Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Nǹkan Ò Rọrùn Fáwọn Èèyàn Lọ́dún 2023—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ kárí ayé lọ́dún 2023 jẹ́ kó hàn gbangba pé a ti wà ní akókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Ẹ jẹ́ ká wo bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ṣe bá ohun tí Bíbélì sọ pé á máa wáyé lákòókò yìí mu.
Ohun tí Bíbélì sọ pé á máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé
‘Àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun.’—Mátíù 24:6.
“Ọ̀pọ̀ ibi ni wọ́n ti ń jagun, rògbòdìyàn sì túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé.” a
Ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ta Ló Máa Gba Àwọn Aráàlú?” àti “Iye Tí Wọ́n Ti Ná Lórí Nǹkan Ìjà Ogun Kárí Ayé Ti Lé Ní Tírílíọ̀nù Méjì Dọ́là.”
“Ìmìtìtì ilẹ̀ máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”—Máàkù 13:8.
“Ìgbà mẹ́tàlá ni ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára lọ́nà tó kàmàmà wáyé lọ́dún 2023, iye yẹn ló sì pọ̀ jù látìgbà tí wọ́n ti ń ṣàkọsílẹ̀ ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lọ́dọọdún.” b
Ka àpilẹ̀kọ náà “Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Runlé-Rùnnà ní Orílẹ̀-Èdè Tọ́kì àti Síríà.”
“Àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù.”—Lúùkù 21:11.
“Ohun tá a máa ń sọ tẹ́lẹ̀ ni pé ayé ń móoru, àmọ́ ní báyìí, ṣe ló ń gbóná janjan.”—António Guterres, Akọ̀wé Àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé. c
Ka àpilẹ̀kọ náà “Ooru Tó Gbóná Janjan Mú Kárí Ayé Lọ́dún 2023.”
“Àìtó oúnjẹ.”—Mátíù 24:7.
“Kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ láti bọ́ ìdílé wọn lọ́dún 2023.” d
Ka àpilẹ̀kọ náà “Ogun àti Ojú Ọjọ́ Tó Ń Burú Sí I Túbọ̀ Ń Fa Ọ̀wọ́n Gógó Oúnjẹ Kárí Ayé.”
‘Nǹkan máa le gan-an, á sì nira.’—2 Tímótì 3:1.
“Ìdá kan nínú mẹ́jọ̀ àwọn èèyàn kárí ayé ló ní ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà tàbí àwọn àrùn ọpọlọ míì.” e
Ka àpilẹ̀kọ náà “Ìbànújẹ́ Túbọ̀ Ń Dorí Ọ̀pọ̀ Àwọn Ọ̀dọ́ Kodò.”
Kí ni ká máa retí lọ́dún 2024?
Kò sẹ́ni tó lè sọ ohun táá ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2024. Àmọ́, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé fi hàn pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò ìjọba èèyàn, á sì fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìyà àti ìnira.—Dáníẹ́lì 2:44; Ìfihàn 21:4.
Ní báyìí ná, tí ọkàn wa ò bá balẹ̀, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé:
“Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí, mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.”—Sáàmù 56:3.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run? A rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú nípa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. O lè ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ kó o lè mọ bí àwọn ìlérí Bíbélì ṣe máa ṣe ìwọ àti ìdílé ẹ láǹfààní.
a Foreign Affairs, “A World at War: What Is Behind the Global Explosion of Violent Conflict?” látọwọ́ Emma Beals àti Peter Salisbury, October 30, 2023.
b Earthquake News, “Year 2023: Number of Major Earthquakes on Course for Record,” May, 2023.
c United Nations, “Secretary-General’s Opening Remarks at Press Conference on Climate,” July 27, 2023.
d World Food Programme, “A Global Food Crisis.”
e World Health Organization, “World Mental Health Day 2023,” October 10, 2023.