ORÍ 14
“Àwọn Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Tọ̀ Ọ́ Wá”
1-3. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn òbí kan mú àwọn ọmọ wọn wá wo Jésù, kí lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sì jẹ́ ká mọ̀ nípa Jésù?
JÉSÙ mọ̀ pé òpin ìgbésí ayé òun lórí ilẹ̀ ayé ti dé tán. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré ló kù, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì kù tóun gbọ́dọ̀ ṣe! Ẹnu iṣẹ́ ìwàásù lòun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wà nílùú kan tó ń jẹ́ Pèríà, èyí tó wà ní apá ọ̀tún Odò Jọ́dánì. Apá ìsàlẹ̀ ni wọ́n forí lé bí wọ́n ṣe ń wàásù bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní ibi tí Jésù ti máa ṣe Àjọ Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn, Ìrékọjá ti ọ̀tẹ̀ yìí sì ṣe pàtàkì fún un gan-an ni.
2 Lẹ́yìn ìjíròrò tó rinlẹ̀ tí Jésù ní pẹ̀lú àwọn aṣáájú ìsìn kan, ohun kékeré kan dí i lọ́wọ́. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọmọ wọn wá wò ó. Ó ṣe kedere pé ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà yàtọ̀ síra, torí ọ̀rọ̀ tí Máàkù fi júwe ọmọ ọdún méjìlá kan báyìí ló fi júwe wọn, àmọ́ Lúùkù ní tiẹ̀ lo ọ̀rọ̀ tó ṣeé tú sí “ìkókó.” (Lúùkù 18:15; Máàkù 5:41, 42; 10:13) Kò kúkú síbi táwọn ọmọdé bá wà tí wọn ò ní máa ṣeréepá tàbí kí wọ́n máa pariwo kí ibẹ̀ sì máa hó yèè. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wá bá àwọn òbí àwọn ọmọ náà wí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí tí wọ́n rò pé ọwọ́ Ọ̀gá àwọn ti dí ju pe káwọn ọmọ kan tún ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa dààmù rẹ̀ lọ. Kí ni Jésù wá ṣe?
3 Nígbà tí Jésù rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú bí i. Ta ló bínú sí? Ṣé àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn ni? Àbí àwọn òbí wọn? Rárá o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gan-an ló bínú sí! Ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnì yòówù tí kò bá gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò wọ inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.” Lẹ́yìn náà, Jésù gbé àwọn ọmọ náà “sí apá rẹ̀,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún wọn. (Máàkù 10:13-16) Gbólóhùn tí Máàkù lò níbí yìí jẹ́ ká mọ̀ pé tìfẹ́tìfẹ́ ni Jésù fi gbá wọn mọ́ra, àfàìmọ̀ kó má jẹ́ pé ṣe ló gbé àwọn tó jẹ́ ìkókó lára wọn “sí apá rẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè kan ṣe ṣàlàyé rẹ̀. Ó hàn gbangba pé Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọdé. Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ míì nípa Jésù, ìyẹn ni pé Jésù ṣeé sún mọ́.
4, 5. (a) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni Jésù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?
4 Bí Jésù bá jẹ́ òṣónú tàbí agbéraga, bóyá làwọn ọmọdé yẹn ì bá fẹ́ láti sún mọ́ ọn; ì bá sì má rọrùn fáwọn òbí wọn láti sún mọ́ ọn. Bó o ṣe ń fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ṣé o ò máa rí i pé ṣe ni inú àwọn òbí yẹn á máa dùn ṣìnkìn bí ọ̀gbẹ́ni tí ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn yìí ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn ṣeré, tó sì ń fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọdé àti pé ó kà wọ́n sì pàtàkì? Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá tó tóbi jù lọ ló wà lọ́rùn Jésù nígbà yẹn, síbẹ̀, òun ni ẹni tó ṣeé sún mọ́ jù lọ.
