Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ò Ní Gbàgbé Yín

A Ò Ní Gbàgbé Yín

Wà á jáde:

  1. 1. Bíjì bá jà,

    Tójò bá rọ,

    Tílẹ̀ bá ń mì tìtì, tílé ń wó lulẹ̀,

    Ọlọ́run ń ṣọ́ yín.

    Ó sì nífẹ̀ẹ́ yín.

    Àwa ọ̀rẹ́

    Tún ti débí.

    A máa ràn yín lọ́wọ́.

    (ÈGBÈ)

    A ò ní gbàgbé yín.

    Ọmọ ìyá ni wá.

    A ò ní pa yín tì.

    A máa dúró tì yín.

    Ẹ má mikàn.

    Ẹ má bẹ̀rù.

    A máa ràn yín lọ́wọ́.

    A ò ní gbàgbé yín.

    Ọmọ ìyá ni wá.

  2. 2. Tíjì bá jà,

    Tílẹ̀ wá mọ́,

    Tẹ́ ẹ rí wa, tá a fìfẹ́ rọ̀gbà yí i yín ká,

    Ẹ máa wá gbà pé,

    A nífẹ̀ẹ́ yín gan-an.

    Okùn ìfẹ́

    Wa lágbára,

    Kò sóhun tó lè já a.

    (ÈGBÈ)

    A ò ní gbàgbé yín.

    Ọmọ ìyá ni wá.

    A ò ní pa yín tì.

    A máa dúró tì yín.

    Ẹ má mikàn.

    Ẹ má bẹ̀rù.

    A máa ràn yín lọ́wọ́.

    A ò ní gbàgbé yín.

    Ọmọ ìyá ni gbogbo wá.

    A ò ní gbàgbé yín.

    Ọmọ ìyá ni wá.