Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iléeṣẹ́ rédíò WBBR, lọ́dún 1924

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

À Ń Wàásù Ìhìn Rere Lórí Rédíò Àti Tẹlifíṣọ̀n

À Ń Wàásù Ìhìn Rere Lórí Rédíò Àti Tẹlifíṣọ̀n

 Ní ìrọ̀lẹ́ Sunday, February 24, 1924, iléeṣẹ́ rédíò WBBR táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì a ń lò gbóhùn sáfẹ́fẹ́ fúngbà àkọ́kọ́. Báwo ni ètò àkọ́kọ́ yìí ṣe rí? Àwọn wo ló gbọ́ ètò rédíò náà? Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé láti jẹ́ kí àwọn èèyàn gbọ́ “ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé”?​—Mátíù 24:14.

Amojú ẹ̀rọ kan ní Iléeṣẹ́ rédíò WBBR

“Ni A Bá Bẹ̀rẹ̀ Ètò Náà”

 Aago mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ ni ètò àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀, wákàtí méjì ni wọ́n sì fi ṣe ètò náà. Iléeṣẹ́ rédíò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí Staten Island, ní New York, ni wọ́n ti gbé ètò náà sáfẹ́fẹ́. Arákùnrin Ralph Leffler tó jẹ́ alábòójútó ní yàrá tí wọ́n ti ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ sọ pé, “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú àwa tá a wà níbẹ̀ ń dùn, lẹ́sẹ̀ kan náà ọkàn wa ò balẹ̀ torí à ń ronú pé ṣé àwọn èèyàn máa gbóhùn wa báyìí? La bá bẹ̀rẹ̀ ètò náà, a sì nígbàgbọ́ pé àwọn èèyàn máa gbọ́ wa.”

 Arákùnrin Victor Schmidt ni ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ rédíò náà, òun ló sì tukọ̀ ètò pàtàkì yẹn. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ètò, ó jẹ́ káwọn olùgbọ́ mọ̀ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jẹ́ olóhùn iyọ̀ máa fi orin atunilára dá wọn lára yá. Arákùnrin kan ló kọ́kọ́ fi dùrù kọ àwọn orin aládùn. Lẹ́yìn náà, Arábìnrin Cora Wellman kọrin tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún Náà,” tó dá lórí àpèjúwe Jésù nípa àgùntàn tó sọ nù. (Lúùkù 15:4-7) Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n tún kọ àwọn orin míì. Lára ẹ̀ ni orin tí Arákùnrin Frederick W. Franz kọ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ọkùnrin Tó Ronú Pìwà Dà Náà.” Orin náà dá lórí àpèjúwe ọmọ tó sọ nù tàbí ọmọ onínàákúnàá.​—Lúùkù 15:11-25.

Ọjọ́ tí wọ́n ṣí Iléeṣẹ́ rédíò WBBR

 Joseph F. Rutherford tó ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn sọ àsọyé láti ya iléeṣẹ́ rédíò náà sí mímọ́ “fún ìtẹ̀síwájú ìjọba Mèsáyà.” Ó sọ pé: “Bí Olúwa ṣe jẹ́ ká ní iléeṣẹ́ rédíò lákòókò yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Ó fẹ́ ká lò ó láti kọ́ àwọn èèyàn nípa bó ṣe máa mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ.”

“A Ò Pàdánù Ohunkóhun”

 Ní ìgbà àkọ́kọ́ tá a gbóhùn sáfẹ́fẹ́, ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ wa ketekete láti àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọkùnrin kan tó ń gbé ní Morrisville, Vermont tó jìnnà tó nǹkan bíi 320 kìlómítà sílé iṣẹ́ rédíò náà sọ pé: “Inú mi dùn láti sọ fún yín pé mo gbọ́ yín níbí. . . . Ohùn Rutherford dún ketekete. . . . A ò pàdánù ohunkóhun.” Kódà ẹnì kan láti Monticello, Florida tó jìnnà gan-an gbọ́ ètò náà! Jèhófà jẹ́ kí iléeṣẹ́ rédíò yìí yọrí sí rere, kó sì pẹ́ tàwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí í fi lẹ́tà ìdúpẹ́ ránṣẹ́.

Joseph Rutherford mú makirofóònù dáni ní yàrá ìgbohùnsílẹ̀ WBBR. Victor Schmidt ni atọ́kùn ètò náà

 Ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) la fi gbé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sáfẹ́fẹ́, b ní pàtàkì fún àwọn tó wà ní àríwá ìlà oòrùn Amẹ́ríkà. Àmọ́ nígbà míì, rédíò WBBR máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ rédíò míì, èyí sì ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Kánádà àti láwọn ibi tó jìnnà gbọ́ ètò orí rédíò náà. Kódà, Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1975 sọ pé: “Nígbà tó máa fi di 1933, ilé iṣẹ́ rédíò ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́jọ (408) la fi ń gbe àwọn ètò wa jáde kárí ayé, àsọyé Bíbélì 23,783 la sì gbé sáfẹ́fẹ́. . . Láyé ìgbà yẹn, téèyàn bá yí rédíò ẹ̀, ó ṣeé ṣe kéèyàn máa gbọ́ àsọyé Bíbélì láwọn iléeṣẹ́ rédíò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Torí náà, a lè sọ pé àwọn èèyàn jákèjádò ayé ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ń fògo fún Ọlọ́run.”