5 Ta ló tún mọ Jésù sẹ́ni tó ṣeé sún mọ́? Kí ló mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ Jésù? Báwo la sì ṣe lè kọ́ bá a ṣe lè jẹ́ kí ara wa yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn bíi ti Jésù? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.
Àwọn Wo Ló Rí Jésù bí Ẹni Tó Ṣeé Sún Mọ́?
6-8. Àárín àwọn wo ni Jésù sábà máa ń wà, ọ̀nà wo ni ìwà tiẹ̀ sì gbà yàtọ̀ sí tàwọn aṣáájú ìsìn?
6 Bó o bá ṣe ń ka àkọsílẹ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere, ẹnu lè yà ọ́ sí bí ogunlọ́gọ̀ èèyàn ò ṣe lọ́ra láti tọ Jésù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kà nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wà pẹ̀lú rẹ̀. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀ lé e láti Gálílì.” “Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” “Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tọ̀ ọ́ wá.” “Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń bá a rin ìrìn àjò.” (Mátíù 4:25; 13:2; 15:30; Lúùkù 14:25) Bó ṣe rí nìyẹn o, àìmọye èèyàn ló sábà máa ń yí Jésù ká.
7 Mẹ̀kúnnù ló pọ̀ jù nínú àwọn wọ̀nyí, àwọn aṣáájú ìsìn sì kórìíra wọn débi pé “àwọn ènìyàn ilẹ̀” ni wọ́n máa ń pè wọ́n. Gbangba gbàǹgbà làwọn Farisí àtàwọn àlùfáà sọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Ìwé táwọn rábì kọ lẹ́yìn ìgbà yẹn jẹ́rìí sí i pé lóòótọ́ làwọn Farisí àtàwọn àlùfáà nírú ìwà bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ló ka àwọn èèyàn náà sí aláìníláárí, wọn kì í bá wọn jẹun, wọn kì í rajà lọ́wọ́ wọn, wọn kì í sì í bá wọn da nǹkan pọ̀. Kódà, àwọn kan lára àwọn olórí ìsìn yẹn gbà pé irú àwọn èèyàn aláìníláárí yẹn ò lè ní àjíǹde torí wọn ò mọ òfin àtẹnudẹ́nu àwọn Júù! Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tí kò rọ́wọ́ mú yẹn ni ò ní lè sún mọ́ àwọn aṣáájú ìsìn, bèlètàsè kí wọ́n ní kí wọ́n tọ́ àwọn sọ́nà tàbí kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n Jésù yàtọ̀ sáwọn olórí ìsìn wọ̀nyẹn.
8 Jésù máa ń sún mọ́ àwọn mẹ̀kúnnù. Ó máa ń bá wọn jẹun, ó máa ń wò wọ́n sàn, ó máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n nírètí. Jésù kì í fi àlá tí ò lè ṣẹ tan ara rẹ̀ jẹ, ó mọ̀ pé èyí tó pọ̀ lára wọn ni ò ní gba àǹfààní tí wọ́n ní láti sin Jèhófà. (Mátíù 7:13, 14) Àmọ́, kì í ro ẹnikẹ́ni pin, ó sì mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ló lè ṣe ohun tó tọ́ bí wọ́n bá fẹ́. Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín Jésù àtàwọn ọ̀dájú àlùfáà àtàwọn Farisí yẹn! Èyí tó tiẹ̀ tún yani lẹ́nu jù ni pé àwọn àlùfáà àtàwọn Farisí kan lọ sọ́dọ̀ Jésù, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ ronú pìwà dà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. (Ìṣe 6:7; 15:5) Kódà díẹ̀ lára àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tó ní agbára níkàáwọ́ pàápàá mọ Jésù sẹ́ni tó ṣeé sún mọ́.—Máàkù 10:17, 22.
