Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ṣé Ìkànnì Àjọlò Ń Ṣàkóbá fún Ọmọ Ẹ?—Bíbélì Lè Ran Àwọn Òbí Lọ́wọ́
“Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lónìí túbọ̀ ń rẹ̀wẹ̀sì, kò sì sí àní-àní pé ìkànnì àjọlò jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń fà á.”—Dókítà Vivek Murthy, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, New York Times, June 17, 2024.
Kí làwọn òbí lè ṣe kí ìkànnì àjọlò má bàa ṣàkóbá fáwọn ọmọ wọn? Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò.
Ohun táwọn òbí lè ṣe
Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì yìí.
“Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”—Òwe 14:15.
Má ṣe tìtorí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń lo ìkànnì àjọlò, kó o wá gba ọmọ ẹ̀ náà láyè láti máa lò ó. Rántí pé ó lè ṣàkóbá fún un. Kó o tó gba ọmọ ẹ láyè láti lò ó, rí i dájú pé ó ti gbọ́n tó láti ṣègbọràn sí òfin tó o bá fún un nípa àkókò tó máa lò nídìí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó ti lè yan àwọn ọ̀rẹ́ gidi, kó sì pinnu láti má ṣe wo ìwòkuwò.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?” àti “Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò.”
“Máa lo àkókò [ẹ] lọ́nà tó dára jù lọ.”—Éfésù 5:16.
Tó o bá gba ọmọ ẹ̀ láyè láti lo ìkànnì àjọlò, fún un ní òfin nípa bó ṣe máa lò ó, kó o sì ṣàlàyé báwọn òfin náà ṣe máa dáàbò bò ó. Máa kíyè sí ọmọ ẹ, tó o bá sì rí i pé ìwà ẹ̀ yí pa dà, o lè pinnu láti dín bó ṣe ń lo ìkànnì àjọlò kù.
Jẹ́ kí ọmọ ẹ wo eré ojú pátákó náà Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò kó lè mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká ṣọ́ra tá a bá ń lò ó.
Mọ púpọ̀ sí i
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní “àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.” (2 Tímótì 3:1-5) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́. O máa rí àwọn àpilẹ̀kọ tó lé ní ogún (20) tó máa ṣe àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn láǹfààní nínú àpilẹ̀kọ tó dá lórí bí ìbànújẹ́ ṣe ń dorí àwọn ọ̀dọ́ kodò.