BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
Àtẹ Ìwé Tó Ń Jẹ́rìí “fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè”
APRIL 1, 2023
Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí tá a ti ń lo àtẹ ìwé lẹ́nu iṣẹ́ ìwáásù, àtẹ wa yìí sì máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra. Gbogbo ibi ni wọ́n ti dá àtẹ ìwé yìí mọ̀. Kì í ṣe pé àtẹ yìí ń fa àwọn èèyàn mọ́ra nìkan ni, ó tún dùn-ún lò. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà gbà pẹ̀lú ohun tí arábìnrin Asenata tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Poland sọ, ó ní: “Wọ́n ṣe àtẹ náà lọ́nà tó rọrùn láti lò, kò tóbi jù, ó sì jojú ní gbèsè. Kò ṣòro láti tò pọ̀, ó sì rọrùn láti tì kiri.”
Ṣé o mọ bí wọ́n ṣe ṣe àwọn àtẹ ìwé yìí?
Àtẹ ìwé Tó Rọrùn Láti Lò
Lọ́dún 2001, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Faransé bẹ̀rẹ̀ oríṣiríṣi ọ̀nà ìwàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí, títí kan lílo àtẹ ìwé. Bí àpẹẹrẹ, oríṣiríṣi àwọn ohun tí a lè kó ìwé sí bíi tábìlì àtàwọn nǹkan míì ni wọ́n gbìyànjú ẹ̀ wò. Nígbà tó yá, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Faransé fọwọ́ sí èyí tí wọ́n rí i pé ó dáa jù, àwọn ará sì lò ó fún ọdún mẹ́ta.
Inú àwọn ará ní orílẹ̀-èdè Faransé dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé ohun tí wọ́n ṣe yọrí sí rere. Ní ọdún 2011, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi àtẹ ìwé àti tábìlì wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí ní ìlú New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó kópa nínú ìwàásù yẹn rí i pé àtẹ ìwé náà wúlò gan-an, wọ́n á sì lè lò ó níbikíbi. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn tún dábàá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣàtúnṣe sí àtẹ ìwé náà kó bá a lè rọrùn láti lò. Torí pé igi ni wọ́n fi ṣe àwọn àtẹ ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe, ó wúwo gan-an ìyẹn sì mú kó ṣòro gbé kiri. Torí náà, wọ́n tún un ṣe, kó má fi bẹ́ẹ̀ wúwo síbẹ̀, kó má tún fẹ́lẹ́ jù débi tí atẹ́gùn á fi máa gbé e ṣubú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ṣe táyà sí ẹsẹ̀ àwọn àtẹ ìwé náà kó bá a lè ṣeé tì kiri. Láfikún síyẹn, wọ́n ṣe àpótí kékeré kan sẹ́yìn àtẹ tuntun náà, kí wọ́n lè máa kó àwọn ìwé míì sí i.
Ètò tí wọ́n ṣe yìí yọrí sí rere. Torí náà, nígbà tó di ọdún 2012, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí àwọn ará kárí ayé máa lo àtẹ ìwé. Wọ́n wá ṣètò pé kí ilé iṣẹ́ kan ṣe àtẹ ìwé tó pọ̀, kó sì lo àwọn nǹkan tí kò ní tètè bà jẹ́ tí ò sì fi bẹ́ẹ̀ wúwo láti ṣe é.
Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n ṣe àwọn àtúnṣe sí àtẹ ìwé náà. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2015, wọ́n ṣe ọ̀rá tó nípọn tó lè máa bo àtẹ ìwé náà tí òjò bá ń rọ̀. Dina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà nífẹ̀ẹ́ sí àtúnṣe yìí. Ó sọ pé, “Àtẹ ìwé wa ti ní ‘aṣọ òjò’ tiẹ̀ tí ò ní jẹ́ kí òjò máa pa àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú ẹ̀.” Lọ́dún 2017, wọ́n ṣe oríṣiríṣi àwòrán orí bébà tó ní àkọlé ní onírúuru èdè tó ṣeé lẹ̀ mọ́ ara àtẹ náà. Arákùnrin Tomasz tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Kì í rọrùn rárá ká tó lè pààrọ̀ àwòrán orí bébà tá à ń lò tẹ́lẹ̀, àmọ́ tuntun yìí rọrùn láti lò gan-an!” Ní ọdún 2019, wọ́n tún ṣe àwọn àtúnṣe míì sáwọn nǹkan tá a fi ń ṣe àwọn àtẹ yìí kó lè túbọ̀ lálòpẹ́.
