Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

A Wà Níṣọ̀kan Lórílẹ̀-Èdè Táwọn Èèyàn Ti Kẹ̀yìn Síra

A Wà Níṣọ̀kan Lórílẹ̀-Èdè Táwọn Èèyàn Ti Kẹ̀yìn Síra

 Látọdún 1948 sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ìjọba orílẹ̀-èdè South Africa ṣòfin pé àwọn tó wá láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ò gbọ́dọ̀ da nǹkan kan pọ̀. a Lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń hùwà tí ò dáa sáwọn tó wá láti ẹ̀yà míì. Kallie tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú sọ bí nǹkan ṣe burú tó lákòókò yẹn, ó ní: “Àwọn aláwọ̀ dúdú pàápàá máa ń ṣe ẹ̀tanú síra wọn.”

 Onírúurú ẹ̀yà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní South Africa ti wá. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é tí wọ́n fi wà níṣọ̀kan lákòókò yẹn? Kí làwa náà sì lè rí kọ́ látinú ohun tí wọ́n ṣe?

Wọ́n Fẹ̀mí Wọn Wewu Torí Wọn Ò Dá Sọ́rọ̀ Òṣèlú

 Ní South Africa, àwọn tí ò fara mọ́ òfin tí ìjọba ṣe yìí bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó fi ẹ̀hónú hàn yìí ni ìjọba jù sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n pa àwọn míì nínú wọn. Bó ṣe di pé àwọn tó ń tako ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í jìjàgbara nìyẹn, tí wọ́n sì ń dá wàhálà sílẹ̀. Àmọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lé òfin ìjọba, a ò wọ́de láti fi èhónú hàn, a ò sì dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń jìjàgbara. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe la fara wé àwọn Kristẹni ìgbàanì tí wọ́n “tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.”​—Róòmù 13:1, 2.

 Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fúngun mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ká gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ kan. Àmọ́ àwọn ará wa ò gbà torí tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe nìyẹn á fi hàn pé wọ́n fara mọ́ rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo òṣèlú, wọ́n á sì tún máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá láti ẹ̀yà míì jà. Bí àpẹẹrẹ, Thembsie sọ pé, “Lásìkò rògbòdìyàn tó wáyé lọ́dún 1976, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n fipá mú láti wá jìjàgbara. Ṣe làwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó ń jà náà ń ti ilé kan bọ́ sí òmíì kí wọ́n lè pe àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ míì láti dara pọ̀ mọ́ wọn. Tẹ́nì kan bá kọ̀, wọ́n lè dáná sun ilé ẹ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lù ú pa.” Olórí ẹgbẹ́ òṣèlú kan tó ń tako ìjọba sọ fún Theophilus tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé, “Tá a bá ti gbàjọba lọ́wọ́ àwọn òyìnbó, a máa pa ẹ́ torí o ò jà fún orílẹ̀-èdè ẹ.”

Wọ́n Ń Ṣèpàdé Níbi Táwọn Èèyàn Ti Yapa Síra Wọn

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Africa ṣì máa ń kóra jọ láti ṣèpàdé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìlú ò fara rọ. (Hébérù 10:24, 25) Àwọn ìjọ kan ò lè kọ́ Ilé Ìpàdé torí òfin tó ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ ti sọ ọ̀pọ̀ di tálákà paraku. b Enver sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún la fi rẹ́ǹtì àwọn ilé kan tá a fi ń ṣèpàdé, àmọ́ àwọn ilé náà ò bójú mu rárá. Ni bàbá mi bá yọ̀ǹda pé kí wọ́n máa ṣèpàdé nílé wa. Torí náà, lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, a máa tún ilé wa tò kó lè rọrùn fáwọn ará láti ṣèpàdé níbẹ̀. Nígbà míì, ó máa ń ju ọgọ́rùn-ún èèyàn tó máa ń kóra jọ sílé wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ṣe àwọn ará lálejò lẹ́yìn ìpàdé ìyẹn sì máa ń mú inú wa dùn.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú àti aláwọ̀ funfun ń ṣèpàdé ní April 1950

Ìpàdé kan tí wọ́n ṣe ní pápá ìṣeré Rand nílùú Johannesburg lọ́dún 1980, onírúurú ẹ̀yà ló wà níbẹ̀

 Òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀ fa ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ àwọn ará lo onírúurú ọgbọ́n láti borí àwọn ìṣòro náà. Bí àpẹẹrẹ ní Agbègbè Limpopo, ètò Ọlọ́run ní kí arákùnrin kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun sọ àsọyé ní àpéjọ àyíká kan ní àdúgbò àwọn aláwọ̀ dúdú, àmọ́ ìjọba ò gbà kó wọ àdúgbò náà. Ni arákùnrin náà bá lọ bá ọkùnrin kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun tó ní oko lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n á ti ṣe àpéjọ náà, ó sì bá a ṣàdéhùn láti lo oko ẹ̀. Bó ṣe di pé arákùnrin yìí ń sọ àsọyé nínú oko, àwọn ará sì ń gbádùn àsọyé náà lódì kejì.

