Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

mustafahacalaki/DigitalVision Vectors via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Àwọn Ètò Kọ̀ǹpútà Tó Lè Dá Ṣiṣẹ́​—Ṣé Wọ́n Máa Ṣe Wá Láǹfààní, àbí Wọ́n Máa Dá Kún Ìṣòro Wa?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Àwọn Ètò Kọ̀ǹpútà Tó Lè Dá Ṣiṣẹ́​—Ṣé Wọ́n Máa Ṣe Wá Láǹfààní, àbí Wọ́n Máa Dá Kún Ìṣòro Wa?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn alákòóso ayé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn onímọ̀ nípa kọ̀ǹpútà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ètò kọ̀ǹpútà tó lè dá ṣiṣẹ́ láìsí ẹni tó ń darí ẹ̀ (ìyẹn AI). Wọ́n sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ètò kọ̀ǹpútà yìí wúlò, àwọn kan lè lò ó nílòkulò kí wọ́n sì fi ṣe wá ní jàǹbá.

  •   “Ètò kọ̀ǹpútà tó ń dá ṣiṣẹ́ yìí ni ètò kọ̀ǹpútà tó lágbára jù lọ. Wọ́n ṣe é kó lè mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn lóde òní . . . Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó lè fi ẹ̀mí àwọn ará ìlú sínú ewu, ó sì lè gbé àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ ti ara ẹni síta. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè mú káwọn èèyàn má fọkàn tán ìjọba.”​—Kamala Harris tó jẹ́ igbá kejì ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, May 4, 2023.

  •   “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ètò kọ̀ǹpútà tó ń dá ṣiṣẹ́ yìí ti mú kí ọ̀nà ìtọ́jú àwọn aláìsàn túbọ̀ dáa sí i, ó tún lè kó bá ìlera wa.” Ọ̀rọ̀ yìí jáde nínú ìwé BMJ Global Health a tí àwùjọ àwọn dókítà lágbàáyé àtàwọn elétò ìlera kọ ní May 9, 2023. Dókítà Frederik Federspiel ló sì jẹ́ alága àwùjọ yìí.

  •   “Àwọn èèyàn tún lè lo ètò kọ̀ǹpútà tó ń dá ṣiṣẹ́ yìí láti tan àwọn ọ̀rọ̀ tí kò jóòótọ́ kálẹ̀. Kò tán síbẹ̀ o, torí pé ètò kọ̀ǹpútà yìí lè ṣe ohun tọ́pọ̀ èèyàn ń ṣe, láìpẹ́ ó máa mú kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Kódà àwọn onímọ̀ nípa kọ̀ǹpútà sọ pé, bópẹ́bóyá ètò kọ̀ǹpútà yìí máa fi ẹ̀mí àwọn èèyàn sínú ewu.”​—The New York Times, May 1, 2023.

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àá mọ̀ bóyá ètò kọ̀ǹpútà yìí máa ṣe wá láǹfààní, àbí ó máa dá kún ìṣòro wa. Kí ni Bíbélì sọ?

Ìdí tá ò fi lè gbára lé gbogbo ohun táwọn èèyàn ṣe

 Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí táwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ò fi lè fọwọ́ sọ̀yà pé gbogbo ohun táwọn bá ṣe ò ní mú aburú kankan wá.

  1.  1. Tàwọn èèyàn bá tiẹ̀ ní èrò tó dáa láti ṣe nǹkan, wọn kì í sábà ronú lórí àkóbá tí ohun náà máa mú wá.

    •   “Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn, àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.”​—Owe 14:12.

  2.  2. Ẹni tó ṣe nǹkan ò lè pinnu bí gbogbo èèyàn ṣe máa lò ó

    •   “Mo gbọ́dọ̀ fi [iṣẹ́ mi] sílẹ̀ fún ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Ta ló sì mọ̀ bóyá ó máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀? Síbẹ̀, òun ni yóò máa darí gbogbo ohun tí mo ti fi akitiyan àti ọgbọ́n kó jọ lábẹ́ ọ̀run.”​—Oníwàásù 2:18, 19.

 Àwọn ohun tá a ti sọ yìí jẹ́ ká rí i pé Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló lè ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tó pé.

Ta ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé?

 Ẹlẹ́dàá wa ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ èyíkéyìí pa ayé yìí run.

  •   “Ayé wà títí láé.”​—Oníwàásù 1:4.

  •   “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”​—Sáàmù 37:29.

 Ẹlẹ́dàá wa máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti fún wa nímọ̀ràn tó máa jẹ́ ká gbádùn ọjọ́ ọ̀la wa. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa?” àti “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”

a Látinú àpilẹ̀kọ náà “Threats by Artificial Intelligence to Human Health and Human Existence,” tí Frederik Federspiel, Ruth Mitchell, Asha Asokan, Carlos Umana, àti David McCoy kọ.