Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Bá A Ṣe Wọ Ọdún 2023, Kí Lá Jẹ́ Kọ́kàn Wa Balẹ̀ Pé Ọ̀la Máa Dáa?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Lọ́dún 2023 tá a mú báyìí, gbogbo wa là ń retí pé kí nǹkan túbọ̀ ṣẹnuure fún àwa àti ìdílé wa. Àmọ́, kí nìdí tá a fi gbà pé nǹkan máa dáa?
Bíbélì fún wa nírètí
Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ìṣòro tá a ní báyìí ò ní pẹ́ dópin. Kódà, ńṣe la kọ Bíbélì “fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí nípasẹ̀ . . . ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.”—Róòmù 15:4.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”
Ìrètí tó ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ nísinsìnyí
Ìrètí tó wà nínú Bíbélì dà bí “ìdákọ̀ró fún ẹ̀mí wa.” (Hébérù 6:19, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Ìrètí yìí máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Ìdí ni pé ó ń jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tá à ń bá yí, ká lérò tó dáa, ká sì ní ayọ̀ tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ:
Wo fídío náà Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi kó o lè rí bí Bíbélì ṣe ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ láti borí ìwà tó ti di bárakú fún un.
Tó o bá fẹ́ mọ bí ìrétí tó wà nínú Bíbélì ṣe lè tù wá nínú téèyàn wa bá kú, wo fídío náà Bá A Ṣe Lè Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú.
Ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé ọ̀la máa dáa
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí pé káwọn nǹkan rere ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wọn, síbẹ̀ kò dá wọn lójú pé àwọn nǹkan náà máa ṣẹlẹ̀. Àmọ́ àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì yàtọ̀. Kí nìdí? Torí ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run a“ẹni tí kò lè parọ́” ni àwọn ìlérí náà ti wá (Títù 1:2) Jèhófà nìkan ló lágbára láti mú àwọn ìlérí tó bá ṣe ṣẹ; kò sí ohunkóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe “gbogbo ohun tó bá fẹ́.”—Sáàmù 135:5, 6.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Bíbélì, kó o lè jàǹfààní nínú àwọn ìlérí tó ṣe. Ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára tó o bà “ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní.” (Ìṣe 17:11) Tó o bá fẹ́, ẹnì kan lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, o ò ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún 2023 pẹ̀lú àwọn ohun tá a sọ yìí, wàá sì rí i pé dídùn lọsàn máa so!
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.