Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kim Steele/The Image Bank via Getty Images

ÀKÀNṢE ÌWÀÁSÙ

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe Sí Ìṣòro Àtijẹ-Àtimu

 Àtijẹ-àtimu túbọ̀ ń nira fáwọn èèyàn kárí ayé, òótọ́ ibẹ̀ sì ni pé ṣe ló túbọ̀ ń le sí i.

  •   Ìròyìn kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ ká rí i pé, a “Owó tó ń wọlé fáwọn èèyàn ò tó ra nǹkan tí wọ́n nílò mọ́.” Ìròyìn náà tún fi kún un pé tí wọn ò bá wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, “ìyàtọ̀ tó máa wà láàárín olówó àtàwọn tálákà máa pọ̀ gan-an,” àti pé “nǹkan á túbọ̀ nira ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fáwọn ìdílé míì.”

 Ṣé ìjọba kan wà tó lè yanjú ìṣòro àtijẹ- àtimu?

 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tó máa fòpin sí ìṣòro ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, ìjọba náà á sì jẹ́ kí gbogbo èèyàn ní nǹkan lọ́gbọọgba. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,” ìjọba yìí lá sì máa ṣàkóso gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ ìjọba yẹn, Ọlọ́run ò ní gbàgbé ẹnì kankan a ò sì ní pa ẹnikẹ́ni tì. (Sáàmù 9:18) Gbogbo àwọn tó bá wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ló máa ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Gbogbo èèyàn ló sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.​—Àìsáyà 65:21, 22.

a Ìròyìn àjọ International Labour Organization tó dá lórí iye tó ń wọlé fáwọn èèyàn lóṣooṣù