̀run tún ń fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn. Ní Orí 5, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ti ṣe “òfin tó ń darí ojú ọ̀run,” a sì rí i pé òfin náà ló mú káwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run wà létòlétò. (Jóòbù 38:33) Abájọ tí Jèhófà fi pe àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yìí ní “ẹgbẹ́ ọmọ ogun”! (Àìsáyà 40:26) Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tún wà, tó túbọ̀ fi ọgbọ́n Jèhófà hàn kedere ju àwọn ìràwọ̀ lọ.

16 Bá a ṣe sọ ní Orí 4, a máa ń pe Ọlọ́run ní orúkọ oyè náà “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” torí pé òun ló ń darí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogun ọ̀run. Èyí jẹ́ ká rí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Báwo nìyẹn tún ṣe jẹ́rìí sí i pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà? Rò ó wò ná: Gbogbo ìgbà ni Jèhófà àti Jésù máa ń ṣiṣẹ́. (Jòhánù 5:17) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jèhófà Ọlọ́run máa fún àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn tí wọ́n á máa ṣe. Ẹ rántí pé ipò àwọn áńgẹ́lì yìí ga ju táwa èèyàn lọ, òye àti agbára wọn sì pọ̀ gan-an. (Hébérù 1:7; 2:7) Síbẹ̀, láti àìmọye bílíọ̀nù ọdún tí wọ́n ti ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi “ń ṣe ohun tó sọ” tí wọ́n sì “ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 103:20, 21) Ẹ ò rí i pé ọgbọ́n Jèhófà tó jẹ́ Alákòóso wọn pọ̀ gan-an!

Jèhófà Ni “Ẹnì Kan Ṣoṣo Tí Ó Gbọ́n”

17, 18. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,” kí la sì rí kọ́ nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ọgbọ́n Jèhófà?

17 Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí yìí, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí Bíbélì ṣe fi hàn pé ọgbọ́n Jèhófà ló ga jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” (Róòmù 16:27) Ká sòótọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ló gbọ́n láìkù síbì kan. Òun ni orísun ọgbọ́n tòótọ́. (Òwe 2:6) Jésù ò gbára lé ọgbọ́n ara ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ló gbọ́n jù lọ nínú gbogbo ẹ̀dá Jèhófà. Èrò ara ẹ̀ kọ́ ló máa ń sọ fáwọn èèyàn, ohun tí Bàbá ẹ̀ kọ́ ọ ló máa ń sọ.​—Jòhánù 12:48-50.

18 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ronú nípa ọgbọ́n Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sọ pé: “Ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o! Ẹ wo bí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámáridìí tó, tí àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì kọjá àwárí!” (Róòmù 11:33) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé ọgbọ́n Jèhófà jọ ọ́ lójú gan-an ni, kódà ẹ̀rù Ọlọ́run bà á gidigidi. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò fún ọ̀rọ̀ náà “jinlẹ̀” lè túmọ̀ sí “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí gbé àwòrán kan sí wa lọ́kàn. Ìyẹn ni pé tá a bá ń ronú nípa ọgbọ́n Jèhófà, ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń yọjú wo ọ̀gbun tí kò nísàlẹ̀. Kò sí báwa èèyàn ṣe lè gbìyànjú tó, a ò lè lóye bí ọgbọ́n Jèhófà ṣe pọ̀ tó, a ò sì lè mọ gbogbo ohun tí Jèhófà mọ̀. (Sáàmù 92:5) Ẹ ò rí i pé bíńtín ni ọgbọ́n àwa èèyàn tá a bá fi wéra pẹ̀lú ọgbọ́n Jèhófà!

19, 20. (a) Kí nìdí tó fi bá a mu pé ẹyẹ idì ni Jèhófà fi ṣàpèjúwe ọgbọ́n ẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?

19 Ohun míì tún wà tó fi hàn pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,” ohun náà ni pé òun nìkan ṣoṣo ló lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Rántí pé ẹyẹ idì tó ń ríran jìnnà ni Jèhófà fi ṣàpèjúwe ọgbọ́n rẹ̀. Ẹyẹ idì aláwọ̀ wúrà lè má wọ̀n ju kìlógíráàmù márùn-ún lọ, àmọ́ ojú rẹ̀ tóbi ju ti àgbàlagbà ọkùnrin lọ. Ojú ẹyẹ idì ríran kedere débi pé tó bá ń fò lójú ọ̀run, ó lè rí ohun kékeré kan tó fẹ́ pa jẹ láti ọ̀nà tó jìn gan-an! Nígbà kan tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ẹyẹ idì, ó sọ pé: “Ojú rẹ̀ ń ríran jìnnà réré.” (Jóòbù 39:29) Bákan náà, ojú Jèhófà máa ń “ríran jìnnà réré,” ó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la!

20 Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Lára àwọn àkọsílẹ̀ yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ìtàn tó ti wà lákọsílẹ̀ kí wọ́n tiẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ rárá. Ó lè jẹ́ ẹni tó máa borí nínú àwọn ogun kan, bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agbára ayé ṣe máa gbàjọba àti bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun wọn, títí kan ọgbọ́n táwọn ọ̀gágun máa lò lójú ogun. Kódà, àwọn kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Jèhófà ti sọ̀rọ̀ nípa wọn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀.​—Àìsáyà 44:25–45:4; Dáníẹ́lì 8:2-8, 20-22.

21, 22. (a) Kí nìdí tá ò fi lè sọ pé gbogbo ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe láyé ẹ̀ ni Ọlọ́run ti rí? Sọ àpèjúwe kan. (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ lo ọgbọ́n ẹ̀?

21 Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe láyé ẹ̀ ni Ọlọ́run ti rí? Àwọn tó gbà gbọ́ nínú àyànmọ́ gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Àmọ́, ńṣe ni èrò yẹn ń bu ọgbọ́n Jèhófà kù, torí ó ń fi hàn pé kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu tó bá kan bó ṣe ń lo agbára ẹ̀ láti rí ọjọ́ ọ̀la. Àpèjúwe kan rèé: Tó bá jẹ́ pé ohùn ẹ dùn gan-an, ṣó wá túmọ̀ sí pé dandan ni kó o máa kọrin ní gbogbo ìgbà? Ìyẹn ò ní bọ́gbọ́n mu! Bákan náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lágbára láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló máa ń lo agbára yìí, ìyẹn ò ní jẹ́ ká lè lo ẹ̀bùn òmìnira tó fún wa láti yan ohun tó wù wá, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ò ní gba ẹ̀bùn iyebíye yìí lọ́wọ́ wa láéláé.​—Diutarónómì 30:19, 20.

22 Èyí tó tiẹ̀ burú jù ni pé, ńṣe làwọn tó nígbàgbọ́ nínú àyànmọ́ máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi fún gbogbo nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n sì gbà pé bí Jèhófà ṣe ń lo ọgbọ́n ẹ̀ ò fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́, irọ́ gbáà nìyẹn! Bíbélì kọ́ wa pé Jèhófà “jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Torí náà, bíi tàwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà tó kù, ìfẹ́ ni Jèhófà fi ń lo ọgbọ́n ẹ̀.

23. Tá a bá gbà pé Jèhófà gbọ́n jù wá lọ, kí ló yẹ ká ṣe?

23 Ó hàn kedere pé a lè gbára lé ọgbọ́n Jèhófà pátápátá. Ó gbọ́n jù wá lọ gan-an. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fìfẹ́ rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Ẹ jẹ́ ká wá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ọgbọ́n Jèhófà, ká bàa lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa tó jẹ́ orísun ọgbọ́n.