9. Kí ló jẹ́ káwọn obìnrin lè máa sún mọ́ Jésù?
9 Àwọn obìnrin pẹ̀lú kì í bẹ̀rù láti sún mọ́ Jésù. Ó dájú pé báwọn aṣáájú ìsìn ṣe máa ń kàn wọ́n lábùkù á ti fayé sú wọn. Àwọn rábì ní tiwọn kì í tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ pé ẹnì kan ń kọ́ àwọn obìnrin lẹ́kọ̀ọ́. Àní wọn kì í jẹ́ káwọn obìnrin ṣe ẹlẹ́rìí nílé ẹjọ́; wọ́n kà wọ́n sí ẹlẹ́rìí tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Kódà àwọn rábì ní àdúrà kan tí wọ́n máa ń gbà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún bí kò ṣe dá àwọn lóbìnrin! Àmọ́, ní ti Jésù, kì í kan àwọn obìnrin lábùkù bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ wọn ló tọ Jésù lọ torí pé ó ń wù wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Màríà ẹ̀gbọ́n Lásárù jókòó síbi ẹsẹ̀ Olúwa, tó sì ń fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ Jésù, nígbà tí Màtá, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń lọ tó ń bọ̀ níbi tó ti gbájú mọ́ oúnjẹ gbígbọ́. Jésù sì gbóríyìn fún Màríà nítorí tó fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sípò kìíní.—Lúùkù 10:39-42.
10. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín bí Jésù ṣe ń ṣe sáwọn aláìsàn àti báwọn aṣáájú ìsìn ṣe ń ṣe sí wọn?
10 Àwọn aláìsàn máa ń rọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù bó tiẹ̀ jẹ́ páwọn aṣáájú ìsìn ti kà wọ́n sẹ́ni ìtanù. Ó wà nínú Òfin Mósè pé kí wọ́n máa tọ́jú àwọn adẹ́tẹ̀ síbi ọ̀tọ̀ nítorí àìlera wọn, síbẹ̀ òfin yẹn ò fàyè gba ìwà àìnífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì. (Léfítíkù orí 13) Nígbà tó yá, àwọn rábì sọ pé àwọn adẹ́tẹ̀ ń ríni lára bí ìgbẹ́. Àwọn aṣáájú ìsìn tiẹ̀ bá a débi pé wọ́n ń sọ̀kò lu àwọn adẹ́tẹ̀ láti lè lé wọn jìnnà! Kò sẹ́ni tó lè rò pé irú àwọn èèyàn tí wọ́n ti hàn léèmọ̀ báyìí lè tún nígboyà láti lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ kan, ṣùgbọ́n kò nira fún wọn láti tọ Jésù lọ. Ọ̀rọ̀ kan tí ò ṣeé gbàgbé bọ̀rọ̀ tí ọ̀kan lára wọn sọ láti fi bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn, ni pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” (Lúùkù 5:12) Ní orí tó kàn, a óò jíròrò èsì tí Jésù fún un. Ní báyìí ná, a ti rí ẹ̀rí tó pọ̀ tá a fi lè sọ pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni Jésù.
11. Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé tìrọ̀rùntìrọ̀rùn làwọn tí ẹ̀rí ọkàn ń dà láàmù nítorí ìwà tí wọ́n hù fi máa ń tọ Jésù lọ, kí nìdí téyìí sì fi ṣe pàtàkì?
