ÌRÁNTÍ IKÚ JÉSÙ
Jésù Máa Fòpin sí Ipò Òṣì
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an pàápàá àwọn aláìní àtàwọn tó ń jìyà. (Mátíù 9:36) Kódà, ó fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13) Láìpẹ́, Jésù tún máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tó bá lo àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run láti fòpin sí ipò òṣì kárí ayé.
Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ ewì láti ṣàlàyé ohun tí Jésù máa ṣe, ó ní:
“Kí ó gbèjà àwọn tó jẹ́ aláìní, kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là.”—Sáàmù 72:4.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ti ṣe fún wa àtohun tó ṣì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? Ní Lúùkù 22:19, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa rántí ikú òun. Lọ́dọọdún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láti rántí ikú ẹ̀ ní àyájọ́ ọjọ́ tó kú. Torí náà, a fẹ́ kó o dára pọ̀ mọ́ wa láti rántí ikú Jésù lọ́jọ́ Sunday, March 24, 2024.