Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ta Lo Lè Fọkàn Tán?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ó máa ń dun àwọn èèyàn gan-an tí ẹni tí wọ́n fọkàn tán bá já wọn kulẹ̀. Ọ̀pọ̀ ò fọkàn tán . . .
àwọn olóṣèlú tó jẹ́ pé àpò ara wọn ni wọ́n ń dù.
àwọn oníròyìn tí kì í sọ òótọ́ délẹ̀délẹ̀ tí wọ́n sì máa ń gbè sápá kan.
àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí kì í ro táwọn èèyàn.
àwọn aṣáájú ìsìn tó ń gbé àwọn olóṣèlú lárugẹ dípò kí wọ́n máa ṣojú fún Ọlọ́run.
Ó yẹ kéèyàn ṣọ́ra kó tó fọkàn tán ẹnì kan. Bíbélì kìlọ̀ pé:
“Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè; eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.”—Orin Dafidi 146:3, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.
Ẹni tó o lè fọkàn tán
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tá a lè fọkàn tán, ìyẹn Jésù Kristi. Kì í ṣe pé Jésù kàn jẹ́ èèyàn dáadáa tó gbé láyé àtijọ́ nìkan ni, àmọ́ Ọlọ́run ti fi í “jẹ Ọba . . . , Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.” (Lúùkù 1:32, 33) Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, Ìjọba yìí sì ti ń ṣàkóso lọ́run báyìí.—Mátíù 6:10.
Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó o fi lè fọkàn tán Jésù, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?” àti “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”