11 Àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ń dà láàmù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá máa ń sún mọ́ Jésù. Bí àpẹẹrẹ, rántí àkókò kan tí Jésù ń jẹun nílé Farisí kan. Obìnrin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ sún mọ́ Jésù ó sì kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ń sunkún nítorí bí ẹ̀rí ọkàn ṣe ń dà á láàmù. Omijé rẹ̀ dà sí ẹsẹ Jésù, ó sì fi irun orí ara rẹ̀ nù ún. Nígbà tẹ́ni tó gba Jésù lálejò rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn bí ohun ẹ̀gbin, tó sì bẹnu àtẹ́ lu Jésù fún bó ṣe gba irú obìnrin yẹn láyè láti sún mọ́ ọn, ńṣe ni Jésù gbóríyìn fún obìnrin yẹn nítorí bó ṣe ronú pìwà dà tinútinú, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà ti darí jì í. (Lúùkù 7:36-50) Àsìkò tá a wà yìí gan-an ló yẹ kó rọrùn fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn ń dà láàmù nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n hù láti lọ bá àwọn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè padà rí ojúure Ọlọ́run! Kí lohun náà gan-an tó mú kí Jésù ṣeé sún mọ́ bẹ́ẹ̀?
Kí Lohun Tó Mú Kí Jésù Ṣeé Sún Mọ́?
12. Kí nìdí tí ò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù ṣeé sún mọ́?
12 Rántí pé pátápátá ni Jésù fara wé àpẹẹrẹ Bàbá rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jòhánù 14:9) Bíbélì rán wa létí pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà, kò sì sígbà kan táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ tí kì í fetí sí wọn, ó tún máa ń fetí sí àwọn ẹlòmíì tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wá a láti lè jọ́sìn rẹ̀. (Sáàmù 65:2) Ọ̀rọ̀ ọ̀hún mà ga o, ẹni tó jẹ́ alágbára ńlá jù lọ láyé àtọ̀run, tó tún jẹ́ Ẹni tó ṣe pàtàkì jù náà ló tún jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ jù lọ yìí o! Jésù fẹ́ràn àwọn èèyàn bíi ti Bàbá rẹ̀. Láwọn orí tó wà níwájú, a óò jíròrò bí ìfẹ́ yẹn ṣe jinlẹ̀ tó lọ́kàn Jésù. Àmọ́ ṣá, lájorí ohun tó jẹ́ káwọn èèyàn lè sún mọ́ Jésù ni pé ó rọrùn fún wọn láti rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ìwà Jésù tó fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn.
13. Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
13 Kì í ṣòro fáwọn èèyàn láti mọ̀ pé Jésù kanlẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ìṣòro tó dé bá Jésù lákòókò kan ò dí i lọ́wọ́ láti fi hàn pé òun kanlẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, nígbà táwọn òbí mú àwọn ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo bọ́wọ́ rẹ̀ ṣe dí tó, tí iṣẹ́ tó wà níwájú rẹ̀ sì pọ̀ gan-an, ó ṣì jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Àpẹẹrẹ tó yááyì mà lèyí jẹ́ fáwọn òbí o! Iṣẹ́ ọmọ títọ́ ò rọrùn lákòókò tá a wà yìí. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì káwọn òbí jẹ́ káwọn ọmọ wọn rí wọn bí ẹni tó ṣeé sún mọ́. Bó o bá jẹ́ òbí, o mọ̀ pé nígbà míì, ọwọ́ rẹ lè dí débi pé o ò ní lè ráyè tàwọn ọmọ rẹ. Síbẹ̀ ǹjẹ́ o lè jẹ́ kọ́mọ náà mọ̀ pé wàá wáyè gbọ́ tiẹ̀ ní gbàrà tó o bá ti ṣe tán? Bó o bá ń pa àdéhùn mọ́, ọmọ rẹ á máa rí i pé sùúrù lérè. Ó tún máa mọ̀ pé kò sígbà tóun á kàn sí ọ bóyá torí nǹkan kan tàbí nítorí ìṣòro kan tó ò ní gbọ́ tòun.
14-16. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi di pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, kí sì nìdí tó fi jẹ́ iṣẹ́ ìyanu ńlá? (b) Kí ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ní Kánà jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ àwọn òbí?