Ìwàásù Ilé-Dé-Ilé Rọ́pò Ìwàásù Orí Rédíò

 Iye àwọn akéde tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ò ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (1,064) lọ nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò WBBR. Àwọn ètò tí wọ́n ń gbé sáfẹ́fẹ́ yìí ran àwùjọ kékeré yìí lọ́wọ́ láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1957, iye àwọn akéde tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti tó 187,762, iye àwọn akéde tó sì wà kárí ayé jẹ́ 653,273. Ohun míì ni pé àwọn ìpàdé ìjọ ti ran àwọn akéde yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé àti láwọn apá míì lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

 Àwọn ìròyìn yìí ló mú kí àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa nígbà yẹn ronú bóyá ó ṣì máa dáa ká máa lo iléeṣẹ́ rédíò náà tàbí ká gbájú mọ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Kí ni wọ́n wá pinnu? Wọ́n pinnu pé kí wọ́n ta iléeṣẹ́ rédíò WBBR, ìyẹn iléeṣẹ́ rédíò kan ṣoṣo tí Watchtower Society ń lò nígbà yẹn. Ní April 15, 1957, wọ́n ta iléeṣẹ́ rédíò náà. Nígbà tí Nathan H. Knorr ń sọ̀rọ̀ ìdágbére lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n tà á, wọ́n bi í pé kí ló dé tí wọ́n fẹ́ ta iléeṣẹ́ rédíò náà. Ó ṣàlàyé pé iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ló jẹ́ kí iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa pọ̀ sí i. Ó fi kún un pé: “Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ló ti jàǹfààní bí iléeṣẹ́ rédíò WBBR ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sáfẹ́fẹ́, àmọ́ àwọn agbègbè tí rédíò náà ò dé kárí ayé làwọn èèyàn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jù, tí wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Torí náà, àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa rí i pé ìwàásù ilé-dé-ilé máa gbéṣẹ́ ju ti orí rédíò lọ. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò ní gbóhùn sáfẹ́fẹ́ mọ́ ni? Rárá o! Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, a tún gbọ̀nà àrà míì yọ.

Ètò Tá Á Ń Gbé Sáfẹ́fẹ́ Lónìí

 Ohun kan ṣẹlẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run ní October 6, 2014 tó múnú wa dùn gan-an. Oṣù yẹn ni ètò orí tẹlifíṣọ̀n tá à ń pè ní JW Broadcasting bẹ̀rẹ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì lè wo ètò oṣooṣù yìí lórí JW Library, fóònù àti kọ̀ǹpútà tó lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lórí Sátẹ́láìtì. c Láwọn ibi kan láyé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń wàásù lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Kí nìdí?

Ètò tẹlifíṣọ̀n JW Broadcasting àkọ́kọ́ ní October 2014

 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run ń lo àwọn iléeṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n tí kì í ṣe táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gbé ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ àti ìpàdé agbègbè sáfẹ́fẹ́ láwọn ibi tí Íńtánẹ́ẹ̀tì ò ti fi bẹ́ẹ̀ dáa. Èyí sì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn tó wù láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti gbọ́ àwọn ètò yìí. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2021 sí 2022, àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ rédíò sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní East Africa pé àwọn èèyàn ń gbádùn àwọn ìpàdé tá à ń gbé sáfẹ́fẹ́. Ó wú wa lórí pé lára àwọn tó gbọ́ ètò náà ní Kenya, South Sudan, àti Tanzania ló sọ pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Bó ti wù kó rí, àwọn ọ̀nà pàtó táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń wàásù kárí ayé ni láti ilé dé ilé, lílo àtẹ ìwé àti ìkànnì jw.org. Ìkànnì wa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rin (1,080). Àwọn tó bá lọ sórí ìkànnì yìí á rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tọ́pọ̀ èèyàn máa ń béèrè, wọ́n á sì rí àwọn ibi tá a ti ń ṣe àwọn ìpàdé wa àti àkókò tá a máa ń ṣe é. Gbogbo ohun tá à ń ṣe yìí ti jẹ́ kó rọrùn fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Kò sí àní-àní pé à ń wàásù ìhìn rere náà ní “gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,” bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀.​—Mátíù 24:14.

a Ọdún 1931 làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yí orúkọ wọn pa dà sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

b Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún láwọn iléeṣẹ́ rédíò sáwọn orílẹ̀-èdè míì títí kan Ọsirélíà àti Kánádà.