Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Láyé?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Láìka gbogbo ìgbìyànjú àwọn alákòóso ayé àti onírúurú àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀, kò sí àlàáfíà ni ayé yìí. Kódà, àsìkò yìí ni ogun àti rògbòdìyàn tíì pọ̀ jù láyé látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti jà. Nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì, ìyẹn bí ìdá mẹ́rin àwọn tó wà láyé ló ń gbé láwọn ibi tí ogun àti rògbòdìyàn ti ń wáyé.
Kí nìdí tí ò fi sí àlàáfíà láìka gbogbo ìsapá àwọn èèyàn sí? Kí ni Bíbélì sọ?
Ìdí mẹ́ta táwọn èèyàn ò fi lè mú kí àlàáfíà wà
1. Ìwà táwọn èèyàn ń hù lónìí kì í jẹ́ kí àlàáfíà wà. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, lákòókò wà yìí, “àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, . . . aláìṣòótọ́, . . . kìígbọ́-kìígbà, . . . ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, . . . alágídí, ajọra-ẹni-lójú.”—2 Tímótì 3:2-4.
2. Àwa èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀ kò lágbára láti yanjú ìṣòro ayé yìí láìjẹ́ pé Jèhófà a Ẹlẹ́dàá wa dá sí i. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
3. Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára Sátánì Èṣù tó jẹ́ alákòóso búburú tó sì “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.” (Ìfihàn 12:9) Tí ‘gbogbo ayé bá ṣì wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,’ ogun àti rògbòdìyàn á máa ṣẹlẹ̀.—1 Jòhánù 5:19.
Ta ló lè mú kí àlàáfíà wà?
Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí àlàáfíà wà, ìsapá èèyàn ò lè ṣe é.
“‘Nítorí mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”—Jeremáyà 29:11.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí yìí ṣẹ? Bíbélì sọ pé ‘Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà máa tẹ Sátánì rẹ́.’ (Róòmù 16:20) Ọlọ́run máa lo Ìjọba kan tí Bíbélì pè ní “Ìjọba Ọlọ́run,” láti mú kí àlàáfíà wà kárí ayé. (Lúùkù 4:43) Jésù Kristi ló máa jẹ́ Ọba Ìjọba náà, á sì kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà.—Àìsáyà 9:6, 7.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.