Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Táwọn Èèyàn Ò Ní Máa Gbé Ẹ̀yà Kan Ga Ju Ẹ̀yà Míì Lọ?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ọjọ́ pẹ́ tọ́pọ̀ ti ń retí ìgbà táwọn èèyàn ò ní máa gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíì lọ. Àmọ́ títí di báyìí, ìyẹn ò tíì ṣẹlẹ̀.
“Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti ba nǹkan jẹ́ gan-an láyé yìí, torí pé kò síbi tẹ́ ẹ yíjú sí tẹ́ ò ti ní rí ìwà burúkú yìí, ì báà jẹ́ láwọn ilé iṣẹ́ tàbí láwùjọ àwọn èèyàn. Ìwà yìí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa fojú burúkú wo ara wọn.”—António Guterres tó jẹ́ Akọ̀wé Àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé.
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní máa gbé ẹ̀yà kan ga ju ẹ̀yà míì lọ? Kí ni Bíbélì sọ?
Ṣé Ọlọ́run ka ẹ̀yà kan sí pàtàkì ju òmíì lọ?
Bíbélì jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn tó wá láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
“Láti ara ọkùnrin kan [ni Ọlọ́run] ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn láti máa gbé lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 17:26.
“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”—Ìṣe 10:34, 35.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ ìyá ni gbogbo èèyàn tó wà láyé àti pé kò sẹ́ni tí ò lè rí ojú rere Ọlọ́run láìka ẹ̀yà tó ti wá sí.
Ohun tó máa fòpin sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà
Ìjọba Ọlọ́run ló máa fòpin sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ìjọba yẹn máa kọ́ àwọn èèyàn nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sí ara wọn. Àwọn èèyàn máa mọ bí wọ́n ṣe lè fa ìkórìíra àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu kúrò lọ́kàn wọn.
“Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà máa kọ́ òdodo.”—Àìsáyà 26:9.
“Àlàáfíà ni òdodo tòótọ́ máa mú wá, èso òdodo tòótọ́ sì máa jẹ́ ìparọ́rọ́ àti ààbò tó máa wà pẹ́ títí.”—Àìsáyà 32:17.
Ní báyìí, Bíbélì ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn míì, kí wọ́n sì máa pọ́n wọn lé bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka ìwé ìròyìn Jí! tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ṣé Ìkórìíra Lè Dópin?”
Tó o bá fẹ́ mọ bí àwọn òbí ṣe lè bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà.”