Bá A Ṣe Ń Rí Àwọn Àtẹ Ìwé Wa Gbà
Ilé iṣẹ́ kan ló máa ń ṣe àwọn àtẹ ìwé yìí, àá sì fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kárí ayé. Lọ́wọ́lọ́wọ́, iye tí wọ́n ń ṣe àtẹ ìwé kan fún wa jẹ́ dọ́là mẹ́tàlélógójì (43), yàtọ̀ sí àwọn ìnáwó míì bí owó tá a máa fi kó o ránṣẹ́. Títí di báyìí, ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún (16) owó dọ́là la ti ná láti ṣe àwọn àtẹ ìwé, a sì ti fi ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420,000) ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kárí ayé.
Ká lè fọgbọ́n ná owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ, ọ̀pọ̀ àtẹ ìwé la máa ń rà lẹ́ẹ̀kan náà. Bákan náà tó bá bà jẹ́, ìjọ lè béèrè fún ohun tó bà jẹ́ lára àtẹ ìwé náà dípò kí wọ́n béèrè fún àtẹ ìwé tuntun míì.
À Ǹ Fi Àwọn Àtẹ Ìwé Wa Wàásù
Inú àwọn ará wa kárí ayé máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń fi àtẹ ìwé wa wàásù. Martina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Gánà sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀nà tá a gbà ń wàásù, àwa la máa ń lọ bá àwọn èèyàn, àmọ́ ní ti àtẹ ìwé yìí àwọn èèyàn ló máa ń wá bá wa. Kódà àtẹ náà tún ń wàásù fún àwọn tí ò tiẹ̀ yà pàápàá, ìyẹn lohun tí mo sì gbádùn jù nípa àtẹ yìí.”
Lórílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Áfíríkà, ọkùnrin kan wá sí ìdí àtẹ ìwé wa, ó sì mú àwọn ìwé kan lédè ẹ̀. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó wá síbi àtẹ ìwé náà, ó sì sọ pé: “Mo ti ka gbogbo ìwé náà tán, àwọn nǹkan tẹ́ ẹ kọ síbẹ̀ wúlò gan-an. Tí mo bá pa dà sábúlé wa, màá sọ ohun tí mo kà nínú ẹ̀ fáwọn mọ̀lẹ́bí mi.” Ibẹ̀ sì jìn tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) kìlómítà. Oṣù méjì lẹ́yìn náà ọkùnrin yẹn pa dà wá, sí ìyàlẹ́nu wa ó sọ pé: “Àwọn ará abúlé wa ti ka gbogbo ìwé náà pátá, wọ́n sì gbádùn ohun tí wọ́n kà. Wọ́n láwọn ṣe tán láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ wọ́n ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n mọ̀ pé inú omi làwọn ti gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi, àmọ́ a ò ní odò lábúlé wa, ṣé a gbọ́dọ̀ wá síbí ká tó lè ṣèrìbọmi ni?” Torí náà, àwọn akéde tó wà níbi àtẹ ìwé náà ṣètò bí aṣáájú-ọ̀nà kan tó gbọ́ èdè ẹ̀ dáadáa ṣe máa kàn sí. Bí aṣáájú-ọ̀nà yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.
Inú wa dùn láti rí bí àwọn ará ṣe ń lo àtẹ ìwé wa láti wàásù “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Báwo la ṣe ń rí owó tá a fi ń ṣe àwọn àtẹ ìwé yìí? Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ń ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn ló mú kó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé orí ìkànnì donate.dan124.com lẹ ti ń fi ránṣẹ́. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.