14 Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò ṣàìnáání ìṣòro wọn. Bí àpẹẹrẹ, wo iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe. Ibi ìgbéyàwó ló lọ ní ìlú Kánà tó wà ní Gálílì. Ohun kan tí kò ṣeé gbọ́ sétí ló ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Àní ṣe ni wáìnì tán! Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù fi ohun tó ṣẹlẹ̀ tó ọmọ rẹ̀ létí. Kí wá ni Jésù ṣe? Ó ní káwọn tó wà níbẹ̀ pọn omi kúnnú ìṣà mẹ́fà tó wà ńbẹ̀. Nígbà tí wọ́n bu díẹ̀ nínú rẹ̀ wá fún olùdarí àsè pé kó tọ́ ọ wò, ó yà á lẹ́nu láti rí i pé ògidì wáìnì ni! Ṣé kì í ṣe pé ọgbọ́n arúmọjẹ kan ti wọ ọ̀ràn yẹn? Rárá o, kì í ṣe ọgbọ́n arúmọjẹ, Jésù ló ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ omi “di wáìnì.” (Jòhánù 2:1-11) Ó pẹ́ tó ti ń wu àwọn èèyàn láti mọ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń yí ohun kan padà di òmíì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan fi gbìyànjú láti yí òjé padà sí góòlù. Pẹ̀lú bí ohun tó para pọ̀ di òjé àti góòlù ṣe jọra tó, ẹ jẹ́ mọ̀ pé wọn ò tíì rọ́gbọ́n tí wọ́n á fi yí òjé padà sí góòlù. a Báwo lọ̀rọ̀ ti omi àti wáìnì ṣe wá jẹ́? Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín omi àti wáìnì. Èròjà méjì péré ló para pọ̀ di omi, àmọ́ èròjà tó para pọ̀ di wáìnì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èròjà wọ̀nyí ló tún ní ọ̀pọ̀ èròjà kéékèèké mìíràn nínú! Kí ló wa dé tí Jésù fi ṣe adúrú iṣẹ́ ìyanu yẹn torí àtiwá ojútùú sí ìṣòro kékeré tí kò ju pé ọ̀tí wáínì ò tó níbi àsè ìgbéyàwó kan?
15 Lójú àwọn tọkọtaya ọjọ́ yẹn, pé wáìnì tán níbi ìgbéyàwó wọn kì í ṣe ìṣòro kékeré rárá. Ìdí ni pé láyé ọjọ́un, àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé kì í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ títọ́jú àwọn àlejò wọn. Ìtìjú àti àbùkù gbáà ló máa jẹ́ fún tọkọtaya yẹn pé wáìnì tán lọ́jọ́ ẹ̀yẹ wọn. Ńṣe ni inú wọn ì bá sì máa bà jẹ́ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Ìṣòro ńlá ló dé bá wọn, Jésù sì rí i bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi wá nǹkan ṣe sí i. Ṣó o lè wá rí ìdí táwọn èèyàn fi ń gbé ẹ̀dùn ọkàn wọn lọ bá a?
16 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ̀yin òbí lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Ká sọ pé ìṣòro kan ti dorí ọmọ rẹ kodò, tó sì wá bá ọ, kí lo máa ṣe? Ó lè ṣe ọ́ bíi pé kó o fojú kéré ohun tó ń da ọmọ yẹn láàmù. O tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi rẹ́rìn-ín. Ó ṣe tán, bó o bá fi ìṣòro yẹn wé ohun tíwọ ń bá yí, kò tiẹ̀ ní fibì kankan jọ ìṣòro lójú rẹ rárá àti rárá. Ṣùgbọ́n o, má gbàgbé pé ìṣòro kékeré kọ́ ni lójú ọmọ yẹn! Ohun tó mú kó jẹ́ ìṣòro ńlá fẹ́ni tó o fẹ́ràn, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìwọ náà kà á sí ìṣòro? Bó o bá jẹ́ kí ọmọ rẹ máa rí i pé o ò ṣàìnáání ìṣòro òun, á kà ọ́ sí òbí tó ṣeé sún mọ́.
