Ọ̀rọ̀ Ààbò Àwọn Obìnrin—Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó jẹ́ obìnrin ni wọ́n ti hùwà ìkà sí kárí ayé. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí i pé ọ̀rọ̀ ẹ jẹ Ọlọ́run lógún àti pé ó máa wá nǹkan ṣe sí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn obìnrin.
“Nígbà tí mo wà ní kékeré, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin máa ń bú mi ó sì máa ń lù mí lójoojúmọ́. Lẹ́yìn tí mo lọ sílé ọkọ, ìyá ọkọ mi náà fojú mi rí màbo. Ṣe lòun àti bàbá ọkọ mi sọ mí dẹrú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n para mi.”—Madhu, a Íńdíà.
Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Kò síbi tá a yíjú sí, tí wọn kì í tí hùwà ìkà sáwọn obìnrin.” Wọ́n fojú bù ú pé, ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn obìnrin ni wọ́n ti lù tàbí fipá bá ṣèṣekúṣe nígbà kan rí láyé wọn.
Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ẹrù lè máa bà ẹ́ pé gbogbo ibi tó o bá lọ ni wọ́n ti lè bú ẹ, kí wọ́n lù ẹ́ tàbí kí wọ́n fipá bá ẹ lòpọ̀. Torí náà, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ka àwọn obìnrin sí. Àmọ́ ṣé Ọlọ́run ka àwọn obìnrin sí, ṣé ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún?
Ṣé Ọlọ́run ka àwọn obìnrin sí?
Ohun Tí Bíbélì Sọ: “Akọ àti abo [ni Ọlọ́run] dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ló dá ọkùnrin àti obìnrin. Ìyẹn fi hàn pé ó ka àwọn méjèèjì sí. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run fẹ́ kí ọkọ kan “nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀,” kò yẹ kó máa fipá mú un ṣe nǹkan, kò sì yẹ kó máa fọ̀rọ̀ burúkú gún un lára tàbí kó máa lù ú. (Éfésù 5:33; Kólósè 3:19) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé, Ọlọ́run ka àwọn obìnrin sí, kò sì fẹ́ kí nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ sí wọn.
“Nígbà tí mo wà ní kékeré, àwọn mọ̀lẹ́bí mi máa ń fipá bá mi sùn. Mo rántí ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), ọ̀gá mi sọ pé òun máa lé mi kúrò níbi iṣẹ́ tí mi ò bá gbà kóun bá mi sùn. Nígbà tí mo dàgbà, ọkọ mi, àwọn òbí mi àtàwọn aládùúgbò wa máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà b Ẹlẹ́dàá wa. Mo rí i pé ó ka àwa obìnrin sí gan-an. Ó wá túbọ̀ dá mi lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ mi, ọ̀rọ̀ mi sì jẹ ẹ́ lógún.”—Maria, Ajẹntínà.
Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kára bẹ̀rẹ̀ sí í tù ẹ́?
Ohun Tí Bíbélì Sọ: “Ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.”—Òwe 18:24.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa dúró tì ẹ́. Tó o bá fẹ́, o lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fẹ́nì kan tó o fọkàn tán.
“Fún nǹkan bí ogún (20) ọdún, mi ò sọ fẹ́nì kankan pé wọ́n ti fipá bá mi sùn rí. Torí náà, inú mi kì í dùn, ọkàn mi kì í balẹ̀, mo sì máa ń kárí sọ. Àmọ́ nígbà tí mo sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi fẹ́nì kan tó fara balẹ̀ gbọ́ mi, ṣe lara tù mí pẹ̀sẹ̀.”—Elif, Türkiye.
Ohun Tí Bíbélì Sọ: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ [Ọlọ́run], torí ó ń bójú tó yín.”—1 Pétérù 5:7.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wa. (Sm 55:22; 65:2) Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó máa jẹ́ kó o rí i pé ẹni iyì ni ẹ́ láìka ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ.
“Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà bẹ́ẹ̀ lara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí. Ní báyìí, mo lè sọ gbogbo bọ́rọ̀ bá ṣe rí lára mi fún Jèhófà. Ọ̀rẹ́ mi ni, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi.” —Ana, Belize.
Ṣé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn obìnrin?
Ohun Tí Bíbélì Sọ: “Jèhófà . . . wàá dá ẹjọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba àti ẹni tí a ni lára, kí ẹni kíkú lásánlàsàn má bàa dẹ́rù bà wọ́n mọ́.”—Sáàmù 10:17, 18.
Ohun tó túmọ̀ sí: Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ, títí kan ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn obìnrin.
“Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa tó fòpin sí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn obìnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin, ará tù mí, ọkàn mi sì balẹ̀.”—Roberta, Mẹ́síkò.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè tù ẹ́ nínú, ìdí tá a fi gbà pé àwọn ìlérí inú ẹ̀ máa ṣẹ àti bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lè fi Bíbélì ràn ẹ́ lọ́wọ́, sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”