Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ìwà Ọmọlúàbí Ti Ṣọ̀wọ́n—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ìwà ọmọlúàbí kò wọ́pọ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ló máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn dókítà. Àwọn tó lọ ń jẹun nílé oúnjẹ sábà máa bú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Kò tán síbẹ̀ o, lára àwọn tó ń wọ ọkọ̀ òfúrufú máa ń kanra mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òfúrufú. Bákan náà, àwọn ọmọ ilé ìwé tó ti yàyàkuyà máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn olùkọ́ wọn, wọ́n sì máa n lù wọ́n nígbà míì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn olóṣèlú kan máa ń ṣe ohun májẹ̀ágbọ́, àwọn olóṣèlú míì sì máa ṣojú ayé bíi pé ọmọlúàbí ni wọ́n.
Bíbélì sọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní ìwà ọmọlúàbí. Ó sì tún jẹ́ ká mọ ìdí tí ìwà ọmọlúàbí fi ṣọ̀wọ́n nínú ayé lónìí.
Kí nìdí tí kò fi sí ìwà ọmọlúàbí mọ́?
Kárí ayé ni àwọn èèyàn ò ti ní ìwà ọmọlúàbí mọ́, wọn kì í ka àwọn èèyàn sí, wọn kì í sì í pọ́n wọn lé.
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, wọ́n rí i pé àsìkò yìí ni ìwà ọmọlúàbí tíì ṣọ̀wọ́n jù lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti nǹkan bí ọdún méjìlélógún (22) sẹ́yìn.
Nínú ìwádìí míì, wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) láti orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gbọ̀n (28), àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méje nínú mẹ́wàá ló sọ pé bí ìwà ọmọlúàbí ṣe pòórá láwùjọ ń kọni lóminú gan-an.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwà táwọn èèyàn á máa hù lónìí.
“Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, . . . aláìnífẹ̀ẹ́, [àti] aláìlè-kó-aràwọn-níjánu.”—2 Tímótì 3:1-3, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-òní.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?”
Ohun táá jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ìwà ọmọlúàbí
Nínú ayé tí ìwà ọmọlúàbí ti ṣọ̀wọ́n, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé Bíbélì ṣàlàyé ohun tí èèyàn lè ṣe kó lè ní ìwà ọmọlúàbí. Àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ ṣeé “gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.” (Sáàmù 111:8) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀:
Ohun tí Bíbélì sọ: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”—Mátíù 7:12.
Ohun tó túmọ̀ sí: Torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà dáadáa sí wa, ṣe ló yẹ káwa náà máa bọ̀wọ̀ fún wọn ká sì máa hùwà dáadáa sí wọn.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ní báyìí tí ẹ ti fi ẹ̀tàn sílẹ̀, kí kálukú yín máa bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ó yẹ ká máa sọ òótọ́ nígbà gbogbo, ká sì máa hùwà tó fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, o lè lọ ka:
Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa.”
Àpilẹ̀kọ “Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì.”