17. Àpẹẹrẹ wo nípa inú tútù ni Jésù fi lélẹ̀, kí sì nìdí tí ànímọ́ yìí kì í fi í ṣe àléébù?
17 Bá a ṣe jíròrò ní Orí 3, Jésù jẹ́ onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀. (Mátíù ) Ànímọ́ tó dáa gan-an tó sì máa ń fini hàn bí onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni jíjẹ́ onínú tútù. Ara èso tẹ̀mí ni, ó sì tan mọ́ ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. ( 11:29Gálátíà 5:22, 23; Jákọ́bù 3:13) Kódà nígbà táwọn kan ṣe nǹkan tó dun Jésù gan-an, ó ṣì kó ara rẹ̀ níjàánu. Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ onínú tútù kì í ṣe àléébù. Ọ̀mọ̀wé kan sọ nípa ànímọ́ yẹn, ó ní: “Nínú ìwà jẹ́jẹ́ ni agbára bí irin wà.” Ká sòótọ́, èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kéèyàn tó lè pa ìbínú mọ́ra kéèyàn sì fi inú tútù bá àwọn ẹlòmíì lò. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú jíjẹ́ onínú tútù, èyí tó máa jẹ́ ká lè jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́.
18. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa ń fòye bá àwọn èèyàn lò, kí sì nìdí tó o fi rò pé ànímọ́ yẹn máa jẹ́ kéèyàn jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́?
18 Jésù máa ń fòye báni lò. Nígbà tí Jésù wà ní Tírè, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nítorí pé “ẹ̀mí èṣù gbé” ọmọbìnrin rẹ̀ “dè burúkú-burúkú.” Lọ́nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Jésù jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò fẹ́ ṣe ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ òun yẹn. Lákọ̀ọ́kọ́, kò fèsì; lẹ́ẹ̀kejì, ó jẹ́ kó mọ ìdí tí ò fi yẹ kóun ṣe ohun tó béèrè; lẹ́ẹ̀kẹta, ó sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ kí ohun tó ń sọ ṣe kedere. Síbẹ̀ náà, ǹjẹ́ Jésù pariwo mọ́ obìnrin yẹn? Ǹjẹ́ ó ṣe ìṣe pé ńṣe lobìnrin yẹn ń forí ọká họmú bó ṣe ń gbó òun tóun jẹ́ ẹni ńlá bẹ́ẹ̀ lẹ́nu? Ó tì o, pẹ̀sẹ̀ lọkàn obìnrin yẹn balẹ̀. Kì í ṣe pé ó ní kí Jésù ran òun lọ́wọ́ nìkan ni, àmọ́ kò tún jánu lórí rẹ̀ àní bó tiẹ̀ mọ̀ pé Jésù ò fẹ́ ṣe nǹkan yẹn fún òun. Jésù rí i pé ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ ló jẹ́ kó lè tẹpẹlẹ mọ́ ohun tó ń fẹ́, ó sì wo ọmọbìnrin rẹ̀ sàn. (Mátíù 15:22-28) Ó dájú pé, bí Jésù ṣe máa ń fòye bá àwọn èèyàn lò, tó máa ń fara balẹ̀ gbọ́ wọn, tó sì máa ń gbà fún ẹlòmíì lákòókò tó bá tọ́, wà lára ohun tó jẹ́ káwọn èèyàn máa sún mọ́ ọn!
Ṣéwọ Náà Ṣeé Sún Mọ́?