Wọ́n Wàásù Láwọn Ìpínlẹ̀ Tí Ò Rọrùn

 Nínú òfin tí ìjọba ṣe yẹn, wọ́n pàṣẹ pé káwọn tó wá láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ má ṣe gbé ní àdúgbò kan náà. Torí náà, àwọn tó wá láti ẹ̀yà kan náà ló sábà máa ń wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ kan. Ìyẹn máa ń gba pé ká fọgbọ́n ṣètò báwọn akéde ṣe máa wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, kì í rọrùn láti lọ wàásù láwọn agbègbè tí a kì í ṣe déédéé. Krish tí ìjọba kà sí ẹ̀yà “Indian” sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í sí ibi táwa tá ò kì í ṣe aláwọ̀ funfun lè sùn mọ́jú. Torí náà, abẹ́ igi tàbí inú mọ́tò wa la máa ń sùn sí. Tó bá di àárọ̀, àá lọ wẹ̀ ní ilé ìtura tó wà ní ilé epo kan. Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé àkọlé gàdàgbà máa wà níwájú ilé ìtura náà pé àwọn aláwọ̀ funfun nìkan ni kó lò ó. Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, àwọn ará kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọ ṣe fún iṣẹ́ ìwàásù, inú wọn sì ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ láwọn abúlé.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá láti onírúurú ẹ̀yà ń wàásù ní abúlé kan lọ́dún 1981

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn nílùú, ṣe làwọn tó ń sin Jèhófà ń pọ̀ sí i. Nígbà tí wọ́n gbé òfin kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà yìí kalẹ̀ lọ́dún 1948, akéde ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n (4,831) ló wà ní South Africa. Nígbà tí wọ́n fi máa mú òfin náà kúrò lọ́dún 1994, iye akéde tó wà níbẹ̀ ti tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́ta, ọgọ́rùn-ún méje àti mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (58,729). Iye yẹn sì ń pọ̀ sí i. Nígbà tó fi máa di ọdún 2021, iye akéde tó wà ní South Africa tí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún àti méjìléláàádọ́fà (100,112).

Ìkórìíra Yí Wọn Ká, Síbẹ̀ Wọ́n Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn

 Lásìkò tí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ń jà ràn-ìn nílùú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní South Africa ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí, wọ́n sì tún wà níṣọ̀kan. Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé ìlànà Bíbélì tí wọ́n fi ń kọ́ni làwọn náà ń tẹ̀ lé. (Ìṣe 10:34, 35) Òótọ́ ni pé àárín àwọn tó kórìíra ara wọn ni wọ́n ń gbé, síbẹ̀ wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì wà níṣọ̀kan.​—Jòhánù 13:34, 35.

 Lọ́dún 1993, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àpéjọ kan ní South Africa, onírúurú ẹ̀yà ló sì wà níbẹ̀. Gbajúgbajà olóṣèlú kan rí báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní South Africa ṣe ń fi tẹ̀rín-tọ̀yàyà kí àwọn tó wá láti òkè òkun káàbọ̀, tí wọ́n sì tún ń gbá wọn mọ́ra nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfúrufú. Ó wá sọ pé: “Ká sọ pé bẹ́ ẹ ṣe wà níṣọ̀kan làwa náà wà níṣọ̀kan ni, a ò bá ti yanjú àwọn ìṣòro wa tipẹ́tipẹ́.”

Milton Henschel tó wá láti Oríléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ àsọyé ní àpéjọ kan tá a ṣe lọ́dún 1955, onírúurú ẹ̀yà ló wà níbẹ̀

Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Africa, àwọn aláwọ̀ dúdú àti aláwọ̀ funfun ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́dún 1986

Thomas Skosama (apá òsì) àti Alfred Steynberg ní àpéjọ kan lọ́dún 1985, ọjọ́ pẹ́ táwọn méjèèjì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá láti onírúurú ẹ̀yà ń pín oúnjẹ fáwọn èèyàn ní àpéjọ kan lọ́dún 1985

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá láti onírúurú ẹ̀yà ń ṣe ìpàdé kan ní pápá ìṣeré FNB nílùú Johannesburg lọ́dún 2011

a Òfin tí ìjọba ṣe yìí gba pé kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa ṣe nǹkan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Torí náà, ẹ̀yà tẹ́nì kan ti wá ló máa pinnu bó ṣe máa kàwé tó, irú iṣẹ́ tó máa ṣe, ibi tó lè gbé àti ẹni tó máa fẹ́. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka “What Was Apartheid?” nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2007 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

b Látọdún 1999, owó táwọn ìjọ bá fi ṣètìlẹyìn ni ètò Ọlọ́run fi ń kọ́ Ilé Ìpàdé láwọn ibi tí wọ́n bá ti nílò ẹ̀ kárí ayé.