Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Bá Lómìnira Àtijáde Bíi Ti Tẹ́lẹ̀

Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Bá Lómìnira Àtijáde Bíi Ti Tẹ́lẹ̀

 Ṣé nǹkan ti sú ẹ torí pé o ò lè jáde nílé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ bíi tí onísáàmù kan tó sọ pé: “Mo dà bí ẹyẹ tó dá wà lórí òrùlé.” (Sáàmù 102:7) Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ kó o rọ́gbọ́n dá sí ìṣòro tó máa ń wáyé tí èèyàn ò bá lè kúrò nílé torí àwọn ìdí kan.

 Túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run

 Kódà tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti kúrò lójú kan, o ṣì lè láyọ̀ tó o bá ní in lọ́kàn pé ó fẹ́ túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run tó o sì ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Mátíù 5:3, 6) Àwọn ohun tó o lè rí lọ́fẹ̀ẹ́ tá a tò sísàlẹ̀ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa ṣe é.

 Ka àwọn apá ibi tó máa jẹ́ kára tù ẹ́ nínú Bíbélì

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tò sísàlẹ̀ yìí ti tu ọ̀pọ̀ èèyàn nínú. Má wulẹ̀ ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì yìí lẹ́ẹ̀kàn náà, lo àkókò tó o fi wà nílé yìí láti fi ka àwọn Bíbélì náà díẹ̀díẹ̀, kó o ronú lórí ohun tó o kà, kó o sì gbàdúrà.​—Máàkù 1:35.

 Kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè mọ ohun tó fà á táwọn nǹkan fi rí bó ṣe rí yìí

 Wàá lókun láti fara da ipò kan tó ń kó ìdààmú bá ẹ tó o bá mọ ohun tó fà á tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ àti bí Ọlọ́run ṣe máa dáwọ́ ẹ̀ dúró táa sì ṣàtúnṣe sáwọn ohun tó ti bà jẹ́.​—Àìsáyà 65:17.

 Má ṣe kó ara ẹ lọ́kàn sókè láìnídìí

 Tó o bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tá a sọ nísàlẹ̀ yìí, á jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀ kí ìdààmú tí àìlè kúrò nílé máa ń fà má bàa bò ẹ́ mọ́lẹ̀, á sì jẹ́ kó o “yéé ṣàníyàn.”​—Mátíù 6:25.

 Wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́

 Tó o bá lọ́rẹ̀ẹ́ tó o lè fọ̀rọ̀ lọ̀, wàá lè ronú lọ́nà tó já gaara, inú ẹ sì máa dùn, àgàgà lásìkò téèyàn ò lè rí ọ̀rẹ́ náà lójúkojú. Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti kúrò nílé, o lè pe àwọn ọ̀rẹ́ tó o ti ní tẹ́lẹ̀ lórí fóònù kẹ́ ẹ lè gbóhùn ara yín tàbí kẹ́ ẹ tiẹ̀ ríra yín látorí fóònù, èyí máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọwọ́ ara yín, kó o sì tún ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Àwọn àpilẹ̀kọ tá a tò sísàlẹ̀ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti bíwọ náà ṣe lè jẹ́ “ọ̀rẹ́ tòótọ́.”​—Òwe 17:17.

 Ṣe ohun tó máa jẹ́ kára ẹ yá gágá

 Bíbélì sọ pé “àǹfààní . . . wà nínú eré ìmárale.” (1 Tímótì 4:8) Ó máa jẹ́ kó o lè ronú dáadáa, kò sì ní jẹ́ kí ọkàn ẹ bà jẹ́, pàápàá lásìkò tó ò lè kúrò nílé. A ti rí i pé kódà tí o ò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti kúrò nílé, ó ṣì láwọn nǹkan tó o lè ṣe tí kò ní jẹ́ kí nǹkan sú ẹ.