19. Báwo la ṣe lè mọ̀ bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn èèyàn máa ń fẹ́ sún mọ́ wa?
19 Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ka ara wọn kún ẹni táwọn èèyàn lè tọ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó wà nípò àṣẹ sábà máa ń sọ pé ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn àwọn wà, pé àwọn tó ń ṣíṣẹ lábẹ́ àwọn lómìnira àtikàn sáwọn nígbàkigbà. Síbẹ̀ Bíbélì kì wá nílọ̀ pàtàkì yìí pé: “Olúkúlùkù nínú ògìdìgbó ènìyàn yóò máa pòkìkí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tirẹ̀, ṣùgbọ́n olùṣòtítọ́ ènìyàn, ta ní lè rí i?” (Òwe 20:6) Ó rọrùn láti sọ pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni wá, ṣùgbọ́n ṣé lóòótọ́ là ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀nà tó gbà fi ìfẹ́ hàn yìí? Ó lè jẹ́ pé àwa fúnra wa kọ́ la máa dáhùn, àwọn ẹlòmíì ló lè sọ irú ẹni tá a jẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú ẹni wo làwọn èèyàn mọ̀ mí sí? Orúkọ wo ni mo ti ṣe fún ara mi?’
20. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà ìjọ ṣeé sún mọ́? (b) Kí nìdí tí ohun tá a gbọ́dọ̀ máa retí lọ́dọ̀ àwọn alàgbà fi gbọ́dọ̀ mọ níwọ̀n?
20 Ní pàtàkì jù lọ, àwọn alàgbà ìjọ máa ń rí i pé àwọn ṣeé sún mọ́. Wọ́n máa ń sapá láti rí i pé àpèjúwe tó wà nínú Aísáyà 32:1, 2 bá àwọn mu, èyí tó sọ pé: “Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” Bí alàgbà kan bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, á lè máa dáàbò bo àwọn àgùntàn Jèhófà, á máa mára tù wọ́n á sì máa gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ ìṣòro. Òótọ́ ni pé kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó já lé wọn léjìká lákòókò tó ṣòro yìí. Síbẹ̀, àwọn alàgbà ní láti máa rí i pé ọwọ́ àwọn ò dí jù débi tí wọn ò fi ní lè bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà. (1 Pétérù ) Àwọn ará sì máa ń gbìyànjú láti má ṣe retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tó ń fi tinútinú ṣe iṣẹ́ wọn, èyí tó fi hàn pé àwọn ará nírẹ̀lẹ̀, wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀.— 5:2Hébérù 13:17.
21. Báwo làwọn òbí ṣe lè jẹ́ ẹni táwọn ọmọ wọn á lè sún mọ́ nígbàkigbà, kí la sì máa jíròrò ní orí tó kàn?
21 Ńṣe làwọn òbí ní láti máa wá bí wọ́n á ṣe máa ráyè fáwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà. Eléyìí kì í ṣe ọ̀ràn kékeré o! Kí wọ́n jẹ́ káwọn ọmọ wọn rí wọn bíi Bàbá tàbí Ìyá tí wọ́n lè finú hàn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní láti jẹ́ onínú tútù àti ẹni tó ń fòye bá wọn lò, kí wọ́n má ṣe máa gbaná jẹ bí ọmọ wọn bá jẹ́wọ́ àṣìṣe kan tó ṣe tàbí tó sọ ohun kan tó fi hàn pé ohun tó ń rò lọ́kàn ò dáa. Bí àwọn òbí ṣe ń fi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí àyè ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wà. Ó dájú pé gbogbo wa la máa fẹ́ jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ bíi ti Jésù. Ní orí tó kàn, a óò jíròrò bó ṣe máa ń wu Jésù látọkànwá láti fi ìyọ́nú bá àwọn èèyàn lò, èyí tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ànímọ́ tó mú kó ṣeé sún mọ́.
a Àwọn onímọ̀ kẹ́mísìrì mọ̀ pé ohun tó para pọ̀ di òjé jọra gan-an pẹ̀lú ohun tó para pọ̀ di góòlù. Àwọn onímọ̀ físíìsì òde òní ti yí ìwọ̀n òjé díẹ̀ padà di góòlù, àmọ́ iye owó tó ná wọn ti pọ̀ jù, èyí tó túmọ̀ sí pé kò mọ́gbọ́n dání láti tẹ̀ síwájú.